Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ MAY 2-8, 2016
6 Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ṣé Ẹ Ti Múra Tán Láti Ṣe Ìrìbọmi?
Ọ̀SẸ̀ MAY 9-15, 2016
12 Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Báwo Lẹ Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrìbọmi?
Inú àwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń dùn pé lọ́dọọdún, àwọn tó tó ẹgbàá márùnlélọ́gọ́fà [250,000] ló ń ṣèrìbọmi. Ọ̀dọ́ ló pọ̀ jù lára àwọn tó ń ṣèrìbọmi, àwọn kan lára wọn ò sì tíì pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá. Kí ló mú kó dá wọn lójú pé wọ́n ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi? Kí ni wọ́n ṣe láti múra sílẹ̀ fún ìrìbọmi? Àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
Ọ̀SẸ̀ MAY 16-22, 2016
18 Báwo Lo Ṣe Lè Pa Kún Ìṣọ̀kan Tó Wà Láàárín Àwa Kristẹni?
Jèhófà máa ń bù kún wa tá a bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn àbá táá ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, nínú ìjọ àti nínú ìdílé wa.
Ọ̀SẸ̀ MAY 23-29, 2016
24 Jèhófà Ń Tọ́ Wa Sọ́nà Ká Lè Jogún Ìyè
Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́nà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí Ọlọ́run ṣe ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ tó sì ń fún wọn ní àwọn ìtọ́ni tuntun bí ìyípadà ṣe ń wáyé. A óò tún mọ bá a ṣe lè máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà.