Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀
KÍ LÈRÒ RẸ?
Tó bá jẹ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá, ṣé ó máa ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti pa á run?
Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ pé: “Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ; ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Aísáyà 40:8.
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí sọ ìtàn bí Bíbélì ṣe wà títí dòní.