Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ MAY 30, 2016–JUNE 5, 2016
3 Tá A Bá Jẹ́ Olóòótọ́, A Máa Rí Ojúure Ọlọ́run
Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ ohun tó ran Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́ tí wọ́n fi jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà kódà nígbà tí wọ́n kojú àdánwò tó le koko. Ó tún máa jẹ́ ká rí i pé ohun yòówù ká yááfì ká lè rí ojú rere Ọlọ́run tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀SẸ̀ JUNE 6-12, 2016
9 “Ẹ Jẹ́ Kí Ìfaradà Ṣe Iṣẹ́ Rẹ̀ Pé Pérépéré”
Ká tó lè gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun, a gbọ́dọ̀ fara dà á dé òpin. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa ṣàgbéyẹ̀wò ohun mẹ́rin tó máa jẹ́ ká lè fara dà á títí dópin, a sì tún máa jíròrò àpẹẹrẹ àwọn mẹ́ta kan tí wọ́n lo ìfaradà. Àpilẹ̀kọ yìí tún máa jẹ́ ká mọ iṣẹ́ tí ìfaradà gbọ́dọ̀ ṣe pé pérépéré nínú gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.
Ọ̀SẸ̀ JUNE 13-19, 2016
15 Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìnp?
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kó má rọrùn fún wa láti máa lọ sípàdé déédéé. Àpilẹ̀kọ yìí máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìpàdé Kristẹni, ó máa jẹ́ ká rí ìdí tí lílọ sípàdé déédéé fi máa ṣe àwa àtàwọn míì láǹfààní àti ìdí tó fi ń múnú Jèhófà dùn.
Ọ̀SẸ̀ JUNE 20-26, 2016
21 Má Ṣe Dá Sí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú Tàbí Ogun
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ìjọba ò fúngun mọ́ wa pé ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun, bí òpin ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ wa pé ká lọ́wọ́ sí i. Nínú àpilẹ̀kọ́ yìí, a máa jíròrò ohun mẹ́rin tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà.
27 Ìtàn Ìgbésí Ayé—Àwọn Obìnrin Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Ìnìkàngbé Di Ìránṣẹ́ Jèhófà