Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ JUNE 27, 2016–JULY 3, 2016
Torí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún, a ò lè ṣe ká má ṣẹ ara wa. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè lo àwọn ìlànà inú Bíbélì láti yanjú aáwọ̀.
Ọ̀SẸ̀ JULY 4-10, 2016
8 “Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká rí àwọn ìdí tá a fi lè sọ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló ń mú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 24:14 ṣẹ. Ó tún sọ ohun téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó di “apẹja ènìyàn.”—Mát. 4:19.
Ọ̀SẸ̀ JULY 11-17, 2016
Tó o bá fẹ́ ṣèpinnu, ṣé nǹkan tó bá ṣáà ti dáa lójú ẹ lo máa ń ṣe? Àbí o máa ń sọ pé káwọn míì sọ ohun tó o máa ṣe fún ẹ? Àpilẹ̀kọ yìí máa ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ pé tá a bá róye ohun tí Ọlọ́run fẹ́ nìkan la tó lè ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu.
Ọ̀SẸ̀ JULY 18-24, 2016
18 Ǹjẹ́ Bíbélì Ṣì Ń Yí Ìgbésí Ayé Rẹ Pa Dà?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ti ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì kan kó o tó ṣèrìbọmi, ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti lo àwọn ànímọ́ Kristẹni kan báyìí? Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ìdí tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀ nígbà míì àti bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fàwọn ànímọ́ tó yẹ Kristẹni ṣèwà hù.
Ọ̀SẸ̀ JULY 25-31, 2016
23 Máa Jẹ Oúnjẹ Tẹ̀mí Tí Jèhófà Ń Pèsè fún Wa Lájẹyó
Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí ewu tó wà nínú kéèyàn máa ronú pé àwọn kan lára àwọn ìtẹ̀jáde wa ò wúlò fún òun. A máa jíròrò bá ò ṣe ní gba irú èrò bẹ́ẹ̀ láyè, a sì máa kọ́ bá a ṣe lè máa jàǹfààní látinú gbogbo oúnjẹ tẹ̀mí tá a ní.