Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ AUGUST 1-7, 2016
6 Mọyì Jèhófà Tó Jẹ́ Amọ̀kòkò Wa
Ọ̀SẸ̀ AUGUST 8-14, 2016
11 Ṣé Wàá Jẹ́ Kí Amọ̀kòkò Ńlá Náà Mọ Ẹ́?
Iṣẹ́ ọnà ni mímọ ìkòkò, àwọn amọ̀kòkò sì máa ń gbádùn iṣẹ́ wọn gan-an. Nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí, a máa rí bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òun ni “Amọ̀kòkò” tó mọ wá, àá sì mọ ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run máa mọ wá nìṣó.
16 Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ọ̀SẸ̀ AUGUST 15-21, 2016
18 “Jèhófà Ọlọ́run Wa, Jèhófà Kan Ṣoṣo Ni”
Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà Ọlọ́run wa gbà jẹ́ “Jèhófà kan ṣoṣo”? Báwo nìyẹn ṣe kan àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ àti àjọṣe tá a ní pẹ̀lú àwọn ará wa? Lónìí tí èdè àti àṣà pọ̀ jáǹtirẹrẹ, ó ṣe pàtàkì pé ká lóye ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe, kí Jèhófà lè jẹ́ “Ọlọ́run Wa.”
Ọ̀SẸ̀ AUGUST 22-28, 2016
23 Má Ṣe Jẹ́ Kí Àṣìṣe Àwọn Míì Mú Ẹ Kọsẹ̀
Gbogbo wa la máa ń ṣe ohun tó lè dun àwọn míì. Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló lá mú ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe nígbà tẹ́nì kan bá sọ tàbí ṣe ohun tó dùn wá?