Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
3 Ìtàn Ìgbésí Ayé Mo Láyọ̀ Pé Mò Ń Lo Ara Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Ọlọ́run
Ọ̀SẸ̀ SEPTEMBER 26, 2016–OCTOBER 2, 2016
8 Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ṣètò Ìgbéyàwó?
Ọ̀SẸ̀ OCTOBER 3-9, 2016
13 Ohun Táá Jẹ́ Kí Tọkọtaya Bára Wọn Kalẹ́
Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ bí ìgbéyàwó ṣe bẹ̀rẹ̀, ó sọ bí Ọlọ́run ṣe lo Òfin Mósè láti darí àwọn tọkọtaya nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ó sì jẹ́ ká mọ ìlànà tí Jésù fún àwa Kristẹni lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Àpilẹ̀kọ kejì jíròrò ojúṣe ọkọ àti aya bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́.
18 Máa Wá Ohun Tó Sàn Ju Góòlù Lọ
Ọ̀SẸ̀ OCTOBER 10-16, 2016
20 Ǹjẹ́ O Lè Fi Kún Ohun Tó Ò Ń Ṣe Nínú Ìjọsìn Ọlọ́run?
Ọ̀SẸ̀ OCTOBER 17-23, 2016
25 Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́?
Inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń rí iye àwọn èèyàn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tí wọ́n sì ń wá sínú ètò Ọlọ́run. Àmọ́, ṣe nìyẹn tún ń sọ fún wa pé a ní láti fi kún ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè fi kún ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn wa, ká sì tún ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́? A máa jíròrò àwọn kókó pàtàkì yìí nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí.