Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ OCTOBER 24-30, 2016
3 ‘Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Rọ Jọwọrọ’
Ọ̀SẸ̀ OCTOBER 31, 2016–NOVEMBER 6, 2016
8 Máa Jà Fitafita Kó O Lè Rí Ìbùkún Jèhófà
Àwọn ìṣòro tá à ń kojú àtàwọn àníyàn tá a ní lè kó ìdààmú ọkàn bá wa débi tá a fi máa juwọ́ sílẹ̀. A máa rí bí Jèhófà ṣe lè fi ọwọ́ agbára rẹ̀ fún wa lókun, kó sì fún wa nígboyà táá mú ká lè fara dà á. Bákan náà, a máa rí bá a ṣe lè jà fitafita láti rí ìbùkún Jèhófà gbà.
13 ÌBÉÈRÈ LÁTI ỌWỌ́ ÀWỌN ÒǸKÀWÉ
14 À Ń Gbèjà Ìhìn Rere Níwájú Àwọn Aláṣẹ
Ọ̀SẸ̀ NOVEMBER 7-13, 2016
17 Ǹjẹ́ Ìmúra Rẹ Ń Fògo fún Ọlọ́run?
Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run kárí ayé máa ń fi ìlànà Ìwé Mímọ́ sọ́kàn tá a bá fẹ́ múra kí ìmúra wa lè mọ́ tónítóní, kó bójú mu, kó sì yẹ ọmọlúàbí. Kí lo lè ṣe láti rí i dájú pé ìmúra rẹ ń fògo fún Ọlọ́run?
22 Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Tọ́ Ẹ Sọ́nà
Ọ̀SẸ̀ NOVEMBER 14-20, 2016
23 Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Mú Kí Ìgbàgbọ́ Yín Túbọ̀ Lágbára
Ọ̀SẸ̀ NOVEMBER 21-27, 2016
28 Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Káwọn Ọmọ Yín Nígbàgbọ́
Nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí, a máa rí báwọn ọ̀dọ́ ṣe lè lo làákàyè wọn láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára, kí wọ́n sì gbèjà ìgbàgbọ́ wọn. Àá tún rí báwọn òbí Kristẹni ṣe lè mú káwọn ọmọ wọn nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, kí wọ́n sì gbà pé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Bíbélì.