Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
3 Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlé Tó Ń Tuni Lára!
Ọ̀SẸ̀ DECEMBER 26, 2016–JANUARY 1, 2017
4 ‘Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú Lẹ́nì Kìíní-Kejì Lójoojúmọ́’
Jèhófà àti Jésù Kristi ló fi àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká fúnni níṣìírí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà gbà pé ó ṣe pàtàkì gan-an ká máa fúnni níṣìírí. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, àá máa fún àwọn míì níṣìírí, èyí á sì mú kí ìfẹ́ wà nínú ìdílé wa àti nínú ìjọ.
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 2-8, 2017
9 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Mú Ká Wà Létòletò
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 9-15, 2017
14 Ṣé Ọwọ́ Pàtàkì Lo Fi Ń Mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ wà létòletò? Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè mú ká wà létòletò? Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o jẹ́ olóòótọ́ sí ètò Ọlọ́run?
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 16-22, 2017
21 A Mú Wọn Jáde Kúrò Nínú Òkùnkùn
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 23-29, 2017
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí sọ ìgbà táwọn èèyàn Ọlọ́run lọ sígbèkùn Bábílónì àti akitiyan táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe kí wọ́n lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ ní nǹkan bí ọdún 1870. A tún máa rí ìpinnu táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nípa Bábílónì Ńlá, àá sì mọ ìgbà tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ìsìnrú Bábílónì.