Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
3 ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ—Mo Di “Ohun Gbogbo fún Ènìyàn Gbogbo”
Ọ̀SẸ̀ JANUARY 30, 2017–FEBRUARY 5, 2017
8 Ọlọ́run Dá Wa Sílẹ̀ Nípasẹ̀ Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí
Ọ̀SẸ̀ FEBRUARY 6-12, 2017
13 “Gbígbé Èrò Inú Ka Ẹ̀mí Túmọ̀ Sí Ìyè àti Àlàáfíà”
Nínú ìwé Róòmù orí 6 àti 8, Pọ́ọ̀lù sọ àwọn nǹkan pàtàkì tó yẹ káwa Kristẹni fi sọ́kàn. Àwọn orí Bíbélì yìí máa jẹ́ ká mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn sí wa, wọ́n á sì jẹ́ ká máa ronú nípa ìyè àìnípẹ̀kun tá à ń fojú sọ́nà fún.
Ọ̀SẸ̀ FEBRUARY 13-19, 2017
19 Kó Gbogbo Àníyàn Rẹ lé Jèhófà
Ọ̀SẸ̀ FEBRUARY 20-26, 2017
24 Jèhófà Máa Ń Sẹ̀san fún Àwọn Tó Ń Fi Taratara Wá A
Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ bá a ṣe lè kó gbogbo àníyàn wa sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àpilẹ̀kọ kejì jẹ́ ká mọ̀ pé kí ìgbàgbọ́ wa tó lè fẹsẹ̀ múlẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbà pé Ọlọ́run máa ń san èrè fáwọn tó ń fi taratara wá a. Ó tún sọ bí ìrètí tá a ní pé Jèhófà máa san wá lẹ́san ṣe ń ṣe wá láǹfààní.