Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì?
No. 5 2017
© 2017 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ìtẹ̀jáde yìí kì í ṣe títà. Ó jẹ́ ara iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé tá à ń fi ọrẹ àtinúwá tì lẹ́yìn.
Tó o bá fẹ́ ṣètọrẹ, jọ̀wọ́ lọ sí ìkànnì wa www.jw.org/yo.
Bá ò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, la ti mú gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a lò.
ÌWÉ ÌRÒYÌN Ilé Ìṣọ́ yìí ń gbé Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Alákòóso ayé òun ọ̀run ga. Ó ń fi ìhìn rere tu àwọn èèyàn nínú pé, láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò fòpin sí gbogbo ìwà ibi, á sì sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè. Ìwé ìròyìn yìí ń gbani níyànjú láti nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi tó kú ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Jésù sì ti ń ṣàkóso báyìí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Láti ọdún 1879 la ti ń tẹ ìwé ìròyìn yìí déédéé, kì í sì í dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Orí Bíbélì ni gbogbo ohun tó ń sọ dá lé.