ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp17 No. 6 ojú ìwé 12-14
  • Kí Nìdí Tí Oríṣiríṣi Bíbélì Fi Wà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tí Oríṣiríṣi Bíbélì Fi Wà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • BÍBÉLÌ ÌPILẸ̀ṢẸ̀
  • BÍBÉLÌ SEPTUAGINT TI ÈDÈ GÍRÍÌKÌ
  • BÍBÉLÌ LÁTÌN VULGATE
  • ÀWỌN ÌTUMỌ̀ BÍBÉLÌ TUNTUN Ń PỌ̀ SÍ I
  • Orukọ Ọlọrun ati “Majẹmu Titun” Naa
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Ìtumọ̀ “Septuagint”—Wúlò Láyé Ọjọ́un àti Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ṣó Pọn Dandan Kó O Kọ́ Èdè Hébérù àti Gíríìkì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
wp17 No. 6 ojú ìwé 12-14
Oríṣiríṣi Bíbélì, èyí tí wọ́n fọwọ́ kọ, tí wọ́n tẹ̀ àti èyí tó wà lórí ẹ̀rọ

Kí Nìdí Tí Oríṣiríṣi BÍBÉLÌ Fi Wà?

Kí nìdí tí oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì fi wà lóde òní? Tó o bá rí ìtumọ̀ Bíbélì tuntun tí wọ́n ṣe jáde, báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ, ṣé ó máa ń jẹ́ kó o lóye Bíbélì ni àbí ó máa ń jẹ́ kó sú ẹ? Tó o bá mọ ibi tí Bíbélì ti wá, ó máa jẹ́ kó o lè fọgbọ́n ṣàyẹ̀wò rẹ̀.

Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́ ná, ta ló kọ Bíbélì, ìgbà wo sì ni wọ́n kọ ọ́?

BÍBÉLÌ ÌPILẸ̀ṢẸ̀

Apá méjì ni wọ́n pín Bíbélì sí. Apá àkọ́kọ́ ní ìwé mọ́kàndínlógójì [39] nínú, tí gbogbo wọn jẹ́ “àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run.” (Róòmù 3:2) Ọlọ́run fi ẹ̀mí darí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ láti kọ àwọn ìwé yìí, ó sì gba ọ̀pọ̀ ọdún. Ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún [1,100] ọdún tí wọ́n fi kọ ọ́, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni títí di àkókò kan lẹ́yìn ọdún 443 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Èdè Hébérù ni wọ́n fi kọ ọ̀pọ̀ lára wọn, ìdí nìyẹn tá a fi ń pe apá yìí ní Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, tí wọ́n tún ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé.

Ìwé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] ló wà nínú apá kejì, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ló sì jẹ́. (1 Tẹsalóníkà 2:13) Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ darí àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi láti kọ apá yìí láàárín àkókò kúkúrú, ìyẹn nǹkan bí ọgọ́ta [60] ọdún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 41 Sànmánì Kristẹni sí ọdún 98 Sànmánì Kristẹni. Èdè Gíríìkì ni wọ́n fi kọ èyí tó pọ̀ jù, ìdí nìyẹn tá a fi ń pe apá yìí ní Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tí wọ́n tún ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun.

Ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ darí yìí ló para pọ̀ di odindi Bíbélì, ìyẹn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run bá wa sọ. Àmọ́ kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì jáde? Mẹ́ta pàtàkì lára àwọn ìdí náà rèé.

  • Káwọn èèyàn lè rí Bíbélì kà ní èdè abínibí wọn.

  • Kí wọ́n lè ṣàtúnṣe sí àwọn àṣìṣe táwọn adàwékọ ti ṣe, kí wọ́n sì dá Bíbélì pa dà sí bó ṣe wà ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.

  • Kí wọ́n lè lo àwọn ọ̀rọ̀ tó bágbà mu.

Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn kókó yìí ṣe nípa lórí ìtumọ̀ Bíbélì méjì tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe.

BÍBÉLÌ SEPTUAGINT TI ÈDÈ GÍRÍÌKÌ

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún kí Jésù tó wá sáyé, àwọn ọ̀mọ̀wé Júù bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè míì, ìyẹn èdè Gíríìkì. Ìtumọ̀ yìí ni wọ́n wá mọ̀ sí Bíbélì Septuagint ti Èdè Gíríìkì. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe é? Kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì dípò èdè Hébérù, láti máa rí “ìwé mímọ́” kà.​—2 Tímótì 3:15.

Bíbélì Septuagint tún ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tí kì í ṣe Júù, tó ń sọ èdè Gíríìkì, láti mọ ohun tí Bíbélì kọ́ni. Lọ́nà wo? Ọ̀jọ̀gbọ́n W.  F. Howard sọ pé: “Láti àárín ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ló ti wá di Bíbélì àwọn Kristẹni. Àwọn míṣọ́nnárì máa ń lọ láti sínágọ́gù kan sí òmíràn kí wọ́n lè ‘fi ẹ̀rí hàn látinú ìwé mímọ́ pé Jésù ni Mèsáyà náà.’ ” (Ìṣe 17:​3, 4; 20:20) Onímọ̀ nípa Bíbélì kan tó ń jẹ́ F. F. Bruce sọ pé: “Èyí jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù kò “fi gba ti Bíbélì Septuagint mọ́.”

Bí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ṣe ń tẹ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lọ́wọ́ ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé, wọ́n ń pa á pọ̀ mọ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti ìtumọ̀ Septuagint, òun ló wá para pọ̀ di odindi Bíbélì tá à ń lò báyìí.

BÍBÉLÌ LÁTÌN VULGATE

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n parí kíkọ Bíbélì, onímọ̀ nípa ẹ̀sìn kan tó ń jẹ́ Jerome túmọ̀ Bíbélì sí èdè Látìn, ìtumọ̀ yìí la wá mọ̀ sí Látìn Vulgate. Àmọ́, wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì sí èdè Látìn tẹ́lẹ̀, kí wá nìdí tí wọ́n fi ní láti ṣe ìtúmọ̀ míì? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The International Standard Bible Encyclopedia ṣàlàyé pé: Ńṣe ni Jerome fẹ́ ṣàtúnṣe “àwọn àṣìtúmọ̀, àṣìṣe tó hàn gbangba, àtàwọn àfikún àti àyọkúrò tí kò pọn dandan.”

Jerome ṣàtúnṣe àwọn àṣìṣe yẹn. Àmọ́ nígbà tó yá, ṣọ́ọ̀ṣì ṣe àṣìṣe tó burú jù lọ nínú ìtàn! Wọ́n sọ pé ìtumọ̀ Bíbélì Látìn Vulgate nìkan làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ máa lò, àṣẹ yẹn sì wà bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún! Dípò tí wọ́n á fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye Bíbélì, ńṣe ni wọ́n sọ Bíbélì Vulgate di ìwé táwọn èèyàn ò lè kà torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ èdè Látìn kà rárá.

ÀWỌN ÌTUMỌ̀ BÍBÉLÌ TUNTUN Ń PỌ̀ SÍ I

Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì, irú bí Bíbélì Syriac Peshitta táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìnlá ni wọ́n tó sapá gan-an láti mú káwọn èèyàn lè rí Ìwé Mímọ́ kà ní èdè abínibí wọn.

Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìnlá ń parí lọ, ọ̀gbẹ́ni John Wycliffe nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ èdè táwọn èèyàn ilẹ̀ yẹn mọ̀ dáadáa. Nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n bọ́ lọ́wọ́ èdè Látìn tó ti di èdè àtijọ́ táwọn èèyàn ò sọ mọ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí ọ̀gbẹ́ni Johannes Gutenberg fi mú kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà tẹ̀wé yára sí i, èyí ló mú kó rọrùn fáwọn onímọ̀ nípa Bíbélì láti ṣe àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tuntun jáde lóríṣiríṣi èdè táwọn èèyàn ń sọ nílẹ̀ Yúróòpù, tí wọ́n sì pín in kiri.

Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, àwọn alátakò ń ṣàròyé pé kò sídìí láti ní ju Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì kan ṣoṣo lọ. Àlùfáà ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejìdínlógún tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John Lewis kọ̀wé pé: “Èdè máa ń yí pa dà, torí náà ó pọn dandan ká máa ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ ká lè ṣàtúnṣe rẹ̀, èyí máa jẹ́ kọ́rọ̀ inú rẹ̀ bóde mu, kó sì yéni.”

Lóde òní, àwọn onímọ̀ nípa Bíbélì máa ń ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tọ́jọ́ wọn ti pẹ́. Ìdí ni pé wọ́n ti wá lóye àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ dáadáa àti pé lẹ́nu àìpẹ́ yìí wọ́n ti rí ọ̀pọ̀ Bíbélì àfọwọ́kọ ayé ìgbàanì tó wúlò gan-an. Èyí ti jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ìtumọ̀ tó péye tó sì bá Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu dáadáa.

Torí náà, àwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní wúlò gan-an. Síbẹ̀ náà, ó ṣì yẹ ká ṣọ́ra fún àwọn kan lára wọn o.a Àmọ́ tó bá jẹ́ ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run ló mú káwọn tó ṣe àtúnṣe Bíbélì kan ṣe é, á jẹ́ pé ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ṣe máa ṣe wá láǹfààní tó pọ̀.

Tó o bá fẹ́ ka Bíbélì ní èdè rẹ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí lórí ẹ̀rọ alágbèéká rẹ, lọ sí www.jw.org/yo. Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE >BÍBÉLÌ.

a Wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Bíbélì Tí Wọ́n Túmọ̀ Lọ́nà Tó Dára?” nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2008.

Orúkọ Mímọ́ Ọlọ́run Nínú Bíbélì

Orúkọ Ọlọ́run tó fara hàn nínú àjákù Bíbélì Septuagint ti ìgbà ayé Jésù

Orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú àjákù Bíbélì Septuagint tìgbà ayé Jésù

Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lo orúkọ mímọ́ Ọlọ́run tó ń jẹ́ Jèhófà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ọ̀pọ̀ lára Bíbélì Gẹ̀ẹ́sì tòde òní ni kò lo orúkọ yẹn. Ńṣe ni wọ́n fi “Olúwa” rọ́pò rẹ̀. Ọ̀kan lára ìdí táwọn atúmọ̀ èdè kan sọ pé ó fà á ni pé lẹ́tà Hébérù mẹ́rin (YHWH) tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run, kò fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì, ìyẹn Greek Septuagint. Àmọ́ ṣé òótọ́ ni?

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, wọ́n rí àjákù Bíbélì Septuagint tó ti pẹ́ gan-an tó ti wà láti ìgbà ayé Jésù. Orúkọ mímọ́ Ọlọ́run lédè Hébérù wà nínú àwọn àjákù náà. Ó jọ pé nígbà tó yá, àwọn adàwékọ yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò, wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà Kyʹri·os tó túmọ̀ sí “Olúwa” rọ́pò rẹ̀. Àmọ́ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sáwọn ibi tó yẹ kó wà nínú Ìwé Mímọ́.

Ṣé Wọ́n Ti Yí Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì Pa Dà?

Àkájọ Ìwé Òkun Òkú Aísáyà

Àkájọ Ìwé Òkun Òkú Aísáyà tó ti wà láti ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000]. Ó bá ohun tó wà nínú Bíbélì mu lóde òní

Àwọn tó ṣe àdàkọ Bíbélì ṣe àwọn àṣìṣe kọ̀ọ̀kan lóòótọ́. Àmọ́ kò sí ìkankan nínú àwọn àṣìṣe náà tó yí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì pa dà. “Kò sí ìkankan lára àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ táwọn Kristẹni gbà gbọ́ tí à ń ṣe iyèméjì nípa rẹ̀.” ​—Our Bible and the Ancient Manuscripts.

Àṣìṣe tó mọ níwọ̀n làwọn adàwékọ Júù ṣe. “Àwọn Júù ìgbà ayé àwọn Kristẹni ìjímìjí tó ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣe é lọ́nà tó pé pérépéré.” ​—Second Thoughts on the Dead Sea Scrolls.

Bí àpẹẹrẹ, àkájọ ìwé Aísáyà kan tí wọ́n rí láàárín àwọn Àkájọ Òkun Òkú ti fi ẹgbẹ̀rún ọdún [1,000] wà ṣáájú èyí tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín òun àti èyí tí à ń lò lónìí? “Wọn kì í sábà fi ọ̀rọ̀ kún un tàbí kí wọ́n yọ ọ́ kúrò.”​—The Book. A History of the Bible.

Àwọn adàwékọ tí kò fara balẹ̀ máa ń ṣe àwọn àṣìṣe bíi kí wọ́n gbé lẹ́tà, ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn síra, ó sì máa ń rọrùn láti tètè rí àwọn àṣìṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sí ṣàtúnṣe rẹ̀. “Yàtọ̀ sí Bíbélì Májẹ̀mú Tuntun kò tún sí ìwé ayé ìgbàanì kankan tí wọ́n ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ fínnífínní bẹ́ẹ̀.” ​—The Books and the Parchments.

“Ọkàn àwọn onígbàgbọ́ tó fẹ́ràn Bíbélì balẹ̀ gan-an pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì pé síbẹ̀ gẹ́lẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì àfọwọ́kọ ayé ìgbàanì bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe àdàkọ rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà tí wọ́n sì ti tún-un tẹ̀ láìmọye ìgbà.” —The Book. A History of the Bible.

Ṣé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ti yí pa dà? Rárá ni ìdáhùn náà!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́