Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
3 Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú
Ọ̀SẸ̀ FEBRUARY 27, 2017–MARCH 5, 2017
7 “Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Kí O sì Máa Ṣe Rere”
Àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2017. Ó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà ìṣòro. Àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ tó gbáyé láyé àtijọ́ máa jẹ́ ká rí bá a ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á ràn wá lọ́wọ́, wọ́n á sì jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe láti yanjú ìṣòro wa àti bá a ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́.
Ọ̀SẸ̀ MARCH 6-12, 2017
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, àá rí bá a ṣe lè mọyì òmìnira tí Ọlọ́run fún wa àti bá a ṣe lè lò ó lọ́nà táá fògo fún Jèhófà tó fún wa lẹ́bùn náà. Ó tún máa jẹ́ ká rí bá a ṣe lè fọ̀wọ̀ wọ àwọn míì tí wọ́n bá ṣèpinnu.
Ọ̀SẸ̀ MARCH 13-19, 2017
17 Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Ẹni Tó Mẹ̀tọ́mọ̀wà
Ọ̀SẸ̀ MARCH 20-26, 2017
22 O Lè Jẹ́ Amẹ̀tọ́mọ̀wà Bí Kò Bá Tiẹ̀ Rọrùn
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn jẹ́ ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ á jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí láti mọ̀wọ̀n ara ẹni àti ohun tí kò túmọ̀ sí. Àpilẹ̀kọ kejì sọ bá a ṣe lè mọ̀wọ̀n ara wa kódà bí kò bá tiẹ̀ rọrùn.
Ọ̀SẸ̀ MARCH 27, 2017–APRIL 2, 2017
27 Fi ‘Nǹkan Wọ̀nyí Lé Àwọn Olùṣòtítọ́ Lọ́wọ́’
Bí ìran kan ṣe ń darúgbó tí ìran míì sì ń bọ́ sójú ọpọ́n ló ń di dandan pé kí wọ́n dá àwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa bójú tó iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run. Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò bí àwọn tó ti dàgbà àtàwọn tí wọ́n faṣẹ́ lé lọ́wọ́ ṣe lè ṣiṣẹ́ pọ̀ kóhun gbogbo lè máa lọ déédéé.
32 Ǹjẹ́ O Mọ̀?