Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
3 Ìtàn Ìgbésí Ayé—Mo Bá Àwọn Ọlọ́gbọ́n Rìn, Mo sì Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Wọn
Ọ̀SẸ̀ MAY 1-7, 2017
8 Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Tí Ọlá Tọ́ Sí
Ó ṣe pàtàkì káwa Kristẹni mọ àwọn tó yẹ ká bọlá fún, àti ọ̀nà tó tọ́ tó sì yẹ ká gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn wo gan-an ni ọlá tọ́ sí? Kí sì nìdí tó fi yẹ ká bọlá fún wọn? Àpilẹ̀kọ yìí máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, á sì jẹ́ ká rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn bọlá fún ẹni tí ọlá tọ́ sí.
Ọ̀SẸ̀ MAY 8-14, 2017
13 Lo Ìgbàgbọ́—Kó O Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání!
Bíbélì sọ pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìnípinnu, ó yẹ ká mọ béèyàn ṣe ń ṣèpinnu. Àmọ́, kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání? Kí ló máa jẹ́ ká lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání? Ǹjẹ́ a lè yí ìpinnu kan tá a ti ṣe pa dà? A máa rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè náà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
Ọ̀SẸ̀ MAY 15-21, 2017
18 Fi Ọkàn Pípé Pérépéré Sin Jèhófà!
Ọ̀SẸ̀ MAY 22-28, 2017
23 Ṣé Wàá Fọkàn sí Àwọn Ohun Tá A Ti Kọ Sílẹ̀?
Torí pé aláìpé ni wá, gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe. Àmọ́ ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò lè wu Jèhófà ni? Nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí, a máa jíròrò àpẹẹrẹ àwọn ọba Júdà mẹ́rin, àá sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn àṣìṣe tí wọ́n ṣe, títí kan àwọn àṣìṣe tó rinlẹ̀ tí wọ́n ṣe. Láìfìyẹn pè, Jèhófà ṣì gbà pé wọ́n fi ọkàn tó pé pérépéré sin òun. Ṣé Ọlọ́run máa gbà pé àwa náà ń fi ọkàn tó pé pérépéré sin òun, bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣàṣìṣe?
28 Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Gidi Tí Àárín Ìwọ àti Ọ̀rẹ́ Rẹ Bá Fẹ́ Dàrú