Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ JULY 31, 2017–AUGUST 6, 2017
4 Jèhófà Ń Tù Wá Nínú Nínú Gbogbo Ìpọ́njú Wa
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa là ń kojú ìṣòro, Jèhófà máa ń pèsè ìtùnú tá a nílò. Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn nǹkan tí Jèhófà pèsè láti tù wá nínú nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.
Ọ̀SẸ̀ AUGUST 7-13, 2017
9 Máa Fọkàn sí Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
Àpilẹ̀kọ yìí máa ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa oníṣòwò kan tó ń wá péálì àti bá a ṣe lè fi àwọn ẹ̀kọ́ náà sílò. Bákan náà, a tún máa rí ọwọ́ tó yẹ ká fi mú iṣẹ́ ìwàásù táwa Kristẹni gbà àti ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a ti kọ́ látọdún yìí wá.
14 Ọkàn Àwọn Èèyàn Ló Ṣe Pàtàkì, Kì Í Ṣe Ìrísí Wọn
16 Ṣé Wàá Yanjú Èdèkòyédè Kí Àlàáfíà Lè Jọba?
21 ‘Ìbùkún Ni fún Ìlóyenínú Rẹ’
Ọ̀SẸ̀ AUGUST 14-20, 2017
22 Pọkàn Pọ̀ Sórí Ọ̀rọ̀ Tó Ṣe Pàtàkì Jù
Ọ̀SẸ̀ AUGUST 21-27, 2017
Kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé lè mú ká gbàgbé ohun tó ṣe pàtàkì. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù ni bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run, àá sì tún kọ́ bá a ṣe lè fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀.
32 ǸJẸ́ O MỌ̀?