Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
3 Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Tọ́kì
Ọ̀SẸ̀ AUGUST 28, 2017–SEPTEMBER 3, 2017
Àpilẹ̀kọ yìí sọ bá a ṣe lè lo àwọn ohun ìní wa láti “yan ọ̀rẹ́” ní ọ̀run. (Lúùkù 16:9) Ó tún ṣàlàyé ohun tá a lè ṣe tí ètò ìṣòwò ayé yìí kò fi ní sọ wá dẹrú àti bá a ṣe lè fayé wa sin Jèhófà.
Ọ̀SẸ̀ SEPTEMBER 4-10, 2017
12 ‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’
Kí ni Kristẹni kan lè ṣe tó bá ṣẹlẹ̀ pé èèyàn rẹ̀ kú láìròtẹ́lẹ̀? Jèhófà mọ̀ pé a nílò ìtùnú, torí náà ó ń tù wá nínú nípasẹ̀ Jésù Kristi ọmọ rẹ̀, nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́ àti ìjọ Kristẹni. Àpilẹ̀kọ yìí sọ bá a ṣe lè rí ìtùnú àti bá a ṣe lè tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú.
Ọ̀SẸ̀ SEPTEMBER 11-17, 2017
17 Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Yin Jèhófà?
Sáàmù 147 rọ àwa èèyàn Ọlọ́run léraléra pé ká yin Jèhófà. Kí ló wú onísáàmù náà lórí tó fi ní ká máa yin Jèhófà? A máa rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí, àá sì tún rí ìdí tó fi yẹ kó máa wù wá láti yin Ọlọ́run wa.
Ọ̀SẸ̀ SEPTEMBER 18-24, 2017
22 Jèhófà Máa Jẹ́ Kí Àwọn Ìpinnu Rẹ Yọrí Sí Rere
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ayọ̀ wọn ò sì lẹ́gbẹ́. Ṣé ó wù ẹ́ kíwọ náà ṣe bíi tiwọn? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá rí àwọn ìmọ̀ràn tá a gbé ka Ìwé Mímọ́. Tó o bá fi wọ́n sílò, á jẹ́ kó o pinnu ohun tí wàá fi ayé rẹ ṣe, á sì jẹ́ kí ayé rẹ ládùn kó sì lóyin.