Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—“Ẹ Máa Ṣiṣẹ́ Ìgbàlà Yín Yọrí”
“Lọ́nà tí ẹ ń gbà ṣègbọràn nígbà gbogbo, . . . ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.”—FÍLÍ. 2:12.
ORIN: 133, 135
1. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn ṣèrìbọmi? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
ẸGBẸẸGBẸ̀RÚN àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún. Àwọn tó pọ̀ jù lára wọn ni kò tíì pé ọmọ ogún ọdún, àwọn míì ò sì tíì pé ọdún mẹ́tàlá. Inú òtítọ́ ni wọ́n ti tọ́ àwọn kan lára wọn dàgbà. Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tìẹ rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a gbóríyìn fún ẹ gan-an. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé èèyàn gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi kó tó lè di Kristẹni àti pé ìgbésẹ̀ pàtàkì ló jẹ́ téèyàn bá máa rí ìgbàlà.—Mát. 28:19, 20; 1 Pét. 3:21.
2. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o bẹ̀rù tàbí fà sẹ́yìn láti ya ara rẹ sí mímọ́?
2 Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ àǹfààní lo máa ní nínú ètò Ọlọ́run lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, àmọ́ àwọn ojúṣe kan wà tó máa já lé ẹ léjìká. Irú ojúṣe wo? Lọ́jọ́ tó o ṣèrìbọmi, wọ́n bi ẹ́ pé, “Lọ́lá ẹbọ Jésù Kristi, ǹjẹ́ o ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ṣé o sì ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀?” O sì dáhùn pé “Bẹ́ẹ̀ ni” sí ìbéèrè náà. Ìrìbọmi tó o ṣe fi hàn pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. O tipa bẹ́ẹ̀ ṣèlérí fún Jèhófà pé wàá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé ìfẹ́ rẹ̀ ló máa gbawájú láyé rẹ. Ìlérí tó o ṣe yẹn kì í ṣe ohun ṣeréṣeré. Àmọ́, ṣó yẹ kó o kábàámọ̀ pé o ṣerú ìlérí bẹ́ẹ̀? Rárá, kò sídìí tó fi yẹ kó o kábàámọ̀. Bó o ṣe fayé rẹ fún Jèhófà kì í ṣe àṣìṣe rárá. Ẹ gbọ́ ná, ta lèèyàn ò bá fayé ẹ̀ fún bí kò ṣe Jèhófà? Abẹ́ Sátánì lẹni tí kò bá fayé rẹ̀ fún Jèhófà wà. Sátánì ò láàánú èèyàn lójú, kò sì fẹ́ kó o rí ìgbàlà. Kódà, inú rẹ̀ máa dùn tó o bá pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun, torí pé ohun tó fẹ́ ni pé kó o wà lọ́dọ̀ òun dípò kó o fara rẹ sábẹ́ àkóso Ọlọ́run.
3. Àwọn ìbùkún wo lo máa rí tó o bá yara rẹ sí mímọ́?
3 Ọ̀pọ̀ ìbùkún ni wàá rí tó o bá kọjú ìjà sí Èṣù, tó o yara rẹ sí mímọ́ tó o sì ṣèrìbọmi. Ní báyìí tó o ti fayé rẹ fún Jèhófà, ìwọ náà lè fi ìdánilójú sọ pé: “Jèhófà ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ mi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe?” (Sm. 118:6) Kò sóhun tó dáa tó pé kó o fayé rẹ sin Jèhófà kó o sì ní ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀.
OJÚṢE RẸ NI
4, 5. (a) Kí nìdí tá a fi sọ pé ojúṣe rẹ ni láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ ṣẹ? (b) Àwọn ìpèníjà wo ni kò yọ àgbàlagbà sílẹ̀?
4 Ní báyìí tó o ti ṣèrìbọmi, ojúṣe rẹ ni láti mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ gún régé. Kò dà bí ilé tàbí ilẹ̀ tí ọmọ kan lè jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Torí náà, ìwọ lo máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí, ká tiẹ̀ ló o ṣì ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ. Kí nìdí tó fi yẹ kó o fi kókó yìí sọ́kàn? Ìdí ni pé òní la rí kò sẹ́ni tó mọ̀la, o ò mọ ìpèníjà tó lè dé lọ́jọ́ iwájú. Àpẹẹrẹ kan ni tàwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá nígbà tí wọ́n ṣèrìbọmi. Bí wọ́n ṣe ń dàgbà sí i, ó ṣeé ṣe kí ìmọ̀lára wọn àtàwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Ọmọbìnrin kan tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún sọ pé: “Bóyá ni ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan máa sọ pé òfin Jèhófà ti le jù kìkì nítorí pé kò jẹ kéèkì ọjọ́ ìbí ọmọ ilé ìwé rẹ̀. Àmọ́ bó ṣe ń dàgbà sí i, tí ìmọ̀lára rẹ̀ láti ní ìbálòpọ̀ sì ń lágbára sí i, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ kó dá òun lójú pé pípa òfin Jèhófà mọ́ lohun tó bọ́gbọ́n mu jù.”
5 Kì í ṣe àwọn ọ̀dọ́ nìkan ni ò mọ ìpèníjà tó lè dé lọ́jọ́ iwájú. Kódà, àwọn tó ti dàgbà kí wọ́n tó ṣèrìbọmi náà máa ń kojú àwọn ìṣòro tí wọn ò rò tẹ́lẹ̀. Lára ohun tó lè dán ìgbàgbọ́ wọn wò ni àìlera, àìníṣẹ́ lọ́wọ́ tàbí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé gbogbo wa pátá la máa kojú àwọn ipò tó máa dán ìgbàgbọ́ wa wò, yálà a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà.—Ják. 1:12-14.
6. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kó o jólóòótọ́ sí Jèhófà yálà àwọn míì ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Kí lo rí kọ́ nínú Fílípì 4:11-13?
6 Tó o bá fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, o gbọ́dọ̀ máa rántí pé o ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé bí iná ń jó, bí ìjì ń jà, ìfẹ́ Jèhófà ni wàá ṣe. Lédè míì, ohun tó o sọ ni pé o ò ní fi Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé àti Ọ̀run sílẹ̀, kódà bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí àwọn òbí rẹ kò bá sin Jèhófà mọ́. (Sm. 27:10) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ ṣẹ láìka ohun tó lè ṣẹlẹ̀.—Ka Fílípì 4:11-13.
7. Kí ló túmọ̀ sí pé kó o ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí “pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì”?
7 Jèhófà fẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ òun. Àmọ́ tó ò bá fẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ ìwọ àti Jèhófà já, tó o sì fẹ́ ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí, o gbọ́dọ̀ sapá gan-an. Ìwé Fílípì 2:12 sọ pé: “Ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.” Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé o gbọ́dọ̀ máa ronú bí àárín ìwọ àti Jèhófà á ṣe túbọ̀ gún régé tí wàá sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i láìka ìṣòro yòówù kó yọjú. Má ṣe dá ara rẹ lójú pé mìmì kan ò lè mì ọ́. Rántí pé a rí àwọn kan tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́ tí wọ́n di aláìṣòótọ́. Torí náà, àwọn nǹkan wo lo lè ṣe táá jẹ́ kó o ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí?
Ó ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÓ O MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
8. Ọ̀nà wo lo lè gbà máa dá kẹ́kọ̀ọ́, kí nìdí tó sì fi ṣe pàtàkì?
8 Bí àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ṣe máa ń ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Èyí gba pé kó o máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀, kó o sì máa tẹ́tí sóhun tóun náà ń bá ẹ sọ. Ọ̀nà pàtàkì kan tó o lè gbà máa tẹ́tí sí Jèhófà ni pé kó o máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Ìyẹn ni pé kó o máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tó ò ń kà. Bó o ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́, máa fi sọ́kàn pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò dà bí ìgbà tó ò ń kàwé torí àtiyege nínú ìdánwò. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ dà bíi pé ṣe lò ń rìnrìn-àjò, tó o sì ń wọ̀tún-wòsì kó o lè rí àwọn nǹkan tuntun. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yìí, á jẹ́ kó o lè túbọ̀ mọ àwọn ànímọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Jèhófà ní, wàá tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ Jèhófà, òun náà á sì sún mọ́ ẹ.—Ják. 4:8.
Ṣé o máa ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣé o sì máa ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé? (Wo ìpínrọ̀ 8 sí 11)
9. Àwọn nǹkan wo ló ti mú kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ túbọ̀ nítumọ̀?
9 Ètò Ọlọ́run ti pèsè àwọn ohun tó máa jẹ́ kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó nítumọ̀. Bí àpẹẹrẹ, lórí ìkànnì jw.org/yo, apá kan wà tá a pé ní “Eré Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì” lábẹ́ abala “Àwọn Ọ̀dọ́.” Apá yìí máa jẹ́ kó o lè ronú jinlẹ̀ kó o sì rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì. Ohun míì tó tún wà lórí ìkànnì jw.org/yo ni àrànṣe kan tá a pè ní Atọ́nà Ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń mú kó rọrùn láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé “Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?” Tó o bá ń lo àwọn àrànṣe yìí dáadáa, á jẹ́ kí ohun tó o gbà gbọ́ túbọ̀ dá ẹ lójú, á sì tún jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì. Nínú Jí! April 2009, wàá rí bó o ṣe lè mú kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ túbọ̀ nítumọ̀, lábẹ́ àkòrí náà: “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Kí Bíbélì Kíkà Gbádùn Mọ́ Mi?” Tó o bá fẹ́ ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí, ó ṣe pàtàkì pé kó o máa kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò.—Ka Sáàmù 119:105.
MÁA GBÀDÚRÀ DÉÉDÉÉ
10. Kí nìdí tó fi yẹ kẹ́ni tó ti ṣèrìbọmi máa gbàdúrà déédéé?
10 Bí ìdákẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń mú kó o tẹ́tí sí Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni àdúrà ń mú kó o lè bá a sọ̀rọ̀. Kò yẹ ká wo àdúrà bí àṣà kan lásán tàbí bí oògùn àwúre táwọn èèyàn gbà pé ó ń jẹ́ káwọn rọ́wọ́ mú nínú ohun táwọn ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká mọ̀ pé Jèhófà là ń bá sọ̀rọ̀ tá a bá ń gbàdúrà. Jèhófà fẹ́ kó o bá òun sọ̀rọ̀. (Ka Fílípì 4:6.) Torí náà, tó o bá ní ìdààmú ọkàn èyíkéyìí, Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé kó o “ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà.” (Sm. 55:22) Ṣó o gbà lóòótọ́ pé àdúrà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa fi dá ẹ lójú pé àdúrà ti ran àwọn lọ́wọ́. Á ran ìwọ náà lọ́wọ́, torí náà jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa gbàdúrà!
11. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lójoojúmọ́?
11 Kì í ṣe ìgbà tó o bá nílò ìrànwọ́ Jèhófà nìkan ló yẹ kó o máa gbàdúrà. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.’ (Kól. 3:15) Nígbà míì, àwọn ìṣòro wa lè gbà wá lọ́kàn débi pé a ò ní rántí àwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run ṣe fún wa. Torí náà, o ò ṣe pinnu pé lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, wàá máa ronú nípa àwọn nǹkan mẹ́ta, ó kéré tán, tí Jèhófà ṣe fún ẹ? Lẹ́yìn náà, gbàdúrà kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fáwọn nǹkan náà. Abigail, ọ̀dọ́bìnrin kan tí kò tíì pé ogún ọdún, tó ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún méjìlá [12] sọ pé: “Lójú tèmi, ẹni tí ọpẹ́ yẹ jù lọ láyé àti lọ́run ni Jèhófà. Ìgbà gbogbo ló yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àwọn nǹkan rere tó ṣe fún wa. Ohun kan wà tẹ́nì kan sọ tí mo máa ń rántí, ó ní: Tá a bá jí lọ́la tá a sì rí i pé a ti pàdánù àwọn nǹkan tá ò rántí dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún lónìí, kí ló máa ṣẹ́ kù fún wa?”
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O RỌ́WỌ́ JÈHÓFÀ LÁYÉ RẸ
12, 13. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kíwọ alára rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere sí ẹ?
12 Ọba Dáfídì tí Jèhófà dá nídè nínú onírúurú ìṣòro àti wàhálà kọrin pé: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere; aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó sá di í.” (Sm. 34:8) Ẹsẹ yìí sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kíwọ náà rọ́wọ́ Jèhófà láyé rẹ. Tó o bá ń ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, tó o sì ń lọ sípàdé, á túbọ̀ ṣe kedere sí ẹ pé Jèhófà máa ń ti àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lẹ́yìn kí wọ́n lè jólóòótọ́. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, tíwọ náà sì ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó yẹ kó o rí ọwọ́ Jèhófà láyé tìẹ náà. Ǹjẹ́ o lè rántí àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún ọ?
13 Ọ̀nà kan wà tí gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbà tọ́ Jèhófà wò tá a sì rí i pé ẹni rere ni, ìyẹn sì ni bó ṣe mú wa wá sọ́dọ̀ Ọmọ rẹ̀. Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòh. 6:44) Ṣó o gbà pé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Ọ̀dọ́ kan lè ronú pé, ‘Ṣebí Jèhófà ti fa àwọn òbí mi, èmi náà sì tẹ̀ lé wọn, wọ́n ṣáà sọ pé bí ìgbín bá fà, ìkarahun á tẹ̀ lé e.’ Àmọ́ rántí pé nígbà tó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà tó o sì ṣèrìbọmi, ṣe lo wọnú àdéhùn pẹ̀lú Jèhófà, tó o sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, o kì í ṣe àjèjì sí Jèhófà, ó mọ̀ ẹ́ dáadáa. Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni ó mọ̀.” (1 Kọ́r. 8:3) Torí náà, jẹ́ kí inú rẹ máa dùn pé o wà nínú ètò Jèhófà, kó máa dán gbinrin lọ́kàn rẹ.
14, 15. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára?
14 Wàá tún mọ̀ pé ẹni rere ni Jèhófà tó o bá ń kíyè sí bó ṣe ń fún ẹ nígboyà láti wàásù fáwọn èèyàn yálà lóde ẹ̀rí tàbí nílé ìwé. Àwọn ọ̀dọ́ kan kì í lè wàásù fáwọn ojúgbà wọn níléèwé. Bóyá irú ẹ̀ ti ṣe ìwọ náà rí. O ò mọ irú ojú táwọn ọmọ iléèwé rẹ máa fi wo ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ bá wọn sọ. Ká sòótọ́, kéèyàn wàásù fún ọmọ iléèwé kan ṣoṣo rọrùn ju kéèyàn wàásù fún àgbájọ àwọn ọmọ iléèwé. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?
15 Lákọ̀ọ́kọ́, ronú nípa ìdí tó o fi gbà pé òótọ́ lohun tó o gbà gbọ́. Ṣó o ti lo àrànṣe tá a pè ní Atọ́nà Ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lórí ìkànnì jw.org/yo? Tó ò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀, gbìyànjú rẹ̀ wò. A dìídì ṣe é kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni, á jẹ́ kó o ronú lórí ohun tó o gbà gbọ́, ìdí tó o fi gbà á gbọ́ àti bó o ṣe lè ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ fáwọn míì. Tí ohun tó o gbà gbọ́ bá dá ẹ lójú, tó o sì múra sílẹ̀ dáadáa, á yá ẹ lára láti sọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn.—Jer. 20:8, 9.
16. Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì?
16 Kódà lẹ́yìn tó o ti múra sílẹ̀ dáadáa, ó lè má rọrùn fún ẹ láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì. Arábìnrin ọlọ́dún méjìdínlógún [18] kan tó ṣèrìbọmi nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá [13] sọ pé, “Ohun tí mo gbà gbọ́ dá mi lójú, àmọ́ àwọn ìgbà míì wà tí kì í rọrùn fún mi láti wàásù fáwọn ọmọ kíláàsì mi.” Kí ló wá ṣe? Ó sọ pé: “Ṣe ni mo máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi láìjẹ́ kí wọ́n fura pé mo fẹ́ wàásù fún wọn. Ó ṣe tán, àwọn náà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe, kò yẹ kẹ́rù ba èmi náà láti sọ ohun tí mò ń ṣe. Nígbà míì mo lè sọ pé, ‘Lọ́jọ́ kan tí mò ń kọ́ ẹnì kan ní Bíbélì, ó ṣẹlẹ̀ pé . . . ’ Lẹ́yìn tí mo bá ti sọ̀yẹn, màá wá máa bá ọ̀rọ̀ mi lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ Bíbélì ni mo sábà máa ń sọ tẹ̀ lé e, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń fẹ́ mọ ohun tí mò ń ṣe nígbà tí mo bá ń kọ́ àwọn èèyàn ní Bíbélì, wọ́n sì máa ń da ìbéèrè bò mí. Bí mo ṣe ń lo ọ̀nà yẹn ti mú kó rọrùn fún mi láti wàásù fáwọn ọmọ kíláàsì mi, inú mi sì máa ń dùn gan-an!”
17. Kí lohun míì táá jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì?
17 Tó o bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn tó o sì fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, ó ṣeé ṣe káwọn náà bọ̀wọ̀ fún ẹ kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ. Arábìnrin Olivia tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] tó sì ṣèrìbọmi kó tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá sọ pé: “Ìgbà gbogbo ni mo máa ń ronú pé àwọn èèyàn á kà mí sí agbawèrèmẹ́sìn tí mo bá bá wọn sọ̀rọ̀ Bíbélì, ìyẹn sì máa ń mú kẹ́rù bà mí.” Nígbà tó yá, ó yí èrò rẹ̀ pa dà. Dípò táá fi máa bẹ̀rù ohun táwọn èèyàn máa rò nípa rẹ̀, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò mọ nǹkan kan nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwa náà la lè jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ gan-an. Torí náà, ohun tá a bá ṣe ló máa pinnu bóyá wọ́n á gbọ́ tàbí wọn ò ní gbọ́. Tá a bá ń tijú àtisọ ohun tá a gbà gbọ́ fún wọn, tí ẹ̀rù ń bà wá tàbí tí ohùn wa ń gbọ̀n nígbà tá à ń bá wọn sọ̀rọ̀, ojú wo ni wọ́n fi máa wò wá? Ṣé wọn ò ní sọ pé ohun tá à ń sọ kò dá wa lójú? Wọ́n tiẹ̀ lè má fẹ́ gbọ́ wa. Àmọ́, tá a bá fìgboyà sọ̀rọ̀, tí ara wa sì balẹ̀ nígbà tá à ń ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa fara balẹ̀ tẹ́tí sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
MÁA ṢIṢẸ́ ÌGBÀLÀ RẸ YỌRÍ
18. Kí làwọn nǹkan táá mú kó o lè ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí?
18 Bá a ṣe jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, o ti rí i pé iṣẹ́ ńlá ni tó o bá máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí. Ó ṣe kedere pé o gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì kó o sì máa ṣàṣàrò, kó o máa gbàdúrà, kó o sì máa ronú nípa àwọn ìbùkún tó o ti rí. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, á jẹ́ kó o túbọ̀ mọyì àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà, wàá sì máa fi ìdánilójú sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì.—Ka Sáàmù 73:28.
19. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kó o ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí?
19 Jésù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Mát. 16:24) Kò sí àní-àní pé kẹ́nì kan tó lè di ọmọlẹ́yìn Kristi, ó gbọ́dọ̀ ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìbùkún lo máa rí nísinsìnyí, wàá sì tún gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé kó o rí i dájú pé o ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ yọrí!