ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp18 No. 1 ojú ìwé 8-9
  • 1 Ó Ń Jẹ́ Ká Yẹra fún Ìṣòro

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1 Ó Ń Jẹ́ Ká Yẹra fún Ìṣòro
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • MÍMU ỌTÍ PARA
  • ÌṢEKÚṢE
  • Ṣé Ó Burú Kéèyàn Máa Tage?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ló Burú Nínú Títage?
    Jí!—1998
  • Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ọtí Lo Fi Ń Wò Ó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Ẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Ọtí
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
wp18 No. 1 ojú ìwé 8-9
Obìnrin kan ń mutí, lẹ́yìn náà ó ronú lórí ìlànà Bíbélì

1 Ó Ń Jẹ́ Ká Yẹra fún Ìṣòro

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú rẹ̀ jẹ́ ìmísí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.” (2 Tímótì 3:16) Ṣé òótọ́ ni? Wo bí ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ṣe ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti tètè jáwọ́ nínú àṣà tí ò dáa, kó tó wọ̀ wọ́n lẹ́wù.

MÍMU ỌTÍ PARA

Delphine, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú gbà pé àníyàn tó gba òun lọ́kàn ti fẹ́ mú kí òun máa mutí para. Bíbélì kò sọ pé ó burú kéèyàn mu ọtí níwọ̀nba, àmọ́ ó sọ pé: ‘Má ṣe wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri.’ (Òwe 23:20) Ọtí àmupara wà lára ohun tó ń fa ìṣòro tó lágbára bí àìsàn, kì í jẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì, ó sì ń gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lọ́dọọdún. A lè yẹra fún irú àwọn ìṣòro bí èyí tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì.

Delphine tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì. Ó wá sọ pé: “Mo ti wá rí i pé ọtí mímu kò lè yanjú ìṣòro mi. Mo tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà ní Fílípì 4:​6, 7, tó sọ pé: ‘Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.’ Mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà ní alaalẹ́ tí ìrònú bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbà mí lọ́kàn. Mó máa ń sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára mi fún un, títí kan ohun tó ń bí mi nínú, ohun tó ń dùn mí àti ohun tó ń bà mí lẹ́rù, màá sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ní èrò tó dáa. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, màá rí i dájú pé mo gbé gbogbo èrò náà kúrò lọ́kàn. Bí mo ṣe jẹ́ kó mọ́ mi lára láti máa gbàdúrà sí Jèhófà ti jẹ́ kí n máa ronú lórí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti ṣe fún mi dípò kí n máa ronú lórí àwọn ohun tí kò tíì ṣe fún mi. Mo pinnu pé mi ò ní mu ọtí mọ́. Ọkàn mi ti wá balẹ̀ gan-an báyìí, mi ò sì ní fẹ́ kí ohunkóhun tún ba ayọ̀ mi jẹ́.”

ÌṢEKÚṢE

Ìṣekúṣe wà lára olórí nǹkan tó ń fa ìbànújẹ́ àti ìyà. Àmọ́ ìlànà Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ìṣòro yẹn tá a bá mọ àwọn nǹkan tó lè fà wá sínú ẹ̀, irú bí i, kéèyàn máa tage àti kéèyàn máa wo nǹkan tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Samuel sọ pé: “Kì í ṣe ohun tó le rárá láti tage. Ọkàn mi lè má fà sí obìnrin kan, àmọ́ tí mo bá rí i pé ó gba tèmi, ìyẹn máa ń jẹ́ kó rọrùn fún mi láti bá a tage.” Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀sùn kan Samuel pé ó máa ń tage jù, kì í sì í ṣe pé ó ní i lọ́kàn láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wà kúkú bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀ọ́mọ̀ tage. Àmọ́ kò nífẹ̀ẹ́ sí ìwà yìí mọ́. Ó wà sọ pé: “Ìwà yìí léwu gan-an, torí ó máa ń jẹ́ kéèyàn ní ẹ̀mí ìmọtara ẹni nìkan.”

Samuel ka àpilẹ̀kọ kan lórí ìkànnì jw.org, èyí tó wà fún àwọn ọ̀dọ́. Ó wà ronú lórí Òwe 20:​11, tó sọ pé: “Àní nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin kan ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán.” Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe ràn án lọ́wọ́? Samuel rí i pé bí òun ṣe ń tage ò dáa, kò sì fi hàn pé òun níwà mímọ́. Ó wá sọ pé: “Mo tún kọ́ pé ṣe ni ọ̀dọ́ tó bá ń tage ń kó bá ara rẹ̀, torí ó máa bẹ̀rẹ̀ sí í ní àwọn ìwà tó máa sọ ọ́ di ọkọ tàbí ìyàwó tí kò dáa. Mo wá ronú lórí bó ṣe máa rí lára ìyàwó tí mo bá fẹ́ tó bá rí bí mo ṣe ń bá obìnrin míì tage. Torí pé ó rọrùn láti tage kò wá túmọ̀ sí pé kò burú.” Samuel ò báwọn obìnrin tage mọ́. Ìyẹn sì ti ràn án lọ́wọ́ láti yẹra fún ìṣekúṣe.

Àpẹẹrẹ Antonio tún wá léwu ju tàwọn tó kù lọ: Ó ti mọ́ ọn lára láti máa wo àwòrán ìṣekúṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti níyàwó, tó sì nífẹ̀ẹ́ aya ẹ̀ gan-an, kò rọrùn fún un láti fìwà yẹn sílẹ̀. Ó sọ pé bí òun ṣe ronú lórí ẹsẹ Bíbélì tó wà ní 1 Pétérù 5:8 ti ran òun lọ́wọ́ gan-an. Ó kà pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” Antonio sọ pé: “Gbogbo ibi ni àwòrán ìṣekúṣe wà láyé yìí, téèyàn bá sì ti rí i, kì í lọ bọ̀rọ̀ lọ́kàn. Ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ kí n ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdẹwò yìí ti ń wá. Tí mo bá rántí pé ọ̀dọ̀ Sátánì ni ó ti wá, èyí máa ń jẹ́ kí n tètè yẹra fún un. Mo ti wá gbà pé Jèhófà nìkan ló lè ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ‘pa agbára ìmòye mi mọ́, kí n sì máa kíyè sára.’ Èyí ló máa jẹ́ kí n lè gbógun ti ìdẹwò tó ń bá mi jà lọ́kàn, tó sì fẹ́ tú ìgbéyàwó mi ká.” Bíbélì ran Antonio lọ́wọ́, ó sì ti jáwọ́ nínú bó ṣe ń wo àwòrán ìṣekúṣe. Ìyẹn sì ti ràn án lọ́wọ́ láti yẹra fún ìṣòro ńlá tó ṣeé ṣe kó wáyé tí kò bá jáwọ́.

A ti rí i pé Bíbélì ní àwọn ìlànà tí kò ní jẹ́ ká kó sínú ìṣòro tó lágbára. Àmọ́ kí la lè ṣe láti jáwọ́ nínú àṣà tó ti mọ́ra, tí kò sì rọrùn láti fi sílẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀.

Àwọn ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn àṣà tí kò dáa

Obìnrin kan ń mu nǹkan
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́