ÀWỌN OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ ÌRÒYÌN YÌÍ
Ọ̀SẸ̀ APRIL 30, 2018–MAY 6, 2018
3 Ìrìbọmi—Ohun Tó Yẹ Kí Gbogbo Kristẹni Ṣe
Ọ̀SẸ̀ MAY 7-13, 2018
8 Ẹ̀yin Òbí, Ṣé Ẹ̀ Ń Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi?
Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Kí nìdí tí kò fi yẹ kẹ́nì kan fi ìrìbọmi falẹ̀? Kí nìdí táwọn òbí kan fi máa ń sọ pé káwọn ọmọ wọn má tíì ṣèrìbọmi? Àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn míì la máa jíròrò nínú àwọn àpilẹ̀kọ méjì yìí.
13 Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ọ̀SẸ̀ MAY 14-20, 2018
14 Aájò Àlejò Ṣe Pàtàkì Gan-An
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àpọ́sítélì Pétérù sọ fáwọn Kristẹni pé: “Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Pét. 4:9) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí lónìí? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ẹ̀mí aájò àlejò? Tẹ́nì kan bá fẹ́ gbà wá lálejò ńkọ́, kí ló yẹ ká fi sọ́kàn? A máa rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
19 Ìtàn Ìgbésí Ayé—Jèhófà Ò Já Mi Kulẹ̀ Rí
Ọ̀SẸ̀ MAY 21-27, 2018
23 Báwo Ni Ìbáwí Ṣe Ń Fi Hàn Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa?
Ọ̀SẸ̀ MAY 28, 2018–JUNE 3, 2018
28 ‘Fetí sí Ìbáwí Kó O sì Di Ọlọ́gbọ́n’
Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló ń jẹ́ kó bá wa wí. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń bá wa wí? Irú ojú wo ló yẹ ká fi wo ìbáwí tí Jèhófà bá fún wa? Báwo la ṣe lè máa kó ara wa níjàánu? Inú àwọn àpilẹ̀kọ yìí la ti máa rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí.