Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ AUGUST 6-12, 2018
3 “Ìjọba Mi Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé Yìí”
Ọ̀SẸ̀ AUGUST 13-19, 2018
8 Ká Jẹ́ Ọ̀kan Bí Jèhófà àti Jésù Ṣe Jẹ́ Ọ̀kan
Nígbà ayé Jésù, ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀yà àti ipò láwùjọ mú káwọn èèyàn yapa síra wọn. Nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì, a máa rí bí Jésù ṣe kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wà níṣọ̀kan, kí wọ́n sì borí ẹ̀tanú tó lè fa ìpínyà láàárín wọn. A sì máa rí bí àpẹẹrẹ wọn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti wà níṣọ̀kan nínú ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí.
Ọ̀SẸ̀ AUGUST 20-26, 2018
16 Máa Fi Àwọn Òfin àti Ìlànà Jèhófà Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ
A gbọ́dọ̀ kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa dáadáa kó lè tọ́ wa sọ́nà. Jèhófà ti fún wa láwọn òfin àti ìlànà tá a lè fi kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa, ká sì lè fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan wò ó. Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò bá a ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé wa.
Ọ̀SẸ̀ AUGUST 27, 2018–SEPTEMBER 2, 2018
21 Ẹ Jẹ́ “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn” Kẹ́ Ẹ Lè Fògo fún Jèhófà
Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn kí wọ́n lè fògo fún Ọlọ́run. Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe kí ìmọ́lẹ̀ wa lè máa tàn, tá a bá sì ṣe wọ́n, ó dájú pé ìmọ́lẹ̀ wa á túbọ̀ máa tàn.
26 Ìtàn Ìgbésí Ayé—Gbogbo Ìgbà Ni Jèhófà Máa Ń Tù Mí Nínú