LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA
Bí Iṣẹ́ Fífúnrúgbìn Ìjọba Náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Lórílẹ̀-Èdè Pọ́túgà
BÍ ÌGBÌ òkun Àtìláńtíìkì ṣe ń bì lu ọkọ̀ òkun kan tó ń lọ sí Yúróòpù, inú ọ̀kan lára àwọn èrò ọkọ̀ náà ìyẹn George Young ń dùn bó ṣe ń ronú lórí irúgbìn òtítọ́ tó ti fún lórílẹ̀-èdè Brazil.a Àmọ́ bí ọkọ̀ yẹn ṣe ń lọ, ó tún ń ronú nípa bó ṣe máa fún irúgbìn òtítọ́ yìí níbi tí ètò Ọlọ́run rán an lọ, ìyẹn orílẹ̀-èdè Sípéènì àti Pọ́túgà tí iṣẹ́ ìwàásù náà ò tíì dé. Ó ronú pé tóun bá débẹ̀, òun á ṣètò báwọn èèyàn ṣe máa gbọ́ àwọn àsọyé Arákùnrin J. F. Rutherford, òun á sì pín ìwé àṣàrò kúkúrú tí ó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300,000]!
George Young rin ọ̀pọ̀ ìrìn-àjò nínú ọkọ̀ ojú omi kó lè wàásù fáwọn èèyàn
Nígbà tí Arákùnrin Young máa dé ìlú Lisbon lọ́dún 1925, ibi tó fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀. Àwọn kan dìtẹ̀ gbàjọba lọ́dún 1910, rògbòdìyàn téyìí sì fà ò tíì tán nílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ìyípadà bá ètò ìjọba wọn, agbára tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ní sì dín kù gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aráàlú túbọ̀ lómìnira, síbẹ̀ orílẹ̀-èdè náà ò fara rọ rárá.
Bí Arákùnrin Young ṣe ń bá ètò lọ lórí báwọn èèyàn ṣe máa gbọ́ àsọyé Arákùnrin Rutherford, ṣe ni ìjọba da àwọn sójà sígboro torí pé àwọn kan tún gbìyànjú láti dìtẹ̀ gbàjọba. Ẹni tó jẹ́ akọ̀wé Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti Ilẹ̀ Òkèèrè tiẹ̀ kìlọ̀ fún Arákùnrin Young pé àwọn èèyàn máa takò ó gan-an. Síbẹ̀ Arákùnrin Young ò fìyẹn pè, ṣe ló ń báṣẹ́ lọ. Ó wá lọ béèrè bóyá òun lè lo gbọ̀ngàn ìṣeré Camões Secondary School, wọ́n sì fún un láyè.
May 13 lọjọ́ tí wọ́n ṣètò fún àsọyé Arákùnrin Rutherford, ara àwọn èèyàn sì ti wà lọ́nà fún ọjọ́ yẹn. Àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn àkọlé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ tí wọ́n lẹ̀ sára ilé ni wọ́n fi polongo àsọyé náà tí àkòrí ẹ̀ jẹ́, “Bó O Ṣe Lè Gbé Títí Láé Lórí Ilẹ̀ Ayé.” Inú bí àwọn alátakò, ni wọ́n bá sáré lọ gbé ìròyìn kan jáde nínú ìwé ìròyìn wọn, wọ́n sì kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n má tẹ́tí sáwọn “wòlíì èké” tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ̀lú. Àwọn alátakò yẹn tiẹ̀ dúró sẹ́nu ọ̀nà gbọ̀ngàn náà, wọ́n sì pín ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé fáwọn èèyàn pé kí wọ́n má ṣe fetí sáwọn ẹ̀kọ́ Arákùnrin Rutherford.
Àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn já sí torí pé inú gbọ̀ngàn náà kún fọ́fọ́, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] èèyàn ló kóra jọ, kódà nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì míì ni ò ráyè wọlé. Àwọn kan lọ dìrọ̀ mọ́ àkàbà olókùn tó wà níbẹ̀, àwọn míì sì gun orí àwọn nǹkan tó wà nínú gbọ̀ngàn yẹn kí wọ́n lè gbọ́ àsọyé náà.
Àmọ́ nǹkan tún fẹ́ yíwọ́. Àwọn alátakò yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, wọ́n sì ń fọ́ àga mọ́lẹ̀. Síbẹ̀ Arákùnrin Rutherford ò fìyẹn pè, ṣe ló rọra gun orí tábìlì káwọn èèyàn lè gbọ́ ohùn rẹ̀ dáadáa. Nígbà tó fi máa parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní nǹkan bí aago méjìlá òru, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún méjì [1,200] ló forúkọ àti àdírẹ́sì wọn sílẹ̀, kí wọ́n lè máa fi àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì ránṣẹ́ sí wọn. Lọ́jọ́ kejì, ìwé ìròyìn O Século gbé àpilẹ̀kọ kan tó dá lórí àsọyé Arákùnrin Rutherford jáde.
Nígbà tó di September 1925, ètò Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Ilé Ìṣọ́ lédè Potogí jáde lórílẹ̀-èdè Pọ́túgà. (Wọ́n ti kọ́kọ́ tẹ Ilé Ìṣọ́ lédè Potogí jáde lórílẹ̀-èdè Brazil.) Láàárín àkókò yẹn ni Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń jẹ́ Virgílio Ferguson láti Brazil bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bó ṣe máa kó wá sí Pọ́túgà kó lè kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìwàásù náà. Òun àti Arákùnrin Young ti jọ ṣiṣẹ́ nígbà kan rí ní ọ́fíìsì àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà ní Brazil. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Virgílio àti Lizzie ìyàwó rẹ̀ kúrò ní Brazil kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ Arákùnrin Young. Wíwá Arákùnrin Ferguson bọ́ sásìkò gan-an torí pé Arákùnrin Young ò ní pẹ́ fi Pọ́túgà sílẹ̀ lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì tí ètò Ọlọ́run rán an lọ. Lára àwọn orílẹ̀-èdè tó sì ń lọ ni ilẹ̀ Soviet Union.
Ìwé ìgbélùú Lizzie àti Virgílio Ferguson, ọdún 1928
Nígbà tó yá, àwọn ológun dìtẹ̀ gbàjọba ní Pọ́túgà, inúnibíni wá túbọ̀ pọ̀ sí i. Àmọ́ Arákùnrin Ferguson lo ìgboyà, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti dáàbò bo àwùjọ kéréje àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà nígbà yẹn. Kódà, ó fún wọn níṣìírí láti máa báṣẹ́ ìwàásù lọ láìfọ̀tá pè. Ó wá lọ gbàṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba kó lè máa lo ilé rẹ̀ fún ìpàdé ìjọ. Nígbà tó sì di October 1927, wọ́n fún un láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Láàárín ọdún àkọ́kọ́ táwọn ológun gbàjọba, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta [450] èèyàn ní Pọ́túgà ló ń san àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìwé kékeré àtàwọn àṣàrò kúkúrú tún mú kí òtítọ́ Ìjọba náà dé àwọn àgbègbè tó wà lábẹ́ àkóso Pọ́túgà, irú bí Àǹgólà, Azores, Cape Verde, East Timor, Goa, Madeira, àti Mòsáńbíìkì.
Ní nǹkan bí ọdún 1929, Manuel da Silva Jordão tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Pọ́túgà kó wá sílùú Lisbon. Onírẹ̀lẹ̀ ni, iṣẹ́ olùtọ́jú ọgbà ló sì ń ṣe. Nígbà tó ń gbé ní Brazil, ó gbọ́ àsọyé kan tí Arákùnrin Young sọ, ó sì sọ lọ́kàn rẹ̀ pé ‘òtítọ́ rèé.’ Ìtara yìí ló mú kó pinnu láti kọ́wọ́ ti Arákùnrin Ferguson lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà. Kí Manuel lè fìtara kọ́wọ́ ti iṣẹ́ náà, ó di apínwèé-ìsìn-kiri bá a ṣe máa ń pe àwọn aṣáájú-ọ̀nà nígbà yẹn. Ìjọ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ dá sílẹ̀ ní Lisbon túbọ̀ ń gbèrú sí i torí pé ètò tí wọ́n ṣe fún títẹ àwọn ìwé wa àti pínpín wọn kiri fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Arákùnrin àti Arábìnrin Ferguson ní láti pa dà sí Brazil lọ́dún 1934, irúgbìn òtítọ́ tí wọ́n gbìn síbẹ̀ ti ń méso jáde. Láìka gbogbo rògbòdìyàn tó ṣẹlẹ̀ ní Yúróòpù nígbà ogun abẹ́lé ilẹ̀ Sípéènì àti nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, síbẹ̀ àwọn ará jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Láwọn àsìkò kan, ṣe ni ìtara wọn dà bí iná àtùpà tó ń jó lọ́úlọ́ú. Àmọ́ lọ́dún 1947, ètò Ọlọ́run rán John Cooke síbẹ̀, òun sì ni míṣọ́nnárì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì tó máa kọ́kọ́ wá síbẹ̀. Èyí wá mú kí iná ìtara wọn bẹ̀rẹ̀ sí í jó lala. Látìgbà yẹn ni iye àwọn akéde Ìjọba náà ti ń pọ̀ sí i lọ́nà tó kàmàmà. Kódà nígbà tí ìjọba fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1962, iye wọn ṣì ń pọ̀ sí i. Nígbà tó di December 1974 tí wọ́n mú ìfòfindè náà kúrò, iye àwọn akéde tó wà níbẹ̀ ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá [13,000].
Lónìí, àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta [50,000] ló ń wàásù ìhìn rere náà lórílẹ̀-èdè Pọ́túgà àti láwọn erékùṣù míì tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí irú bí Azores àti Madeira. Ó dùn mọ́ni pé lára àwọn akéde tó wà ní Pọ́túgà lónìí ló jẹ́ ìran kẹta lára àwọn tó gbọ́ àsọyé mánigbàgbé tí Arákùnrin Rutherford sọ lọ́dún 1925.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n fìgboyà wàásù ìhìn rere náà. Ṣe ni wọ́n fi hàn pé àwọn jẹ́ “ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn fún Kristi Jésù sí àwọn orílẹ̀-èdè.”—Róòmù 15:15, 16.—Látinú Àpamọ́ Wa ní Pọ́túgà.
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìkórè Ṣì Pọ̀” nínú Ilé Ìṣọ́, May 15, 2014, ojú ìwé 31 àti 32.