Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
Ọ̀SẸ̀ OCTOBER 29, 2018–NOVEMBER 4, 2018
3 “Bí Ẹ Bá Mọ Nǹkan Wọ̀nyí, Aláyọ̀ Ni Yín Bí Ẹ Bá Ń Ṣe Wọ́n”
Kò sí àǹfààní kankan nínú ìmọ̀ téèyàn ní àmọ́ téèyàn ò lò ó. Torí náà, ká tó lè fi ohun tá à ń kọ́ sílò, ó gba pé ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nínú Bíbélì. A máa rí bí wọ́n ṣe wàásù fún onírúurú èèyàn, tí wọ́n gbàdúrà fáwọn míì, tí wọ́n sì fìjà fún Ọlọ́run jà.
8 Ẹ̀yin Àgbàlagbà—Jèhófà Mọyì Iṣẹ́ Yín
Ọ̀SẸ̀ NOVEMBER 5-11, 2018
12 Ẹ Máa Fìfẹ́ Gbé Àwọn Míì Ró
Nǹkan nira gan-an lákòókò tá à ń gbé yìí, àwọn ìṣòro tá à ń kojú sì lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Àmọ́ Jèhófà àti Jésù máa ń fún wa lókun. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ káwa náà máa fún àwọn ará wa lókun, ká sì máa tù wọ́n nínú. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fìfẹ́ hàn sí àwọn ará wa, ká sì gbé wọn ró.
Ọ̀SẸ̀ NOVEMBER 12-18, 2018
17 Aláyọ̀ Ni Àwọn Tó Ń Sin “Ọlọ́run Aláyọ̀”
Ọlọ́run aláyọ̀ ni Jèhófà, ó sì fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ náà láyọ̀. Àmọ́ ṣé a lè láyọ̀ láìka gbogbo ìṣòro tá à ń kojú nínú ayé Sátánì yìí? Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe táá jẹ́ ká ní ayọ̀ tó máa wà pẹ́ títí.
22 Ǹjẹ́ O Mọ Ohun Tí Aago Sọ?
Ọ̀SẸ̀ NOVEMBER 19-25, 2018
23 Alágbára Ńlá Ni Jèhófà, Síbẹ̀ Ó Ń Gba Tẹni Rò
Ọ̀SẸ̀ NOVEMBER 26, 2018–DECEMBER 2, 2018
28 Máa Gba Tàwọn Míì Rò Bíi Ti Jèhófà
Àwọn onímọtara-ẹni-nìkan ló kúnnú ayé yìí, àmọ́ àwa èèyàn Jèhófà yàtọ̀ sí wọn torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an, ìfẹ́ yìí sì máa ń mú ká gba tàwọn míì rò. Nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, a máa rí bí Jèhófà ṣe fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ tó bá di pé ká gba tàwọn míì rò. Nínú àpilẹ̀kọ kejì, a máa rí àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fara wé Jèhófà tó bá di pé ká gba tàwọn míì rò.