ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp19 No. 2 ojú ìwé 3
  • Tí Ìṣòro Bá Pọ̀ Lápọ̀jù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Tí Ìṣòro Bá Pọ̀ Lápọ̀jù
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Gbogbo Nǹkan Bá Tojú Sú Ẹ
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Tí Ẹnì Kan Tó O Fẹ́ràn Bá Kú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
  • Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
  • Ayé Rẹ Ṣì Máa Dùn!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
wp19 No. 2 ojú ìwé 3
Ọ̀dọ́bìnrin kan ń sunkún níbi iṣẹ́

Tí Ìṣòro Bá Pọ̀ Lápọ̀jù

ÌGBÉSÍ ayé máa ń dùn tí nǹkan bá ń lọ dáadáa fúnni. Àmọ́, tí ìṣòro bá pọ̀ lápọ̀jù, ńṣe ni gbogbo nǹkan máa ń súni.

Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìjì líle wáyé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sallya pàdánù èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn nǹkan tó ní, ó sọ pé: “Ìdààmú bá mi, gbogbo nǹkan sì sú mi. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé ẹ̀mí mi ò lè gbé e mọ́.”

Ìṣòro míì tó tún lágbára ni ikú ẹnì kan téèyàn fẹ́ràn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin kan tó ń jẹ́ Janice ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà nìyẹn, ó sọ pé: “Àárín ọdún méjì péré ni àwọn ọmọkùnrin mi méjèèjì kú, èyí sì mú kí n ní ẹ̀dùn ọkàn tó lékenkà. Mo gbìyànjú láti ṣara gírí débi tí agbára mi lè gbé e dé. Mo wá sọ fún Ọlọ́run pé: ‘Ìyà yìí ti pọ̀ jù, agbára mi ò gbé e mọ́! Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n kúkú sùn kí n má sì jí mọ́.’”

Àpẹẹrẹ míì tún ni ti Daniel tó ní ìdààmú ọkàn tó lágbára gan-an nígbà tí ìyàwó rẹ̀ lọ ṣèṣekúṣe pẹ̀lú ọkùnrin míì. Ó sọ pé: “Nígbà tí ìyàwó mi jẹ́wọ́ pé òun ti ṣèṣekúṣe, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n fi ọ̀bẹ gún ọkàn mi. Ńṣe ni gbogbo ara ń ro mí goorogo lójoojúmọ́ fún ọ̀pọ̀ oṣù.”

Àwọn nǹkan tá a máa jíròrò nínú Ilé Ìṣọ́ yìí máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ pé ìgbésí ayé rẹ ṣì máa dùn kódà

  • Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀

  • Tí ẹnì kan tó o fẹ́ràn bá kú

  • Tí ẹnì kejì rẹ bá ṣe ìṣekúṣe

  • Tí àìsàn burúkú bá ń ṣe ẹ́

  • Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o pa ara rẹ

Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè ṣe tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí àtàwọn tó tẹ̀ lé e.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́