ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp19 No. 2 ojú ìwé 14-15
  • Ayé Rẹ Ṣì Máa Dùn!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayé Rẹ Ṣì Máa Dùn!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Bìkítà fún Ẹ
  • Asán Kọ́ Ni Ayé Rẹ
  • Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dára
  • Jèhófà Mọ Iye ‘Irun Orí Rẹ’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ẹni Tó Mọyì Wa Gan-an
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ṣé Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mó Bá Ń Ronú Àtipa Ara Mi?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”
    Sún Mọ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
wp19 No. 2 ojú ìwé 14-15
Ọ̀dọ́bìnrin kan ń ka Bíbélì

Ayé Rẹ Ṣì Máa Dùn!

Faizal bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn lẹ́yìn ọdún kan tí ìyàwó rẹ̀ kú. Dókítà wá sọ fún un pé ó ní àrùn kan tó máa gba pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ ọkàn fún un. Faizal sọ pé: “Nígbà tí mo ka ìwé Jóòbù, mo gbà pé ó nídìí tí Jèhófà fi jẹ́ kí ìtàn yẹn wà nínú Bíbélì. Téèyàn bá ní ìṣòrò, tó sì kà nípa ẹnì kan nínú Bíbélì tí òun náà ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀, ó máa ń jẹ́ kí ara tu èèyàn, kó sì dáni lójú pé ayé èèyàn ṣì máa dùn.”

Tarsha ṣì kéré nígbà tí ìyá rẹ̀ kú. Ó sọ pé: “Ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí mo kọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa ló jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀, ó jẹ́ kí n ní ìrètí, ó sì ń fún mi láyọ̀ láìka ọ̀pọ̀ ìṣòro tí mo ní sí. Ọkàn mi balẹ̀ pé Jèhófà lágbára láti fún mi lókun tí màá fi kojú ìṣòro ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.”

ÀWỌN àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ̀rọ̀ nípa bí oríṣiríṣi ìṣòro ṣe lè mú kí ayé súni. Bó o ṣe ń bá àwọn ìṣòro rẹ yí, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé asán ni ìgbésí ayé rẹ tàbí kó máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sí ẹnì kankan tó bìkítà nípa rẹ. Àmọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run ń rí gbogbo wàhálà rẹ, ó bìkítà nípa rẹ, ẹni ọ̀wọ́n lo sì jẹ́ lójú rẹ̀.

Irú ìdánilójú tí ẹni tó kọ Sáàmù 86 náà ní nìyẹn, ìdí nìyẹn tó fi sọ nípa Ọlọ́run pé: “Mo ké pè ọ́ ní ọjọ́ wàhálà mi, torí mo mọ̀ pé wàá dá mi lóhùn.” (Sáàmù 86:7) Àmọ́, o lè máa béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa dá mi lóhùn “ní ọjọ́ wàhálà mi”?’

Ó lè má jẹ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Ọlọ́run máa mú ìṣòro rẹ kúrò, àmọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi dá ẹ́ lójú pé ó máa fún ẹ ní àlàáfíà ọkàn, táá jẹ́ kó o lè fara dà á. Ó ní: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín.” (Fílípì 4:6, 7) Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó tẹ̀ lé e yìí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Ọlọ́run bìkítà fún wa.

Ọlọ́run Bìkítà fún Ẹ

“Ọlọ́run ò gbàgbé ìkankan nínú [àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́] . . . ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”​—Lúùkù 12:6, 7, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé

RÒ Ó WÒ NÁ: Àwọn ẹyẹ kéékèké lè má jẹ́ bàbàrà lójú àwọn èèyàn, àmọ́ wọ́n ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Kódà, ó ń kíyè sí ológoṣẹ́ tó kéré jọjọ; ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ṣeyebíye lójú rẹ̀. Àmọ́, àwa èèyàn ṣeyebíye lójú Ọlọ́run ju àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ lọ. Nínú gbogbo ìṣẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé, àwa èèyàn la ṣàrà ọ̀tọ̀ jù lọ torí pé Ọlọ́run dá wa ní “àwòrán rẹ̀.” Àwa la sì lè gbé àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó ga lọ́lá yọ.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27.

“Jèhófà, o ti yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, o sì mọ̀ mí. . . . O mọ ohun tí mò ń rò . . . Ṣàyẹ̀wò mi, kí o sì mọ àwọn ohun tó ń gbé mi lọ́kàn sókè.”​—Sáàmù 139:1, 2, 23.

RÒ Ó WÒ NÁ: Ọlọ́run mọ̀ ẹ́ dáadáa. Ó mọ àwọn àṣírí ọkàn rẹ, àti àwọn èrò inú rẹ tí o kò sọ fún ẹnikẹ́ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdààmú ọkàn rẹ lè má yé àwọn míì, ó yé Ọlọ́run, ó bìkítà nípa rẹ, ó sì ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Èyí máa jẹ́ kí ọkàn rẹ balẹ̀ pé ayé rẹ ṣì máa dùn.

Asán Kọ́ Ni Ayé Rẹ

“Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi; jẹ́ kí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ dé ọ̀dọ̀ rẹ. . . . Tẹ́tí sí mi; tètè dá mi lóhùn. . . . Á fetí sí àdúrà àwọn òtòṣì.”​—Sáàmù 102:1, 2, 17.

RÒ Ó WÒ NÁ: Ńṣe ló dà bíi pé látìgbà tí ọmọ aráyé ti bẹ̀rẹ̀ sí í jìyà ni Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí omijé ẹnì kọ̀ọ̀kan jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (Sáàmù 56:8) Gbà pé ó ń kíyè sí tìẹ náà. Ọlọ́run ò ní gbàgbé gbogbo ìyà tó o ti jẹ àti ẹkún tó o ti sun torí pé ẹni ọ̀wọ́n lo jẹ́ lójú rẹ̀.

“Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́. . . Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ . . . ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’”​—Àìsáyà 41:10, 13.

RÒ Ó WÒ NÁ: Ọlọ́run ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tí ìṣòro bá bò ẹ́ mọ́lẹ̀, ó máa gbé ẹ dìde.

Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dára

“Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”​—Jòhánù 3:16.

RÒ Ó WÒ NÁ: Nítorí pé o ṣeyebíye gan-an lójú Ọlọ́run, ó yọ̀ǹda Jésù Ọmọ rẹ̀ láti fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ẹ. Ohun tí Ọlọ́run ṣe yìí ló máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ láti gbé ní àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ títí láé.a

Ní báyìí, ẹ̀dùn ọkàn rẹ ṣì lè pọ̀, ó sì lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sọ́nà àbáyọ, àmọ́ tó o bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó o sì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú àwọn ìlérí rẹ̀, wàá láyọ̀, wàá sì rí i lóòótọ́ pé ayé rẹ ṣì máa dùn!

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àǹfààní tó o máa rí nínú bí Jésù ṣe kú nítorí tiwa, wo fídíò náà Ìrántí Ikú Jésù tó wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo. Wo abẹ́ NÍPA WA > ÌRÁNTÍ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́