Àwọn Ohun Tó Wà Lórí Ìkànnì Jw.Org
Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ yìí, àá máa darí àwọn èèyàn sí àwọn àpilẹ̀kọ tuntun tó máa ń jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn wa tẹ́lẹ̀ àmọ́ tó jẹ́ pé orí ìkànnì jw.org ló wà báyìí.
ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ
Ìbínú lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ, ohun kan náà ló lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ tó o bá ń di ìbínú sínú. Báwo lo ṣe lè kápá ìbínú rẹ tẹ́nì kan bá múnú bí ẹ gan-an?
(Lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌGBÉYÀWÓ ÀTI ÌDÍLÉ.)
BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
Bí Antonio ṣe jingíri nínú ìwà ipá, lílo oògùn olóró àti mímu ọtí lámujù mú kó gbà pé ìgbésí ayé òun kò nítumọ̀ rárá. Kí ló yí i lọ́kàn pa dà?
(Lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀLÀÁFÍÀ ÀTI AYỌ̀.)