ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w19 January ojú ìwé 31
  • Ẹnì Kan Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹnì Kan Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹnì Kan Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àwọn Arákùnrin Méjì Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
w19 January ojú ìwé 31
Kenneth àti Jamie Cook

Kenneth E. Cook, Jr., àti ìyàwó rẹ̀, Jamie

Ẹnì Kan Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí

LÁÀÁRỌ̀ ọjọ́ Wednesday, January 24, 2018, inú ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ti Kánádà dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ ìfilọ̀ pàtàkì kan pé Arákùnrin Kenneth Cook, Jr. ti kún Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ìlú Pennsylvania lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n bí Arákùnrin Cook sí, ibẹ̀ náà ló sì dàgbà sí. Nígbà tó ku díẹ̀ kó parí ilé ẹ̀kọ́ girama, ọmọ kíláàsì rẹ̀ kan kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì ṣèrìbọmi ní June 7, 1980. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní September 1, 1982. Lẹ́yìn ọdún méjì, wọ́n pè é sí Bẹ́tẹ́lì, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Wallkill, New York ní October 12, 1984.

Láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) tó tẹ̀ lé e, onírúurú iṣẹ́ ni Arákùnrin Cook ṣe ní ẹ̀ka tá a ti ń tẹ̀wé àti ẹ̀ka tó ń bójú tó ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Lọ́dún 1996, ó fẹ́ Arábìnrin Jamie, àwọn méjèèjì sì jọ ń ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Wallkill. Nígbà tó di December 2009, wọ́n gbé Arákùnrin àti Arábìnrin Cook lọ sí ọ́fíìsì tó wà ní Patterson, New York, níbi táwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run wà. Níbẹ̀, Arákùnrin Cook ń bá ẹ̀ka tó ń bójú tó Lẹ́tà Táwọn Èèyàn Kọ sí Ọ́fíìsì Wa ṣiṣẹ́. Ìgbà tó yá, wọ́n dá wọn pa dà sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Wallkill, àmọ́ àsìkò díẹ̀ ni wọ́n lò níbẹ̀ torí pé nígbà tó di April 2016, wọ́n gbé wọn lọ sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn, nílùú New York. Oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, wọ́n kó lọ sí oríléeṣẹ́ wa ní Warwick. Ní January 2017, ètò Ọlọ́run yan Arákùnrin Cook gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí.

Àwọn arákùnrin mẹ́jọ tó jẹ́ ẹni àmì òróró tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí báyìí ni:

K. E. Cook, Jr.; S. F. Herd; G. W. Jackson; M. S. Lett; G. Lösch; A. Morris III; D. M. Sanderson; D. H. Splane

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́