Àwọn Ohun Tó Wà Lórí Ìkànnì JW.ORG
TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?
Bí Eṣinṣin Ìgbẹ́ Ṣe Máa Ń Dábírà Tó Bá Ń Fò
Kòkòrò yìí lè fò bí ọkọ̀ òfúrufú táwọn ológun máa ń lò, àmọ́ òun tún lè dédé ṣẹ́rí pa dà lórí eré, láàárín ohun tí kò tó ìṣẹ́jú àáyá kan. Ibo ni kòkòrò yìí ti rí agbára tó fi lè fò bẹ́ẹ̀?
(Lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ ÀTI BÍBÉLÌ.)
BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
Ó Ṣe Mí Bíi Pé Gbogbo Ohun Tí Mo Fẹ́ Lọwọ́ Mi Ti Tẹ̀
Ọ̀dọ́ ni Stéphane, ọwọ́ ẹ̀ ti mókè, gbajúmọ̀ sì ni, síbẹ̀ náà, kò láyọ̀, ọkàn ẹ̀ ò sì balẹ̀. Báwo ló ṣe wá di ẹni tó ní ayọ̀ tòótọ́, tí ìgbésí ayé ẹ̀ sì nítumọ̀?
(Lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀLÀÁFÍÀ ÀTI AYỌ̀.)