Àwọn Ohun Tó Wà Lórí Ìkànnì Jw.Org
TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?
Bí Ẹja Dolphin Ṣe Ń Mọ Ohun Tó Ń Lọ Lábẹ́ Omi
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó jọ nǹkan àgbàyanu tí ẹja Dolphin bottlenose ń ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn náà á lè ṣe àwọn ẹ̀rọ tó lè ṣiṣẹ́ lábẹ́ omi.
Lórí ìkànnì jw.org, lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ ÀTI BÍBÉLÌ > TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?
ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ
Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Máàkì Rẹ̀ Lè Gbé Pẹ́ẹ́lí
Tó o bá ń fúngun mọ́ ọmọ rẹ, ọkàn ẹ̀ ò ní balẹ̀ níléèwé, kò sì tún ní balẹ̀ nílé. Mọ ibi tí ìṣòro wà gan-an, kó o sì jẹ́ kó wù ú láti máa kẹ́kọ̀ọ́.
Lórí ìkànnì jw.org, lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌGBÉYÀWÓ ÀTI ÌDÍLÉ > ỌMỌ TÍTỌ́.