Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Iṣẹ́ wo làwọn ìríjú máa ń ṣe láyé àtijọ́?
LÁYÉ ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ìríjú ni ẹni tó ń bójú tó agboolé àti ohun ìní ẹlòmíì. Ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “ìríjú” sábà máa ń tọ́ka sí alábòójútó tàbí ọ̀gá àwọn tó ń bójú tó ilé.
Nígbà tí Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù jẹ́ ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì, Pọ́tífárì ọ̀gá rẹ̀ fi í ṣe ìríjú, ó sì ní kó máa bójú tó agbo ilé òun. Kódà, “ó fi gbogbo ohun tó ní sí ìkáwọ́ Jósẹ́fù.” (Jẹ́n. 39:2-6) Nígbà tí Jósẹ́fù náà di alákòóso tó lágbára nílẹ̀ Íjíbítì, ó yan ìríjú kan láti máa bójú tó agbo ilé rẹ̀.—Jẹ́n. 44:4.
Lásìkò tí Jésù wà láyé, àwọn tó ní ilẹ̀ rẹpẹtẹ tí wọ́n fi ń dáko kì í sábà gbé lágbègbè tí wọ́n ń dáko sí. Ṣe ni wọ́n máa ń yan àwọn ìríjú táá máa bójú tó àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú oko náà, kí wọ́n sì rí i dájú pé wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́.
Irú ẹni wo ni wọ́n máa ń yàn sípò ìríjú? Òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Róòmù kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tó ń jẹ́ Columella sọ pé ẹrú tí wọ́n bá fẹ́ yàn sípò ìríjú tàbí alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ “ẹni tí wọ́n ti rí i pé ó mọ̀ nípa iṣẹ́ náà dáadáa.” Ó tún ní láti jẹ́ “ẹni tó mọ bí a ṣe ń darí àwọn èèyàn, àmọ́ tí kì í fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú nǹkan tí kò sì le koko.” Ó sọ pé: “Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́ tí kì í sì í ronú pé gbogbo nǹkan lòun ti mọ̀ tán.”
Bíbélì lo àpẹẹrẹ ìríjú àtàwọn iṣẹ́ tó máa ń ṣe láti ṣàlàyé àwọn ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni níyànjú nípa bí wọ́n ṣe lè lo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wọn. Ó ní: “Ẹ máa fi ṣe ìránṣẹ́ fún ara yín bí ìríjú àtàtà tó ń rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.”—1 Pét. 4:10.
Jésù náà sọ̀rọ̀ nípa ìríjú kan nínú àkàwé tó ṣe nínú Lúùkù 16:1-8. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀, ó fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé òun máa yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tàbí “ìríjú olóòótọ́” táá máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí déédéé fáwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lásìkò òpin yìí. (Mát. 24:45-47; Lúùkù 12:42) Inú wa dùn pé a wà lára àwọn tó ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó ń fúnni lókun tí ìríjú olóòótọ́ náà ń pèsè.