Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní September: Gbogbo èdè—Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye (ńlá, ₦120; kékeré, ₦120). A ní láti sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé. October: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀-owó fún Ilé-Ìṣọ́nà tàbí Jí! Ṣe àkànṣe ìsapá láti fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn sóde. A tún lè fi àsansílẹ̀-owó lọni nígbà ìpadàbẹ̀wò. November: Gẹ̀ẹ́sì—New World Translation of the Holy Scriptures àti ìwé náà The Bible—God’s Word or Man’s? Yorùbá—Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun. Àwọn èdè yòókù—Iwe Itan Bibeli Mi tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétáásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn, gbọ́dọ̀ ṣàkọsílẹ̀ àkáǹtì ìjọ ní September 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe èyí.
◼ A ń rán àwọn alàgbà létí láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni tí a pèsè nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, 1991, ní ojú ìwé 21 sí 23, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tí a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí ó yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tí wọ́n lè nítẹ̀sí sí dídi ẹni tí a gbà padà.
◼ Àwọn akéde tí ń wéwèé láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà ní October, gbọ́dọ̀ tètè fi ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà wọn sílẹ̀. Èyí yóò yọ̀ǹda fún àwọn alàgbà láti ṣe àwọn ètò tí ó bá pọndandan fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìpínlẹ̀.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tí Ó Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó Nísinsìnyí:
Gẹ̀ẹ́sì: Iwe Itan Bibeli Mi; Kọrin Ìyìn sí Jehofah (ńlá); Kọrin Ìyìn sí Jehofah (tí a fi lẹ́tà ńlá gàdàgbà kọ); ìdìpọ̀ Ilé-Ìṣọ́nà ti 1985. Hausa: Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi? Igala: Ìtùnú fun Awọn ti o Soríkọ́ (Ìwé àṣàrò kúkúrú nọmba 20); Kinni Awọn Ẹlẹrii Jehofah Gbagbọ? (Ìwé àṣàrò kúkúrú nọmba 14); “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” Tiv: Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Yorùbá: Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.
◼ Kásẹ́ẹ̀tì Àtẹ́tísí Tuntun Tí Ó Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó:
Gẹ̀ẹ́sì: Kingdom Melodies Album (sẹ́ẹ̀tì oníkásẹ́ẹ̀tì mẹ́jọ).
◼ A óò ti ilé Beteli pa ní October 21. Nítorí náà, ẹ jọ̀wọ́ ẹ má ṣe wá láti ṣèbẹ̀wò tàbí láti ra ìwé ní ọjọ́ yìí.
◼ Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Olóṣooṣù: Ní òpin oṣù kọ̀ọ̀kan, ẹ ní láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá olóṣooṣù ti ìjọ ránṣẹ́ ní kánmọ́ sí ọ́fíìsì ní lílo káàdì S-1. Ó ṣe pàtàkì gidi láti kọ orúkọ ìjọ àti iye akéde tí ó ròyìn ní oṣù yẹn sórí káàdì náà. Káàdì náà kò ní wúlò fún wa bí ìsọfúnni yìí kò bá sí níbẹ̀. Àwọn nọ́ḿbà yòókù lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ni ẹ ní láti kọ ketekete: àròpọ̀ ìwé ńlá, ìwé pélébé àti ìwé pẹlẹbẹ, wákàtí, àsansílẹ̀-owó, ẹyọ ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan, ìpadàbẹ̀wò, àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé. Bákan náà, nọ́ḿbà ìjọ ni ẹ ní láti kọ ketekete sórí káàdì náà. Èyí yóò mú kí ó túbọ̀ rọrùn láti dá káàdì náà padà sí ìjọ tí ó ni ín, bí àìní náà bá dìde. Yóò dára kí alábòójútó olùṣalága àti àwọn alàgbà yòókù yẹ káàdì ìròyìn náà wò láti rí i dájú pé gbogbo ìsọfúnni tí a nílò wà lórí káàdì náà, kí wọ́n tó fi ránṣẹ́ sí Society.