Àpótí Ìbéèrè
◼ Irú àfiyèsí wo ni ó yẹ kí a fi fún àwọn irin iṣẹ́ tí a ń lò nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí?
1 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní ìgbékalẹ̀ tí ó ṣe wẹ́kú, tí a gbé ka orí Ìwé Mímọ́, lọ́kàn, akéde ìhìnrere kan lè ṣàìwà ní ìmúrasílẹ̀ nígbà tí ó bá kan ti àwọn irin iṣẹ́ tí ó ń lò. Nígbà tí ó bá wà lẹ́nu ọ̀nà, ó lè máà ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fi ń lọni ní lọ́ọ́lọ́ọ́, tàbí àwọn ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, àti ìwé àṣàrò kúkúrú tí ó wà nínú àpò ẹ̀rí rẹ̀ lè ti rún tàbí fàya. Ó lè má ṣeé ṣe fún un láti rí lẹ́ẹ̀dì ìkọ̀wé tàbí àkọsílẹ̀ ilé dé ilé, nítorí pé àpò ìwàásù rẹ̀ kò sí létòlétò.
2 Ó ṣe pàtàkì pé kí o fún àwọn irin iṣẹ́ rẹ ní àfiyèsí dáradára kí o tó lọ ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá.
3 Àwọn ohun wo ni ó yẹ kí ó wà nínú àpò ẹ̀rí kan tí ó wà létòlétò? Bibeli ṣe kókó. Fi àkọsílẹ̀ ilé dé ilé tí ó pọ̀ tó sínú rẹ̀. Rí i dájú pé o ní ìtẹ̀jáde tí a ń gbé jáde lákànṣe ní oṣù náà lọ́wọ́. O tún nílò àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ ní àfikún sí àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú àti àwọn ìwé pẹlẹbẹ. Mú ẹ̀dà ìwé Reasoning lọ́wọ́. Níní Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tí ó dé kẹ́yìn lọ́wọ́ yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti ṣàtúnyẹ̀wọ̀ àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dámọ̀ràn kí o tó lọ sínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Nígbà tí o bá ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ tí ó ti ṣeé ṣe kí o bá àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè mìíràn pàdé, yóò dára kí o ní ìwé pélébé náà, Good News for All Nations, lọ́wọ́. Níní ẹ̀dà kan lára àwọn ìtẹ̀jáde wa tí a ṣe nítorí àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbara dì láti bá àwọn ọ̀dọ́langba sọ̀rọ̀.
4 Gbogbo ohun tí o ń lò ní láti wà ní ipò tí ó dára, kí o sì ṣètò wọn dáradára sínú àpò rẹ. Kì í ṣe dandan pé kí àpò náà jẹ́ titun, ṣùgbọ́n ó ní láti wà ní mímọ́ tónítóní, kí ó sì dára.
5 Àpò ẹ̀rí rẹ jẹ́ ara irin iṣẹ́ tí o ń lò nínú pípolongo ìhìnrere. Jẹ́ kí ó wà létòlétò.