Báwo Ló Ṣe Rí?
Ìbéèrè tó dára jù lọ tó yẹ ká máa ronú lé lórí nípa àwọn ìwé tá a ní lọ́kàn láti lò lóde ẹ̀rí nìyẹn. Ìwé tí etí rẹ̀ ká kò, tó ti pọ́n ràkọ̀ràkọ̀, tó rí málamàla tàbí tó ti gbó, kò ní jẹ́ káwọn èèyàn fojú tó dára wo ètò wa, ó sì lè máà jẹ́ káwọn èèyàn pọkàn pọ̀ sorí ìhìn rere, tó sì ń gba ẹ̀mí là tó wà nínú àwọn ìwé náà.
Báwo la ṣe lè mú kí àwọn ìwé wa wà ní mímọ́? Àwọn kan ti rí i pé ó máa ń ṣàǹfààní tí àwọn bá to báàgì wọn lọ́nà tí àwọn ìwé tó jọra á fi wà lójú kan. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń kó àwọn ìwé ńlá sójú kan, wọ́n máa ń kó àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé pẹlẹbẹ sójú kan, wọ́n sì máa ń kó àwọn ìwé ìléwọ́ sójú kan, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n máa ń fara balẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ dá Bíbélì àtàwọn ìwé tí wọ́n lò pa dà sínú báàgì wọn, kí wọ́n má bàa bà jẹ́. Àwọn akéde kan máa ń tọ́jú ìwé wọn sínú àpamọ́wọ́ pẹlẹbẹ tàbí báàgì onírọ́bà tí wọ́n lè rí ohun tó wà nínú rẹ̀. Ọgbọ́n yòówù ká ta sí i, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká má ṣe fún ẹnì kankan láyè láti ṣe àríwísí iṣẹ́ ìwàásù wa nípa fífún un ní ìwé tí kò bójú mu.—2 Kọ́r. 6:3.