Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 31, 2011.
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká rọ̀ mọ́ àwọn ìránnilétí Jèhófà? (Sm. 119:60, 61) [w00 12/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 3]
Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú Sáàmù 133:1-3? [w06 9/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3]
Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ‘yẹ Dáfídì wò látòkè délẹ̀’ tó sì ‘díwọ̀n ìrìn àjò’ rẹ̀ àti ‘ìnàtàntàn rẹ̀ lórí ìdùbúlẹ̀’? (Sm. 139:1, 3) [w06 9/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 6; w93 10/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 6]
Ìṣòro wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lè wà nínú rẹ̀ tí Jèhófà á pèsè “ìtìlẹ́yìn” tàbí kí ó ‘gbé wọn ró’? (Sm. 145:14) [w04 1/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 11]
Kí ló mú kí ọkùnrin tí Òwe 6:12-14 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jẹ́ ẹni tí kò dára fún ohunkóhun? [w00 9/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 5 sí 6]
Kí nìdí tí ọlọ́gbọ́n èèyàn fi máa ń “tẹ́wọ́ gba àṣẹ”? (Òwe 10:8) [w01 7/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1]
Báwo ni ọlọ́gbọ́n àti òmùgọ̀ ṣe yàtọ̀ síra tó bá dọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe máa ń hùwà nígbà tí wọ́n bá fi ìwọ̀sí lọ̀ wọ́n tàbí tí wọ́n bá ṣe àríwísí wọn? (Òwe 12:16) [w03 3/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3 sí 4]
Báwo ni níní èrò tó dáa ṣe máa ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti jẹ “àsè nígbà gbogbo”? (Òwe 15:15) [w06 7/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 6]
Báwo la ṣe lè dẹni tó “jèrè ọkàn-àyà,” ọ̀nà wo sì lẹni tó ṣe bẹ́ẹ̀ gbà “nífẹ̀ẹ́ ọkàn ara rẹ̀”? (Òwe 19:8) [w99 7/1 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 4]
Báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe lè ṣàǹfààní fún ìdílé kan? (Òwe 24:3) [w06 9/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 11; be ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 1]