Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 7
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 7
Orin 131 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 12 ìpínrọ̀ 9 sí 13, àti àpótí tó wà lójú ìwé 97 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Òwe 27-31 (10 min.)
No. 1: Òwe 28:19–29:10 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Ríronú Lórí Ohun Tó Wà Nínú Róòmù 8:32 Ṣe Lè Fi Wá Lọ́kàn Ba Lẹ̀ Pé Gbogbo Ìlérí Ọlọ́run Ló Máa Ṣẹ? (5 min.)
No. 3: Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Kọ́ Ni Ìgbàgbọ́ Wò-ó-sàn Òde Òní Ti Wá—td 32D (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Bá A Ṣe Lè Dáhùn Ìbéèrè Nípa Ìfàjẹ̀sínilára. Ìjíròrò tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004, ojú ìwé 29 sí 31. Sọ àwọn kókó tó máa jẹ́ kí àwọn ará lè dáhùn àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò yìí: (1) Bí Ìṣe 15:28, 29 ṣe sọ, kí ló túmọ̀ sí láti ta kété sí ẹ̀jẹ̀? (2) Kí ni títa kété sí ẹ̀jẹ̀ túmọ̀ sí tá a bá fojú ibi tí ìmọ̀ ìṣègùn ti gbòòrò dé báyìí wò ó? (3) Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn Kristẹni gba ìtọ́jú tí wọ́n ti máa lo àwọn èròjà kéékèèké inú ẹ̀jẹ̀?
10 min: Àwọn Ọ̀ràn Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ.
10 min: Jèhófà Kò Ní Fi Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Sílẹ̀. (Sm. 94:14) Ìjíròrò tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ July 1, 1997, ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 12 sí 19. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
Orin 110 àti Àdúrà