Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? Láfikún sí èyí tàbí gẹ́gẹ́ bí àfidípò, ẹ tún lè lo ìwé olójú ewé 32 èyíkéyìí tá a tò sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù August 2011. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí àwọn ọmọdé bá wà nínú ilé náà, kẹ́ ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà tàbí Ìwé Ìtàn Bíbélì. January: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá fún àwọn èèyàn ní ìwé náà. Bí onílé bá ti ní ìwé náà, tí kò sì fẹ́ kí á wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ lè fún un ní àwọn ìwé ìròyìn tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tàbí ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí. Ẹ lè lo àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tí ìjọ ní lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àfidípò.