Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní October: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀-owó fún Jí! tàbí Ilé-Ìṣọ́nà tàbí fún àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àkànṣe ìsapá láti fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn sóde. A tún lè fi àsansílẹ̀-owó lọni nígbà ìpadàbẹ̀wò. Àwọn ìwé ìròyìn ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún ọdún kan jẹ́: ₦300. Ti olóṣooṣù fún ọdún kan tàbí ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún oṣù mẹ́fà jẹ́: ₦150. November: Gẹ̀ẹ́sì—New World Translation of the Holy Scriptures àti ìwé náà The Bible—God’s Word or Man’s? Yorùbá—Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun. Àwọn èdè yòókù—Iwe Itan Bibeli Mi tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. December: Gbogbo èdè—Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó, lo Iwe Itan Bibeli Mi tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. January: Gbogbo èdè—Ìwé olójú ìwé 192 èyíkéyìí tí a tẹ̀ sórí àwọn pépà tí ó ti ń di pípọ́n ràkọ̀ràkọ̀ tàbí tí ń pàwọ̀ dà tàbí èyíkéyìí tí a tẹ̀ jáde ṣáájú 1982 ni a lè fi lọni ní ẹ̀dínwó. A kò gbọdọ̀ fi àwọn ìtẹ̀jáde tí a tẹ̀ sórí àwọn pépà tí kì í ṣá tàbí pàwọ̀ dà kún àwọn ìfilọni ẹlẹ́dìínwó wọ̀nyí. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétáásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Ẹ̀yin alàgbà, ẹ jọ̀wọ́ kíyè sí i pé 40 kobo ni ẹ̀dà kan Ìròyìn Ìjọba tí a fi ránṣẹ́ sí i yín, kì í ṣe 80 kobo, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ sínú lẹ́tà wa.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti November 6, 1995, a óò bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ìwé “Jẹ́ Kí Ijọba Rẹ Dé” ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.
◼ Ìtẹ̀jáde Jí! November 8 yóò ní àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ lórí ìsìn Mormon nínú. Ìgbéjáde yìí kì í ṣe àtakò sí ìgbàgbọ́ Mormon bí kò ṣe ìtúpayá kedere lórí díẹ̀ lára àwọn ìgbàgbọ́ Mormon, ní ìfiwéra pẹ̀lú Bibeli. A ti ṣe ìwádìí kúlẹ̀kúlẹ̀ lórí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí, a sì ti fi wọ́n wé àwọn ìwé Mormon. A gbàgbọ́ pé àyẹ̀wò nípa ìtàn àti ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Mormon yìí yóò ran àwọn olótìítọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti rí ibi tí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ wà gan-an. Ìwọ lè fẹ́ láti gba ẹ̀dà púpọ̀ sí i láti lò ní ọjọ́ iwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àwọn ìjọ gbọ́dọ̀ fi tó Society létí ní kánmọ́ bí wọ́n bá fẹ́ àfikún ẹ̀dà ìtẹ̀jáde yìí.
◼ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ óò rí àfikún àtúnṣe tí a ṣe nínú “Àwọn Ọ̀gangan Ibi Àpéjọpọ̀ Àgbègbè 1995” nísàlẹ̀. Àwọn ìjọ tí a yí ọjọ́ àpéjọpọ̀ wọn padà ní láti ṣe ìfilọ̀ nípa ọjọ́ àpéjọpọ̀ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn fún wọn, ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí ó tẹ̀ lé e. Bákan náà, wọ́n ní láti lẹ ìsọfúnni yìí mọ́ pátákó ìsọfúnni, ní fífa ìlà sábẹ́ apá tí ó kàn wọ́n.
November 3-5, 1995
IKOT AKAN 1 (Efik) EF-7 àwọn ìjọ ní ìtòtẹ̀léra lọ́nà a, b, d láti A sí E; EF-8: Nwowo (Atan Ikpe), Edem Urua, Esa Ekpo, Essene, Ette Town, Minya, Mkpat Enin, Atan Obom (Okon Ikot Abasi), Ukan Akama, àti Ukpana
November 10-12, 1995
IKOT AKAN 2 (Efik) EF-7 àwọn ìjọ ní ìtòtẹ̀léra lọ́nà a, b, d láti F sí Z; EF-8: Gbogbo ìjọ YÀTỌ̀ SÍ Nwowo (Atan Ikpe), Edem Urua, Esa Ekpo, Essene, Ette Town, Minya, Mkpat Enin, Atan Obom (Okon Ikot Abasi), Ukan Akama, àti Ukpana
December 15-17, 1995
AKURE 1 (Yorùbá) Y-18: Gbogbo ìjọ YÀTỌ̀ SÍ Aiyeteju Amuro, Egbe, Isanlu, àti Mopa; Y-19.
January 12-14, 1996
AKURE 4 (Yorùbá) Y-22, 23