Jíjẹ́ Ẹni Tí Jehofa Ń Yẹ̀ Wò—Èé Ṣe Tí Ó Fi Ṣàǹfààní?
1 Gbogbo ènìyàn ń fẹ́ ìlera pípé. Ó ń mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ gbádùn mọ́ni. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ń gbádùn ìlera pípé ń lọ fún àyẹ̀wò lóòrèkóòrè. Èé ṣe? Wọ́n ń wá ọ̀nà láti ṣàwárí àwọn ìṣòro ìlera tí ó lè máa yọjú, kí wọ́n baà lè gbé ìgbésẹ̀ láti wá ojútùú sí wọn. Ó tilẹ̀ túbọ̀ ṣe pàtàkì láti dáàbò bo ìlera wa tẹ̀mí. Rírí ìtẹ́wọ́gbà Jehofa sinmi lórí bíbá a nìṣó láti jẹ́ “onílera ninu ìgbàgbọ́,”—Titu 1:13.
2 Ìsinsìnyí ni àkókò tí ó yẹ wẹ́kú fún Jehofa láti yẹ̀ wá wò. Èé ṣe tí ó fi rí bẹ́ẹ̀? Nítorí pé Jehofa wà nínú tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ̀, ó sì ń yẹ ọkàn-àyà gbogbo ènìyàn wò. (Orin Da. 11:4, 5; Owe 17:3) Bíi Dafidi, a ń bẹ Jehofa láti yẹ̀ wá wò kínníkínní: “Wádìí mi Oluwa, kí o sì rídìí mi; dán inú mi àti ọkàn mi wò.”—Orin Da. 26:2.
3 A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún àwọn ohun tí ó lè wu ìlera wa tẹ̀mí léwu, tí ó lè wá láti inú wa lọ́hùn-ún, nítorí ẹran ara wa aláìpé. Owe 4:23 gbani nímọ̀ràn pé: “Ju gbogbo ohun ìpamọ́, pa àyà rẹ mọ́; nítorí pé láti inú rẹ̀ wá ni orísun ìyè.”
4 Ayé oníwà ìbàjẹ́, ẹlẹ́gbin tí ó yí wa ká pẹ̀lú lè wu ìlera wa tẹ̀mí léwu. Bí a bá sún mọ́ ètò ìgbékalẹ̀ búburú yìí ju bí ó ti yẹ lọ, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bí ó ti ń ronú, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìṣarasíhùwà ayé dàgbà. Tàbí a lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé bíi ti àwọn ènìyàn ayé, kí ẹ̀mí ayé sì ṣẹ́pá wa.—Efe. 2:2, 3.
5 Satani lè lo inúnibíni tàbí àtakò tààràtà nínú ìsapá láti pa wá run ráúráú nípa tẹ̀mí. Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń lo àwọn ìfanimọ́ra nínú ayé lọ́nà ọgbọ́n wẹ́wẹ́ láti fi dẹ wá. Peteru rọ̀ wá láti ‘pa awọn agbára ìmòye wa mọ́ kí a sì máa kíyèsára,’ níwọ̀n bí Satani ti dà bíi “kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà lati pa ẹni kan jẹ.” A rọ̀ wá láti ‘mú ìdúró wa lòdì sí i, ní dídúró gbọn-in ninu ìgbàgbọ́.’—1 Pet. 5:8, 9.
6 Àìní wà láti dáàbò bo ìlera wa tẹ̀mí ní mímú kí ìgbàgbọ́ wa máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ alágbára, nípa fífún un lókun lójoojúmọ́. Aposteli Paulu dámọ̀ràn pé, kí a máa dán ìgbàgbọ́ wa wò léraléra. Gan-an bí a ti máa ń fi ọgbọ́n kọbi ara sí ìmọ̀ràn tí ó wúlò tí dókítà tí ó mọṣẹ́ fún wa, bákan náà, a máa ń fetí sí Jehofa nígbà tí àyẹ̀wò Rẹ̀ nípa tẹ̀mí bá fi hàn pé a ní ìṣòro kan tí a ní láti ṣàtúnṣe. Èyí ń mú kí ó ṣeé ṣe fún wa “lati máa gba ìtọ́sọ́nàpadà.”—2 Kor. 13:5, 11.
7 Jehofa ní tòótọ́ jẹ́ Olùyẹ̀wò gíga lọ́lá. Àwọn àyẹ̀wò rẹ̀ máa ń pé pérépéré nígbà gbogbo. Ó mọ ohun tí a nílò gan-an. Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ‘olùṣòtítọ́ ẹrú,’ ó ń júwe àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tí ó ń fúnni ní ìlera fún wa. (Matt. 24:45; 1 Tim. 4:6) Jíjẹ oúnjẹ aṣaralóore nípa tẹ̀mí yìí déédéé, nínú ilé àti ní àwọn ìpàdé ìjọ, ń mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti pa ìlera tẹ̀mí mọ́. Eré ìdárayá déédéé nípa tẹ̀mí, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìgbòkègbodò Kristian mìíràn, tún ṣàǹfààní pẹ̀lú. Nítorí náà, a fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà tẹ́wọ́ gba àyẹ̀wò Jehofa déédéé, pẹ̀lú ìdánilójú pé òun yóò mú kí a ní ìlera tẹ̀mí tí ó dára jù lọ.