Ìwọ Ha Ń Jẹun Kánú Nípa Tẹ̀mí Bí?
“Oúnjẹ àtàtà jẹ́ olórí ohun tí ẹ̀dá ènìyàn nílò. . . . Láìsí oúnjẹ tí ó tó, a óò kú.”—Food and Nutrition.
ÒTÍTỌ́ tí kò ṣeé já ní koro yẹn hàn kedere nínú ìrísí àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé tí ebi ń pa, tí wọ́n ti gbẹ, nítorí tí a fi “olórí ohun tí ẹ̀dá ènìyàn nílò” dù wọ́n. Ó ṣeé ṣe fún àwọn mìíràn láti kojú àìní yìí dé àyè kan, ṣùgbọ́n, síbẹ̀, wọn kì í jẹun kánú. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ tí ó ṣeé ṣe fún láti jẹun kánú ni ó jẹ́ pé, jíjẹ ìpápánu tí ń pèsè ojúlówó okun díẹ̀ ti tẹ́ wọn lọ́rùn. Ìwé náà, Healthy Eating, sọ pé: “Oúnjẹ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun ìní wa tí a kì í lò dáradára rárá.”
Ọ̀ràn kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ nípa oúnjẹ tẹ̀mí—òtítọ́ tí a ń rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì. Àní àwọn kan kò tilẹ̀ ní ohun aṣaralóore tẹ̀mí tí ó kéré jù lọ; ebi nípa tẹ̀mí ń pa wọ́n. Àwọn mìíràn wulẹ̀ dágunlá sí jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí ó wà níkàáwọ́ wọn. Ìwọ ńkọ́? O ha ń jẹun kánú nípa tẹ̀mí bí? Àbí ó ha lè jẹ́ pé o ń fi oúnjẹ tẹ̀mí du ara rẹ? Ó ṣe pàtàkì láti má ṣe ṣàbòsí ara wa nínú ọ̀ràn yí, nítorí pé, a nílò oúnjẹ tẹ̀mí ju bí a ṣe nílò oúnjẹ ti ara lọ pàápàá.—Mátíù 4:4.
Oúnjẹ fún Ìdàgbàsókè Tẹ̀mí
Food and Nutrition, ìwé kan tí ó jíròrò ìjẹ́pàtàkì jíjẹ oúnjẹ tí ó gbámúṣé, fún wa ní ìdí mẹ́ta pàtàkì fún jíjẹun kánú. Ọ̀kan ni pé, a nílò oúnjẹ “láti mú kí ìdàgbàsókè wa rọrùn àti láti sọ àwọn sẹ́ẹ̀lì ara wa tí ń jó rẹ̀yìn di ọ̀tun.” Ìwọ ha mọ̀ pé ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ìgbésí ayé rẹ, ẹgbẹẹgbẹ̀ sẹ́ẹ̀lì ara rẹ ń tú ká, wọ́n sì nílò arọ́pò? Ìdàgbàsókè tí ó yẹ àti ìtọ́jú ara ń béèrè fún oúnjẹ àtàtà.
Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn rí nípa tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ ní Éfésù, ó tẹnu mọ́ bí Kristẹni kọ̀ọ̀kan ṣe nílò oúnjẹ àtàtà nípa tẹ̀mí tó láti di “géńdé ọkùnrin.” (Éfésù 4:11-13) Nígbà tí a bá fi oúnjẹ tẹ̀mí tí ń ṣara lóore bọ́ ara wa yó, a kò ní dà bí àwọn ọmọ jòjòló tí ara wọn kò tí ì gbó, tí wọn kò lè dá tọ́jú ara wọn, tí wọ́n sì ń kó sínú onírúurú ewu. (Éfésù 4:14) Kàkà bẹ́ẹ̀, a ń dàgbà di àgbàlagbà tí ó lágbára, tí ó lè ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́, nítorí pé, a ń “fi àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ bọ́” wa.—Tímótì Kíní 4:6.
Ṣe bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn tìrẹ ṣe rí? O ha ti dàgbà nípa tẹ̀mí bí? Àbí o ṣì jẹ́ ọmọdé jòjòló nípa tẹ̀mí—tí ó lè tètè kó sínú ewu, tí kò lè dá ṣe ohunkóhun, tí kò sì lè tẹ́wọ́ gba àwọn ẹrù iṣẹ́ Kristẹni? Lọ́nà tí ó yéni, díẹ̀ lára wa ni yóò yára sọ pé àwọn jẹ́ ọmọdé jòjòló nípa tẹ̀mí, ṣùgbọ́n yíyẹ ara ẹni wò fínnífínní jẹ́ ohun yíyẹ. Àwọn Kristẹni kan, tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní. Bí ó tilẹ̀ yẹ kí àwọn fúnra wọn ti di “olùkọ́,” tí wọ́n lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, kí wọ́n sì múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin tún nílò ẹni kan láti máa kọ́ yín láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run; ẹ sì ti di irúfẹ́ àwọn ẹni tí ó nílò wàrà, kì í ṣe oúnjẹ líle.” Bí o bá fẹ́ dàgbà nípa tẹ̀mí, jẹ́ kí ebi oúnjẹ àtàtà, oúnjẹ líle nípa tẹ̀mí máa pa ọ́. Má ṣe jẹ́ kí oúnjẹ ọmọdé jòjòló nípa tẹ̀mí tẹ́ ọ lọ́rùn!—Hébérù 5:12.
A tún nílò oúnjẹ líle nípa tẹ̀mí yìí láti ṣàtúnṣe ìpalára tí àwọn àdánwò ojoojúmọ́ tí a ń dojú kọ nínú ayé oníkanra yìí ti lè mú wá. Ìwọ̀nyí lè fa okun wa nípa tẹ̀mí gbẹ. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run lè sọ okun yẹn dọ̀tun. Pọ́ọ̀lù wí pé: “Àwa kò juwọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ẹni tí a jẹ́ ní òde bá tilẹ̀ ń joro lọ, dájúdájú ẹni tí àwa jẹ́ ní inú ni a ń sọ dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́.” (Kọ́ríńtì Kejì 4:16) Báwo ni a ṣe ń ‘sọ wá dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́’? Lọ́nà kan, nípa jíjẹun déédéé nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nípa dídákẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì, àti nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú wọn gẹ́gẹ́ bí àwùjọ.
Oúnjẹ fún Agbára Nípa Tẹ̀mí
A tún nílò oúnjẹ “láti pèsè ooru àti agbára.” Oúnjẹ ń pèsè ohun aṣaralóore tí ara wa nílò láti lè ṣiṣẹ́ dáradára. Bí a kò bá jẹun kánú, agbára wa kò ní tó nǹkan. Bí a kò bá ní èròjà iron nínú ara wa, ó lè mú kí ó rẹ̀ wá, kí a sì máa ṣe sùọ̀sùọ̀. Ṣé bí ó ṣe máa ń ṣe ọ́ nìyẹn nígbà tí àkókò bá tó fún ìgbòkègbodò tẹ̀mí? Ó ha ń ṣòro fún ọ láti ṣe ojúṣe rẹ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú jíjẹ́ Kristẹni? Àwọn kan tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ti káàárẹ̀ nínú rere ṣíṣe, wọn kò sì ní okun fún àwọn iṣẹ́ Kristẹni mọ́. (Jákọ́bù 2:17, 26) Bí o bá rí i pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn tìrẹ ṣe rí, dé ìwọ̀n gbígbòòrò, ojútùú náà lè wà nínú mímú ọ̀nà ìjẹun rẹ nípa tẹ̀mí sunwọ̀n sí i tàbí kí o fi kún oúnjẹ tí o ń jẹ nípa tẹ̀mí.—Aísáyà 40:29-31; Gálátíà 6:9.
Má ṣe jẹ́ kí a tàn ọ́ jẹ débi mímú àṣà àìjẹun kánú nípa tẹ̀mí dàgbà. Ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀tàn tí Sátánì ti lò jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún ni, mímú kí àwọn ènìyàn gbà gbọ́ pé, wọn kò ní láti ka Bíbélì, kí wọ́n sì gba ìmọ̀ pípéye láti inú rẹ̀ sínú. Ó ń lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ àtayébáyé kan tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun agbésùnmọ̀mí máa ń lò láti ṣẹ́gun ìlú àwọn ọ̀tá—fífi oúnjẹ dù wọ́n, kí ó sì mú kí ebi sún wọn láti túúbá. Ṣùgbọ́n, ó ti tẹ̀ síwájú sí i nínú lílo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ yìí. Ó ń fẹ̀tàn mú kí àwọn tí ó “kógun tì” febi pa ara wọn nígbà tí ó sì jẹ́ pé òkìtì bàǹbà oúnjẹ tẹ̀mí tí ó gbámúṣé yí wọn ká. Abájọ tí ọ̀pọ̀ fi ń kó sínú páńpẹ́ rẹ̀!—Éfésù 6:10-18.
Oúnjẹ fún Ìlera Tẹ̀mí
Ìwé náà, Food and Nutrition, sọ pé ìdí kẹta tí a fi nílò oúnjẹ ni “láti darí ìlera ara wa . . . kí a sì dènà àrùn.” Àǹfààní ìlera tí ó wà nínú oúnjẹ àtàtà kì í tètè hàn. Nígbà tí a bá jẹ oúnjẹ àtàtà tán, a kì í sábà ronú pé, ‘Ìyẹn ti ṣe ọkàn àyà mi (tàbí kíndìnrín mi tàbí iṣan mi, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ) lóore.’ Síbẹ̀, gbìyànjú láti máa jẹun fún sáà gígùn kan, kíá ni àbájáde rẹ̀ lórí ìlera rẹ yóò fara hàn. Irú àbájáde wo? Ìwé ìtọ́kasí kan lórí ìṣègùn sọ pé: “Ipa tí ó wọ́pọ̀ jù lọ jẹ́ èyí tí ó burú: àìlèdàgbà dáradára, àìlègbógun-tàrùn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, àìlágbára tàbí àìlókun.” Àìlera kan nípa tẹ̀mí tí ó ṣeé fi wé e ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì ìgbàanì fún àkókò kan. Wòlíì Aísáyà sọ nípa wọn pé: “Gbogbo orí ni ó ṣàìsàn, gbogbo ọkàn ni ó sì dákú. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí fi dé orí, kò sí ìlera nínú rẹ̀.”—Aísáyà 1:5, 6.
Oúnjẹ àtàtà nípa tẹ̀mí ń fún wa ní agbára láti dènà irú àìlera nípa tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ àti àbájáde àìsàn nípa tẹ̀mí. Ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ń ṣèrànwọ́ láti mú wa wà ní ipò rere nípa tẹ̀mí—bí a bá ń jẹ ẹ́! Jésù Kristi sọ̀rọ̀ lórí bí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ní ọjọ́ rẹ̀, kò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àìbìkítà àwọn baba ńlá wọn, nínú ọ̀ràn jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí kánú. Àwọn pẹ̀lú kọ̀ láti jẹ òtítọ́ tí òun fi ń kọ́ni. Kí ni ó yọrí sí? Jésù wí pé: “Ọkàn àyà àwọn ènìyàn yìí ti sébọ́, wọ́n sì ti fi etí wọn gbọ́ láìsí ìdáhùnpadà, wọ́n sì ti di ojú wọn; kí wọ́n má baà fi ojú wọn rí láé kí wọ́n sì fi etí wọn gbọ́ kí òye rẹ̀ sì yé wọn nínú ọkàn àyà wọn kí wọ́n sì yí pa dà, kí n sì mú wọn lára dá.” (Mátíù 13:15) Ọ̀pọ̀ jù lọ kò jàǹfààní nínú agbára ìmúláradá tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní. Wọ́n wà gẹ́gẹ́ bí aláìsàn nípa tẹ̀mí. Àní àwọn Kristẹni kan, tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró pàápàá, di “aláìlera àti aláìsàn.” (Kọ́ríńtì Kíní 11:30) Ǹjẹ́ kí a má ṣe fojú tẹ́ńbẹ́lú oúnjẹ tẹ̀mí tí Ọlọ́run ń pèsè.—Orin Dáfídì 107:20.
Ìbàjẹ́ Nípa Tẹ̀mí
Yàtọ̀ sí ewu kíkú nípa tẹ̀mí nítorí àìjẹun nípa tẹ̀mí, ewu mìíràn tún ń bẹ tí a nílò láti wà lójúfò sí—irú oúnjẹ tí a ń jẹ fúnra rẹ̀ ti lè bà jẹ́. Gbígba àwọn ẹ̀kọ́ tí èrò líléwu ti àwọn ẹ̀mí èṣù ti bà jẹ́ sínú lè pa wá, gan-an gẹ́gẹ́ bí jíjẹ oúnjẹ ti ara tí kòkòrò àrùn ti bà lé, tàbí tí májèlé ti dà sí, ṣe lè pa wá. (Kólósè 2:8) Kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti dá oúnjẹ tí ó lè pani mọ̀. Aláṣẹ kan sọ pé: “Oúnjẹ kan lè dà bí èyí tí ó gbámúṣé, síbẹ̀ kí ó sì ní kòkòrò àrùn nínú.” Nítorí náà, yóò dára bí a bá ṣàyẹ̀wò orísun oúnjẹ ìṣàpẹẹrẹ wa, ní níní in lọ́kàn pé, a lè ti mú àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu àti ọgbọ́n èrò orí wọnú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kan, láti bà wọ́n jẹ́, bí irú ìwé àwọn apẹ̀yìndà. Àwọn olùṣe oúnjẹ jáde kan tilẹ̀ ń lo àwọn lébẹ́ẹ̀lì tí ń ṣini lọ́nà, láti tan àwọn oníbàárà wọn jẹ ní ti ohun tí ọjà náà ní nínú. Dájúdájú, a lè retí pé kí Sátánì, ẹlẹ́tàn ńlá náà, ṣe ohun kan náà. Nítorí náà, rí i dájú pé, o gba irú oúnjẹ ìṣàpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ láti orísun kan tí ó ṣeé gbára lé, kí o baà lè jẹ́ “onílera nínú ìgbàgbọ́.”—Títù 1:9, 13.
Thomas Adams, oníwàásù kan ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, sọ nípa àwọn ènìyàn àkókò rẹ̀ pé: “Wọ́n ti fi eyín ara wọn gbẹ́ sàréè ara wọn.” Ní èdè míràn, ohun tí wọ́n jẹ ni ó pa wọ́n. Rí i dájú pé, ohun tí o ń jẹ nípa tẹ̀mí kò pa ọ́. Wá ìpèsè oúnjẹ àtàtà nípa tẹ̀mí rí. Jèhófà Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ènìyàn rẹ̀, tí wọ́n yíjú sí àwọn olùkọ́ni èké àti àwọn wòlíì èké pé: “Nítorí kí ni ẹ ṣe ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe oúnjẹ? . . . Ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára, sì jẹ́ kí inú yín dùn nínú ọ̀rá. Ẹ tẹ́tí lélẹ̀, kí ẹ sì wá sọ́dọ̀ mi: ẹ gbọ́, ọkàn yín yóò sì yè.”—Aísáyà 55:2, 3; fi wé Jeremáyà 2:8, 13.
Ọ̀pọ̀ Yanturu Oúnjẹ Tẹ̀mí
Dájúdájú, kò sí àìtó oúnjẹ gbígbámúṣé nípa tẹ̀mí. Gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi ti sọ tẹ́lẹ̀, ó ní ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọgbọ́n inú nísinsìnyí, tí ọwọ́ rẹ̀ dí fún pípèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu’ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ẹ. (Mátíù 24:45) Nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà, Jèhófà ṣèlérí pé: “Kíyè sí i àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun, ṣùgbọ́n ebi yóò pa ẹ̀yin: . . . Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrin fún inú dídùn.” Ní tòótọ́, ó ṣèlérí àsè oúnjẹ fún àwọn tí wọ́n fẹ́ láti jẹun. “Olúwa àwọn ọmọ ogun yóò se àsè ohun àbọ́pa fún gbogbo orílẹ̀-èdè, àsè ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti ohun àbọ́pa tí ó kún ọ̀rá.”—Aísáyà 25:6; 65:13, 14.
Ṣùgbọ́n, ro èyí wò ná: Ebi lè pa wá kú níbi àsè! Níbi tí oúnjẹ ti yí wa ká, a tún lè wà láìjẹun kánú bí a kò bá ru ara wa sókè ní ti gidi, láti jẹ́ nínú rẹ̀. Òwe 26:15 fúnni ní àpèjúwe gidi yìí: “Ọ̀lẹ pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ ṣinṣin nínú ìṣaasùn; kò sì lè yọ ọ́ jáde pa dà wá sí ẹnu rẹ̀.” Ipò ìbànújẹ́ mà ni èyí jẹ́ o! Àwa pẹ̀lú lè ya ọ̀lẹ débi tí a kò fi ní lè làkàkà nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì, tí a pète láti ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ oúnjẹ tẹ̀mí. Tàbí kí a ya ọ̀lẹ débi tí yóò fi rẹ̀ wá jù láti múra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé ìjọ Kristẹni tàbí kí a kópa nínú wọn.
Àṣà Jíjẹun Kánú
Nígbà náà, a ní ìdí rere láti mú àṣà jíjẹun kánú nípa tẹ̀mí dàgbà. Ṣùgbọ́n, ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ gan-an ni pé, ọ̀pọ̀ máa ń ṣa oúnjẹ tẹ̀mí jẹ, àwọn kan tilẹ̀ ń febi pa ara wọn pátápátá. Wọ́n lè dà bí àwọn kan tí wọn kò rí ìjẹ́pàtàkì jíjẹ oúnjẹ àtàtà, àfi ìgbà tí wọ́n tó rí àbájáde rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nínú ìgbésí ayé. Ìwé náà, Healthy Eating, fúnni ní ìdí kan tí a fi lè má bìkítà nípa àṣà ìjẹun wa, bí a tilẹ̀ mọ̀ pé oúnjẹ àtàtà ṣe kókó fún ìwàláàyè: “Ìṣòro náà ni pé, [gẹ́gẹ́ bí àbájáde àṣà àìjẹun kánú] ìlera kì í tètè jó rẹ̀yìn, kì í tètè sí àbájáde kíákíá, irú bí èyí tí ń tẹ̀ lé fífònà dá láìwọ̀tún wòsì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlera ẹni lè máa rọra jó rẹ́yìn lọ́nà tí ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣeni lọ́ṣẹ́, àrùn lè tètè ranni, egungun lè tètè di fúẹ́fúẹ́, ọgbẹ́ sísan àti kíkọ́fẹpadà nínú àìsàn lè falẹ̀.”
Nínú àwọn ọ̀ràn tí ó burú jáì, ẹnì kan lè dà bí ọ̀dọ́bìnrin kan tí àrùn ìfòyà sísanra jù ń ṣe. Ó mú un dá ara rẹ̀ lójú pé, oúnjẹ díẹ̀ ni òun nílò, pé ara òun yá gágá, láìsì mọ̀ pé òun ń gbẹ. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, kò lè jẹun mọ́. Ìwé ìtọ́kasí kan lórí ìṣègùn sọ pé: “Ó jẹ́ ipò eléwu.” Èé ṣe? “Bí ebi kò tilẹ̀ pa aláìsàn náà kú, yóò gbẹ hangogo nítorí àìjẹunkánú, àrùn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ sì lè dá a wólẹ̀.”
Obìnrin Kristẹni kan jẹ́wọ́ pé: “Fún ọ̀pọ̀ ọdún, mo jìjàkadì pẹ̀lú mímọ ìjẹ́pàtàkì mímúrasílẹ̀ déédéé fún ìpàdé àti ìdákẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ n kì í sì í lè ṣe é.” Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó ṣe ìyípadà, tí ó fi wá di akẹ́kọ̀ọ́ tí ó jáfáfá nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kìkì nígbà tí ó tó mọ ìjẹ́kánjúkánjú ipò rẹ̀.
Nítorí náà, má ṣe gbàgbé ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pétérù fúnni. Di “ọmọdé jòjòló,” kí o sì ‘ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà, pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí o lè dàgbà dé ìgbàlà.’ (Pétérù Kíní 2:2) Bẹ́ẹ̀ ni, “ní ìyánhànhàn”—mú ọkàn ìfẹ́ lílágbára dàgbà—láti fi ìmọ̀ Ọlọ́run kún èrò inú àti ọkàn àyà rẹ. Àwọn àgbàlagbà nípa tẹ̀mí pẹ̀lú ní láti jẹ́ kí ìyánhànhàn náà máa bá a nìṣó. Má ṣe jẹ́ kí oúnjẹ tẹ̀mí di ‘ọ̀kan nínú àwọn ohun ìní rẹ tí ó ń ṣì lò.’ Jẹun kánú nípa tẹ̀mí, kí o sì jàǹfààní ní kíkún láti inú gbogbo “ọ̀rọ̀ afúnni nílera” tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì.—Tímótì Kejì 1:13, 14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
O ha ní láti mú kí ọ̀nà ìjẹun rẹ sunwọ̀n sí i bí?