Ǹjẹ́ O Máa Ń Jẹ Oúnjẹ Tẹ̀mí Dáadáa?
1 Wọ́n máa ń sọ pé ‘oúnjẹ lọ̀rẹ́ àwọ̀.’ Òótọ́ ni. Bí okun àti ìlera wa ṣe rí wà lọ́wọ́ bá a ṣe ń jẹun sí. Níwọ̀n bí Jésù ti sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà,” ó fi hàn pé bá a ṣe ń jẹun sí nípa tẹ̀mí ń ní ipa lórí wa sí rere tàbí sí búburú. (Mát. 4:4) Nítorí náà, báwo lo ṣe ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tẹ́rùn tó? Ṣé ńṣe lo máa ń ṣa oúnjẹ jẹ? Ṣé ńṣe lo máa ń kánjú jẹ ẹ́? Àbí inú rẹ máa ń dùn láti fara balẹ̀ jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀, tí ń ṣara lóore tí o sì ń jẹ ẹ́ déédéé?
2 Gbé Bí O Ṣe Ń Jẹun Yẹ̀ Wò: Jèhófà ń tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu’ àti “àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn.” (Mát. 24:45; Aísá. 25:6) Láti máa jàǹfààní ní kíkún látinú àwọn ohun tó ń fìfẹ́ pèsè yìí, a gbọ́dọ̀ sapá gan-an láti máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí dáadáa.
3 O lè bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ṣé mo máa ń ka ẹsẹ ojoojúmọ́ àti àlàyé rẹ̀ lójoojúmọ́? Ṣé mo máa ń ka Bíbélì tí mo sì máa ń ronú lórí rẹ̀ lójoojúmọ́? Ṣé mo máa ń múra àwọn ìpàdé ìjọ nípa kíka àwọn ohun tí a óò gbọ́ níbẹ̀ ṣáájú àkókò? Ǹjẹ́ mo ti ka àwọn ìtẹ̀jáde wa tó dé kẹ́yìn, títí kan Apá Kìíní ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé?’
4 Jésù ṣèlérí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn . . . Aláyọ̀ ni àwọn tí ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo, níwọ̀n bí a ó ti bọ́ wọn yó.” (Mát. 5:3, 6) Nítorí náà, máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí dáadáa nípa fífi ìmọ̀ Ọlọ́run kún inú àti ọkàn rẹ.