Pípésẹ̀ sí Ìpàdé Déédéé—Ṣe Kókó fún Dídúró Gbọn-ingbọn-in Wa
1 Aposteli Paulu rọ̀ wá láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ “onílera ninu ìgbàgbọ́.” (Titu 1:9, 13) Ní àwọn ìpàdé ìjọ, a máa ń gbé àwọn èrò tí ń gbéni ró yẹ̀ wò, a sì máa ń gba ìtọ́ni lórí bí a ṣe lè gbé ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí wọ̀, kí a baà lè “dúró gbọn-in-gbọn-in lòdì sí awọn ètekéte Èṣù.”—Efe. 6:11; Filip. 4:8.
2 Àwọn Ìpàdé Ń Pèsè Àwọn Ohun Tí A Nílò: Pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé ṣe kókó fún dídúró gbọn-ingbọn-in wa. (1 Kor. 16:13) Ní àwọn ìpàdé, a máa ń gbàdúrà láti dúpẹ́ àti láti yin Ọlọrun, ní àfikún sí rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i nítorí ìjọ àti àwọn àìní rẹ̀. (Filip. 4:6, 7) Dídara pọ̀ nínú kíkọrin Ìjọba ń gbé wa ró, ó sì ń mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti fi èrò àti ìmọ̀lára wa hàn, bí a ti ń jọ́sìn Jehofa. (Efe. 5:19, 20) Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wa nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣáájú àti lẹ́yìn ìpàdé, máa ń fún wa níṣìírí, ó ń gbé wa ró, ó sì ń tù wá lára.—1 Tessa. 5:11.
3 Ní April ọdún yìí, ọ̀rọ̀ àsọyé àkànṣe náà, “Òpin Ìsìn Èké Ti Súnmọ́lé,” fi tagbáratagbára tẹ ìjẹ́kánjúkánjú gbígbégbèésẹ̀ lójú ẹsẹ̀ láti jáde kúrò nínú Babiloni Ńlá, mọ́ àwọn olùfẹ́ òtítọ́ lọ́kàn. (Ìṣí. 18:4) Ní June àti July, ẹ wo bí ó ti gbádùn mọ́ni tó láti kárí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ mẹ́ta nínú Ilé-Ìṣọ́nà, lórí ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí ó ti mọ́lẹ̀ sí ojú ọ̀nà àwọn olódodo! (Owe 4:18) Ronú nípa àwọn ohun tí à bá ti pàdánù ká sọ pé a pa àwọn ìpàdé wọ̀nyẹn jẹ.
4 Bí ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa ti sọ, ní ojú ìwé 72, Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun jẹ́ ìpèsè kan fún bíbá a nìṣó láti máa kọ́ odindi ìjọ lẹ́kọ̀ọ́. A kò lè sọ àǹfààní tí a ní fún kíkẹ́kọ̀ọ́ yìí nù.
5 Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí a ń ṣe, ń mú wa gbara dì láti túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ìpàdé tí a ti fún wa ní ìtọ́ni láti ṣàjọpín nínú pípín Ìròyìn Ìjọba nọmba 34 fi èyí hàn. Àwọn ìbùkún Jehofa lórí iṣẹ́ yìí pọ̀ jaburata, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú àbájáde tí kò lẹ́gbẹ́ kárí ayé. (Fi wé 2 Korinti 9:6, 7.) A fún àwọn tí ń pésẹ̀ déédéé sí ìpàdé níṣìírí, wọ́n sì ṣèrànwọ́ nínú títi ìgbétásì náà lẹ́yìn.
6 Nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, àwọn ohun tí a ń kọ́ láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń mú kí ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú wa jí pépé sí i. Bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti ń yára wáyé, a ní láti lóye ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rírinlẹ̀ inú Bibeli.
7 Jẹ́ Kí Pípésẹ̀ sí Ìpàdé Déédéé Gba Ipò Àkọ́kọ́: Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tí àwọn ará wa ti ń jìyà, wọ́n ṣì lóye bí pípéjọ pọ̀ wọn ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó. Fún àpẹẹrẹ, ní Burundi, Rwanda, Liberia, àti ní Bosnia-òun-Herzegovina, àwọn ẹni tuntun tí ń wá sí ìpàdé fi ìlọ́po méjì tàbí mẹ́ta ju àwọn akéde tí ń wá lọ. Ní ọ̀nà yìí, Jehofa ń ran àwọn ará lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní dídúró gbọn-ingbọn-in nínú ẹ̀mí kan.—Filip. 1:27; Heb. 10:23-25.
8 Ẹni tí ó bá ti máa ń pa ìpàdé jẹ ní láti gbé ìgbésẹ̀ nísinsìnyí láti ṣe àtúnṣebọ̀sípò. (Oniwasu 4:9-12) Kí ó baà lè ṣeé ṣe fún wa láti dúró gbọn-ingbọn-in, a nílò pàṣípààrọ̀ ìṣírí pẹ̀lú àwọn tí ó dàgbà dénú, èyí tí pípésẹ̀ déédéé sí ìpàdé mú kí ó ṣeé ṣe.—Romu 1:11.