Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún November
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 6
Orin 6
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a ṣà yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Ẹ Máa Gbé Èrò Inú Yín Ka Àwọn Nǹkan Ti Òkè.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
20 min: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ Ni Ó Ṣàǹfààní fún Kíkọ́ni.” Jíròrò àwọn apá ẹ̀ka Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun, ní fífi bí ó ti gbọ̀gá lọ́wọ́ àwọn yòókù hàn. Ṣàlàyé àwọn àǹfààní tí ó ní nítorí tí a fi èdè òde òní kọ ọ́. Jẹ́ kí a ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ méjì.
Orin 78 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 13
Orin 33
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: “Jíjọ̀wọ́ Ara Wa Tinútinú fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo.” Ọ̀rọ̀ àsọyé onítara ọkàn láti ẹnu alàgbà, lórí ìpínrọ̀ 1 sí 9.
20 min: “Jíjọ̀wọ́ Ara Wa Tinútinú fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo.” Kí a kárí ìpínrọ̀ 10 sí 15 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Tọ́ka sí àwọn àìní àdúgbò àti ọ̀nà tí gbogbo àwùjọ lè gbà ṣèrànwọ́.
Orin 156 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 20
Orin 64
5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
20 min: “Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Mọrírì Ìníyelórí Bibeli.” Alàgbà jíròrò ìdí tí ó fi yẹ kí a ṣe ìpadàbẹ̀wò pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, pẹ̀lú àwọn akéde méjì tàbí mẹ́ta. Ẹ ṣàtúnyẹ̀wò, kí ẹ sì ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ fún ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò tí a dámọ̀ràn, bíi pé ẹ ń ṣe ìdánrawò.
20 min: “Ẹ Máa Hùwà Ní Irú Ọ̀nà Kan Tí Ó Yẹ Ìhìn Rere.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà ti June 15, 1989, ojú ìwé 16 sí 17, ìpínrọ̀ 5 sí 9, kún un.
Orin 23 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 27
Orin 96
5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
13 min: “Pípésẹ̀ sí Ìpàdé Déédéé—Ṣe Kókó fún Dídúró Gbọn-ingbọn-in Wa.” Ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ.
15 min: “Fífi Ìfẹ́ Kristian Yanjú Ìṣòro.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka gbogbo ìpínrọ̀.
12 min: Fífi Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí Lọni ní Oṣù December. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn apá fífani mọ́ra tí ó wà nínú ìwé náà—àwọn àkòrí tí ń runi lọ́kàn sókè àti àwọn àwòrán fífani mọ́ra, ní àfikún sí àwọn àlàyé rírọrùn àti lílo àwọn ìbéèrè lọ́nà jíjáfáfá. Fa àwọn kókó ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ díẹ̀ tí yóò fa ọkàn àwọn ènìyàn ní ìpínlẹ̀ yín mọ́ra yọ. Jẹ́ kí akéde tí ó dáńgájíá kan ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kan tàbí méjì, ní ṣókí. Rọ gbogbo àwùjọ láti lo ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ lọ́nà rere, ní December.
Orin 8 àti àdúrà ìparí.