Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní November: Gẹ̀ẹ́sì—New World Translation of the Holy Scriptures àti ìwé The Bible—God’s Word or Man’s? fún ₦400 (Bibeli nìkan, ₦320). Yorùbá—Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun, fún ₦120. Àwọn èdè yòókù—Iwe Itan Bibeli Mi, fún ₦240, tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye (ńlá, ₦120; kékeré, ₦120). December: Gbogbo èdè—Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí kò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó, lo Iwe Itan Bibeli Mi tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. January: Gbogbo èdè—Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí, tí a tẹ̀ sórí pépà ti ń di pípọ́n ràkọ̀ràkọ̀ tàbí tí ń pàwọ̀ dà tàbí èyíkéyìí tí a tẹ̀ jáde ṣáájú 1982, ni a lè fi lọni ní ẹ̀dínwó. A kò gbọdọ̀ fi àwọn ìtẹ̀jáde tí a tẹ̀ sórí àwọn pépà tí kì í ṣá tàbí pàwọ̀ dà kún àwọn ìfilọni ẹlẹ́dìn-ínwó wọ̀nyí. February: Efik, Gẹ̀ẹ́sì, àti Igbo—Revelation—Its Grand Climax At Hand! Àwọn èdè yòókù—Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí, ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Society nílò àwọn tí ó lè ṣètumọ̀ sí àwọn èdè wọ̀nyí: Efik, Gun, Hausa, Igala, Igbo, Isoko, Tiv, àti Yorùbá. Ẹni náà ti ní láti lo, ó kéré tán, ọdún 12 ní ilé ẹ̀kọ́, pẹ̀lú credit nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì, nínú ìwé ẹ̀rí GCE fún ìpele ẹ̀kọ́ ilé ìwé gíga tàbí WASC/SSCE àti credit nínú èdè ìbílẹ̀ rẹ̀, bí ó bá ṣe é nínú ìdánwò GCE tàbí WASC/SSCE (èkejì kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan). Ẹnikẹ́ni tí ó bá rò pé òún lè tóótun, tí ó sì nífẹ̀ẹ́ láti ṣiṣẹ́ sìn ní Beteli, ní láti kọ̀wé sí Society, kí ó sì béèrè fún fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́ Beteli. Lẹ́tà náà ní láti ní ìsọfúnni nípa ìwọ̀n ẹ̀kọ́ ìwé tí ó ní, àti èdè tí ó rò pé òún lè tóótun fún gẹ́gẹ́ bí olùtúmọ̀ kan. A tún dá a lámọ̀ràn pé, kí ó fi ẹ̀dà èsì ìdánwò tàbí ìwé ẹ̀rí rẹ̀ ṣọwọ́ sí wa. Bí ó bá ní ju GCE tàbí WASC/SSCE lọ, ó lè fi ẹ̀dà ìwé ẹ̀rí ìwọ̀n ẹ̀kọ́ tí ó ní ṣọwọ́ sí wa. Àwọn àpọ́n tàbí àwọn tí ó ti ṣègbéyàwó, ṣùgbọ́n tí wọn kò tí ì lọ́mọ, ni a ń fẹ́, wọ́n sì ní láti wà ní ipò tí yóò ṣeé ṣe fún wọn láti tẹ́wọ́ gba ìkésíni wá sí Beteli.