Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun
Àtúnyẹ̀wò pípa ìwé dé lórí àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún àwọn ọ̀sẹ̀ July 24 sí November 13, 1995. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, kìkì Bibeli nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀lé àwọn ìbéèrè wà fún ìṣèwádìí fúnra rẹ. Nọ́ḿbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́kasí tí a ṣe sí Ilé-Ìṣọ́nà.]
Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀lé e yìí:
1. Kò sí ìdí láti fojú sí ẹ̀kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́, nítorí púpọ̀ ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni ni a kì yóò lò láé. [4, yy-YR ojú ìwé 81]
2. A lè wo ìlò ọtí líle àti oògùn gẹ́gẹ́ bí ìgbádùn tí kò lè pani lára. [10, yy-YR ojú ìwé 97]
3. Sìgá mímu kò lè pani lára rárá, ó sì lè mú ìgbádùn púpọ̀ wá. [13, yy-YR ojú ìwé 112]
4. O ní láti fetí sílẹ̀ dáradára sí gbogbo ìtọ́ni láti orí pèpéle nígbà tí o bá wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. [1, sg-YR ojú ìwé 24 àti 25]
5. Bí ó bá ṣeé ṣe, gbogbo ìdílé ní láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé. [13, sg-YR ojú ìwé 37 àti 38]
6. Nípa fífi taápọntaápọn kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́, ìwọ yóò fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristian kan. [4, yy-YR ojú ìwé 82]
7. Ìwé kíkà ní gbangba ṣe pàtàkì púpọ̀, láti lè kàwé dáradára sì ṣe kókó fún gbogbo òjíṣẹ́. [3, sg-YR ojú ìwé 30]
8. Ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà kọ̀ọ̀kan ṣe pàtàkì púpọ̀, a sì ní láti baralẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ bí ó bá ti lè tètè ṣeé ṣe tó lẹ́yìn tí a bá ti gbà á. [13, sg-YR ojú ìwé 36]
9. Ọ̀rọ̀ Solomoni ní Oniwasu 3:1, 2 wulẹ̀ ń tọ́ka sí bíbá a nìṣó ìyípo àkókò ìwàláàyè àti ikú ni, kì í sì í ṣe sí àyànmọ́ oníkálùkù. [6, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 10/15/91 ojú ìwé 5.]
10. Àwọn òbí tí ń yọ̀ǹda fún àwọn ọmọ wọn láti wo ohunkóhun tí a ń fi hàn lórí tẹlifíṣọ̀n, ní ti gidi, ń fi wọ́n sílẹ̀ láìṣàkóso. (Owe 29:15) [5, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 8/1/88 ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 8.]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀lé e yìí:
11. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a dẹ́bi fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún ṣíṣe lámèyítọ́ àwọn ìsìn mìíràn? [1, td-YR 32C]
12. Èé ṣe tí ìgbàgbọ́ náà pé “rere ń bẹ nínú gbogbo ìsìn” fi jẹ́ ẹ̀tàn? [3, td-YR 32G]
13. Ìrètí wo ni àwọn Kristian ní fún àwọn olólùfẹ́ wọn tí ó ti kú? [4, td-YR 3A]
14. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé ìpadàbọ̀ Jesu yóò jẹ́ èyí tí a kò lè fojú rí? [6, td-YR 29A]
15. Àwọn ìlànà òdodo wo ni a tẹnu mọ́ nínú Orin Solomoni? [10, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
16. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ ní Isaiah 14:4, 12-14, ìṣarasíhùwà ta ni ọba Babiloni fi hàn? [16, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 9/15/85 ojú ìwé 16, ìpínrọ̀ 2.]
17. Ta ni olùṣọ́ òde òní, kí sì ni ó ń kéde? (Isa. 21:8, 12) [17, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 3/1/87 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 10.]
18. Èé ṣe tí Oniwasu 12:12 fi gbé ojú ìwòye tí ó lòdì bẹ́ẹ̀ kalẹ̀ nípa ìwé? [9, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 9/15/87 ojú ìwé 25.]
19. Báwo ni ìfẹ́ ṣe “lágbára bí ikú”? (Orin Sol. 8:6, 7) [11, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 11/15/87 ojú ìwé 25.]
20. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “asán” tí a lò ní ọ̀pọ̀ ìgbà nínú ìwé Oniwasu? [6, w-YR 9/15/87 ojú ìwé 24]
21. Ní Isaiah 6:8 Jehofa béèrè lọ́wọ́ Isaiah pé: “Ta ni èmi óò rán?” Ìdáhùn wo tí Isaiah fúnni ni ó jẹ́ ìṣírí ńláǹlà fún wa lónìí? [13, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
22. Ta ni yóò jẹ́ alákòóso tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ ní Isaiah, orí 11, àwọn àǹfààní wo sì ni àkóso rẹ̀ yóò mú wá? [15, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
23. Nígbà wo ni a lè retí pé kí àwọn ipò àgbàyanu tí a ṣàpèjúwe ní Isaiah, orí 2, ṣẹlẹ̀ kárí ayé? [12, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
24. Èé ṣe tí yóò fi lòdì fún Kristian kan láti mu sìgá? [14, yy-YR ojú ìwé 112]
25. Ní àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ pàtó wo ni lílè kàwé dáradára ṣe pàtàkì jù lọ? [3, sg-YR ojú ìwé 30]
26. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó ṣeé ṣe, ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́ wo ni ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan tẹ̀lé? [13, sg-YR ojú ìwé 37]
27. Èé ṣe tí Jehofa fi kọ̀ láti fetí sí ọ̀pọ̀ àdúrà tí a gbà sí i? [12, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
Mú ìdáhùn tí ó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀lé e yìí:
28. Ní ìbámu pẹ̀lú Owe 26:20, 21, bí a bá jẹ́ (ẹni tí ń yára fèsì; aláìfọ̀rọ̀bọpobọyọ̀; onínú tútù), dípò ‘kíkó igi sí iná’ àti mímú àwọn ẹlòmíràn bínú, àwa yóò ní (ìṣòro ara ẹni; ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí kò dán mọ́rán; ìbátan rere) pẹ̀lú wọn. [3, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 10/15/91 ojú ìwé 13, ìpínrọ̀ 16.]
29. Ní ìbámu pẹ̀lú Owe 27:6, ẹnì kan tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ (kì yóò sọ ohunkóhun láé láti pa ìmọ̀lára rẹ lára; yóò bẹ̀rù láti sọ òtítọ́ nípa ara rẹ fún ọ; yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn nígbà tí o bá nílò rẹ̀). [4, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 9/15/90 ojú ìwé 28.]
30. Àwọn ènìyàn tí ó rò pé ìwà ọ̀làjú ni ẹ̀mí ìrònú má-ṣèdájọ́-ẹnikẹ́ni, gbogbo ohun tí ó bá ti wáyé náà ni ó dára, ti òde òní (kò lè pani lára; wulẹ̀ gbàgbàkugbà; wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí) ní ti gidi. (Isa. 5:20) [13, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 3/1/93 ojú ìwé 11.]
31. Orin Solomoni tẹnu mọ́ (ipò Solomoni gẹ́gẹ́ bí ọba; ọrọ̀ ńlá Solomoni; ìdúróṣinṣin ọmọbìnrin tí ń gbé inú oko sí ọmọkùnrin olùṣọ́ àgùtàn kan). [10, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]
So àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ tí ó tẹ̀lé e yìí mọ́ àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí:
Owe 22:3; Owe 31:29; Isa. 13:19, 20; Isa. 48:17
32. Ní kíkìlọ̀ fún wa lòdì sí àwọn àṣà tí ń pani lára, Ọlọrun ní ti tòótọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí ayé lọ́nà tí ó dára jù lọ. [14, yy-YR ojú ìwé 114]
33. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í fi dandan ṣẹlẹ̀ pé kí Jehofa pèsè ìdáàbòbò ojú ẹsẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ jàm̀bá, ogun abẹ́lé, tàbí ìwà ọ̀daràn, lílo ọgbọ́n tí ó ṣeé múlò tí a gbé karí Bibeli lè níye lórí. [1, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 1/1/92 ojú ìwé 17, ìpínrọ̀ 23.]
34. Nígbà tí aya kan bá jẹ́ òṣìṣẹ́ tí ó sì jẹ́ adúróṣinṣin, ọkọ rẹ̀ lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn wọ̀nyí.
35. A ní ìdí rere láti máṣe ṣiyè méjì láé nípa ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí a mí sí. [15, Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w-YR 5/15/93 ojú ìwé 6.]