Jíjọ̀wọ́ Ara Wa Tinútinú fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo
1 Ìwé ayé kan sọ̀rọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, pé: “Yóò ṣòro láti rí àwọn mẹ́ḿbà àwùjọ mìíràn tí ń ṣiṣẹ́ kára nídìí ìsìn wọn bíi ti àwọn Ajẹ́rìí.” Èé ṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ń ṣiṣẹ́ kára tó bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe é tinútinú?
2 Ìdí kan ni pé, a ti gbin ẹ̀mí kánjúkánjú sí wọn lọ́kàn. Jesu mọ̀ pé àkókò tí òún ní láti fi parí iṣẹ́ òun lórí ilẹ̀ ayé kò tó nǹkan. (Joh. 9:4) Bí Ọmọkùnrin Ọlọrun tí a ṣe lógo ti ń tẹrí àwọn ọ̀tá rẹ̀ ba lónìí, àwọn ènìyàn Jehofa mọ̀ pé àkókò tí àwọn ní láti fi ṣe iṣẹ́ wọn kò tó nǹkan. Nítorí náà, wọ́n tẹpẹlẹ mọ́ jíjọ̀wọ́ ara wọn tinútinú fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀. (Orin Da. 110:1-3) Bí àìní ti wà fún àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i láti kórè, wọn kò lè dẹwọ́ ìsapá wọn nílẹ̀. (Matt. 9:37, 38) Nípa báyìí, wọ́n ń sapá láti fara wé Jesu, tí ó fi àpẹẹrẹ pípé pérépéré nípa ìmúratán àti ìṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ lélẹ̀.—Joh. 5:17.
3 Ìdí mìíràn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́, bí ẹni pé fún Jehofa, ni pé, ètò àjọ àgbáyé wọn yàtọ̀ pátápátá sí àwọn àwùjọ yòókù. Ohun tí àwọn ètò ìsìn ayé ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn kò ju ìwọ̀nba àkókò àti ìsapá. Ipa bínńtín ni ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ní lórí ìgbésí ayé wọn, lórí ìbálò wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, tàbí lórí ìlépa wọn nínú ìgbésí ayé. Níwọ̀n bí wọn kò ti ní agbára ìsúnniṣe tí ń bá ìgbàgbọ́ tòótọ́ rìn, wọ́n ti fi dandan lé e pé kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ‘sọ nǹkan dídùn fún wọn,’ ní fífi dá wọn lójú pé ìsapá bínńtín wọn ti tó. (Isa. 30:10) Àwọn àlùfáà wọn ti gbà pẹ̀lú wọn nípa ‘rírìn wọ́n ní etí,’ ní gbígbin ẹ̀mí àgunlá àti ìṣọ̀lẹ nípa tẹ̀mí sí wọn lọ́kàn.—2 Tim. 4:3.
4 Ẹ wo bí èyí ti yàtọ̀ pátápátá tó láàárín àwọn ènìyàn Jehofa! Ohun gbogbo nípa ìjọsìn wa gba ìsapá, ìtiraka, àti iṣẹ́. A ń fi ohun tí a gbà gbọ́ sílò lójoojúmọ́ àti nínú gbogbo ohun tí a ń ṣe. Bí òtítọ́ tilẹ̀ ń mú wa dunnú lọ́pọ̀lọpọ̀, a ń ja “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàkadì” láti baà lè mú ohun tí ó ń béèrè fún ṣẹ. (Fi wé 1 Tessalonika 2:2.) Bíbójú tó ojúṣe ìgbésí ayé ojoojúmọ́ ti tó láti mú ọwọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn há gádígádí. Bí ó ti wù kí ó rí, a kò gba àwọn àníyàn wọ̀nyí láyè láti dí wa lọ́wọ́ nínú fífi ire Ìjọba náà ṣe àkọ́kọ́.—Mat. 6:33.
5 Ohun tí a fún wa láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa ṣàǹfààní púpọ̀, ó sì jẹ́ kánjúkánjú débi pé, a sún wa láti ‘ra àkókò padà’ nínú àwọn ìlépa mìíràn, kí a sì lò ó ní ọ̀nà tí ó túbọ̀ ṣàǹfààní lórí àwọn ohun tẹ̀mí. (Efe. 5:16) Ní mímọ̀ pé ìfọkànsìn oníwà-bí-ọlọrun wa àti ẹ̀mí ìmúratán wa ń mú ọkàn Jehofa yọ̀, a ní ìsúnniṣe tí ó ga jù lọ láti máa bá iṣẹ́ àṣekára wa nìṣó. Pẹ̀lú àwọn ìbùkún jìngbìnnì tí a ń rí gbà nísinsìnyí àti ìrètí ìwàláàyè ọjọ́ iwájú, ìpinnu wa ni láti máa bá a lọ ní ‘ṣíṣiṣẹ́ kára kí a sì tiraka’ nítorí ire Ìjọba.—1 Tim. 4:10.
6 Ìfọkànsìn àti Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ: Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn lónìí ń fi ire àti àìní ti ara ṣe èkínní lórí gbogbo nǹkan yòókù. Wọn kò rò pé àwọn ń ṣe ohun tí ó burú nípa pípọkàn pọ̀ sórí ohun tí wọn yóò jẹ, mu, tàbí wọ̀. (Matt. 6:31) Nítorí pé àwọn ohun kòṣeémánìí kò tẹ́ wọn lọ́rùn, góńgó gbígbé ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì nísinsìnyí àti ‘níní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere tí a tòjọ pamọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, kí wọ́n baà lè farabalẹ̀ pẹ̀sẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn ara wọn,’ ni ń sún wọn ṣiṣẹ́. (Luku 12:19) Olùre ṣọ́ọ̀ṣì àfiṣàpẹẹrẹ ń ronú pé ìsapá ara ẹni èyíkéyìí tí ìsìn òún lè máa béèrè lọ́wọ́ òun jẹ́ dídu òun lẹ́tọ̀ọ́ òun. Èrò jíjáwọ́ nínú àwọn ìlépa onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì tàbí dídín in kù pàápàá tàbí fífi ire tí ó gbádùn mọ́ni sílẹ̀, burú bùrùjà. Pẹ̀lú ìrònú rẹ̀ tí ó gbé karí ara rẹ̀, mímú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ dàgbà kò mọ́gbọ́n dání, kò sì gbéṣẹ́.
7 Ojú tí a fi ń wo ọ̀ràn yìí yàtọ̀ pátápátá. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti gbé ìrònú wa ga sókè, débi pé, bí Ọlọrun ti ń ronú ni a ṣe ń ronú, kì í ṣe bíi ti ènìyàn. (Isa. 55:8, 9) Àwọn góńgó wa nínú ìgbésí ayé ré kọjá àwọn ìlépa ti ara. Ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Jehofa àti ìsọdimímọ́ orúkọ rẹ̀ ni àwọn ọ̀ràn tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ní gbogbo àgbáyé. Ìjẹ́pàtàkì àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí ga lọ́lá débi pé, ní ìfiwéra, gbogbo orílẹ̀-èdè “dà bí òfo níwájú rẹ̀.” (Isa. 40:17) A gbọ́dọ̀ wo ìsapá èyíkéyìí láti gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tí ó ṣá ìfẹ́ inú Ọlọrun tì gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀.—1 Kor. 3:19.
8 Nítorí náà, bí a tilẹ̀ nílò àwọn ohun ti ara díẹ̀, tí àwọn díẹ̀ sì wúlò fún bíbá àwọn ìgbòkègbodò Ìjọba wa lọ, a ronú pé àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í ṣe “awọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù” ní ti gidi. (Filip. 1:10) A ní ẹ̀mí 1 Timoteu 6:8 ní dídín ìlépa àwọn ire ti ara kù, tí a sì ń fi ọgbọ́n sakun láti pọkàn wa pọ̀ sórí ‘awọn ohun tí a kò rí tí ó jẹ́ fún àìnípẹ̀kun.’—2 Kor. 4:18.
9 Bí a bá ṣe ń ronú nípa àwọn èrò Ọlọrun sí, bẹ́ẹ̀ ni àníyàn wa nípa àwọn ohun ti ara yóò ṣe máa dín kù sí i. Nígbà tí a bá ronú lórí àwọn ohun tí Jehofa ti ṣe fún wa àti àwọn ìbùkún àgbàyanu tí ó ti ṣèlérí fún ọjọ́ iwájú, a ti ṣe tán láti ṣèrúbọ èyíkéyìí tí ó bá béèrè lọ́wọ́ wa. (Marku 10:29, 30) A jẹ ẹ́ ní gbèsè ìwàláàyè wa gan-an. Bí kì í bá ṣe àánú àti ìfẹ́ rẹ̀ ni, a kì bá tí gbádùn ìgbésí ayé nísinsìnyí, a kì bá tí ní ọjọ́ ọ̀la èyíkéyìí pàápàá. A ronú pé ó di ọ̀ranyàn fún wa láti jọ̀wọ́ ara wa fún un, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé gbogbo ohun tí a ń ṣe nínú ìsìn rẹ̀ ‘ni ó yẹ kí a máa ṣe.’ (Luku 17:10) Ohunkóhun tí a bá béèrè lọ́wọ́ wa láti fi fún Jehofa, a ń fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà yọ̀ọ̀da, ní mímọ̀ pé a óò “ká yanturu.”—2 Kor. 9:6, 7.
10 A Nílò Àwọn Òṣìṣẹ́ Afitinútinú Ṣiṣẹ́ Nísinsìnyí: Ìjọ Kristian kó wọnú àkókò ìgbòkègbodò kíkún fọ́fọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ rẹ̀. Wọ́n ní láti fúnni ní ìwàásù kúnnákúnná ṣáájú kí a tó dojú Jerusalemu dé ní 70 C.E. Ní àkókò yẹn, ọwọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu “dí jọjọ pẹlu ọ̀rọ̀ naa.” (Ìṣe 18:5) Ìmúgbòòrò tí ń yára kánkán náà mú kí ó di dandan láti kọ́ àwọn ajíhìnrere àti àwọn olùṣọ́ àgùntàn jíjá fáfá púpọ̀ sí i àti láti lò wọ́n. Wọ́n nílò àwọn ọkùnrin tí ó mọ bí a ti ń bá àwọn aláṣẹ ayé lò àti àwọn ọkùnrin tí ó dáńgájíá tí ó lè bójú tó ìkójọ àti ìpínkiri àwọn ohun ti ara. (Ìṣe 6:1-6; Efe. 4:11) Bí àwọn kan tilẹ̀ ṣiṣẹ́ lọ́nà tí ó hàn gbangba, ọ̀pọ̀ jù lọ ni a kò mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo wọn ni ó “fi tokuntokun tiraka,” ní fífi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ papọ̀ láti rí i pé iṣẹ́ náà di ṣíṣe.—Luku 13:24.
11 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sídìí fún ìgbòkègbodò kíkún fọ́fọ́ kárí ayé láàárín àwọn ọ̀rúndún tí ó tẹ̀ lé e, ìmúpadàbọ̀sípò ńlá nínú ìgbòkègbodò Ìjọba bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jesu gba agbára Ìjọba rẹ̀ ní 1914. Lákọ̀ọ́kọ́, ọ̀pọ̀ kò mọ̀ pé àìní fún àwọn òṣìṣẹ́ fún ire Ìjọba yóò di ńlá, tí ń béèrè fún ìrànwọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùyọ̀ọ̀da ara ẹni ní àwọn ilẹ̀ kárí ayé.
12 Lónìí, ètò àjọ náà ń kó wọnú onírúurú ìwéwèédáwọ́lé tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ ohun àmúṣọrọ̀ wa tán. Ìgbòkègbodò Ìjọba ń yára kánkán. Ìjẹ́kánjúkánjú àkókò wa ń mú kí a tiraka, kí a sì lo gbogbo ohun tí a ní láti ṣàṣeparí iṣẹ́ tí ó wà lọ́wọ́. Pẹ̀lú òpin gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan búburú tí ń sún mọ́lé, a ń fojú sọ́nà fún ìgbòkègbodò tí ó túbọ̀ kún fọ́fọ́ ní àwọn ọjọ́ tí ń bẹ níwájú. A ké sí gbogbo ìránṣẹ́ Jehofa tí ó ti ṣèyàsímímọ́ láti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ tinútinú fún iṣẹ́ ìkójọ jíjẹ́ kánjúkánjú yìí.
13 Àwọn Ohun Wo Ni Ó Yẹ Ní Ṣíṣe? A lè sọ ní tòótọ́ pé, ‘púpọ̀ rẹpẹtẹ wà lati ṣe ninu iṣẹ́ Oluwa.’ (1 Kor. 15:58) Ní ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀, ìkórè náà ti gbó, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ kò tó nǹkan. A ké sí wa láti ṣe ipa tiwa, kì í ṣe nínú títúbọ̀ jẹ́rìí kúná jákèjádò ìpínlẹ̀ wa nìkan ni, ṣùgbọ́n nínú kíkún ojú ìwọ̀n ìpèníjà náà láti ṣiṣẹ́ sìn níbi tí àìní ti pọ̀ jù pẹ̀lú.
14 O wúni lórí láti rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí ní apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé ti ń fi tinútinú jọ̀wọ́ ara wọn fún àwọn ìgbòkègbodò mìíràn. Èyí lè jẹ́ nínú yíyọ̀ọ̀da ara wọn fún kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn, ṣíṣiṣẹ́ sìn ní àwọn àpéjọpọ̀, ṣíṣèrànwọ́ nínú àwọn ìsapá láti pèsè ìrànwọ́ ní àwọn àkókò ìjábá, àti pípa Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò mọ́ ní tónítóní déédéé. Ní ti ìgbòkègbodò tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn yìí, ó yẹ kí a rí i dájú pé a fi Gbọ̀ngàn Ìjọba sílẹ̀ ní mímọ́ tónítóní àti létòlétò lẹ́yìn ìpàdé kọ̀ọ̀kan. Ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tí a lè kà sí yẹpẹrẹ ń fi hàn pé a lóye àwọn ọ̀rọ̀ Jesu tí ó wà nínú Luku 16:10 dáradára pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ ninu ohun tí ó kéré jùlọ jẹ́ olùṣòtítọ́ ninu ohun tí ó pọ̀ pẹlu, ẹni tí ó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo ninu ohun tí ó kéré jùlọ jẹ́ aláìṣòdodo ninu ohun tí ó pọ̀ pẹlu.”
■ Ṣètìlẹ́yìn fún Àwọn Ìgbòkègbodò Ìjọ: Bí ìjọ kọ̀ọ̀kan tilẹ̀ ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí apá kan ètò àjọ látòkèdélẹ̀, tí ó sì ń gba ìtọ́ni láti ọ̀dọ “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú,” àwọn akéde Ìjọba kọ̀ọ̀kan ni ó para pọ̀ dà á. (Matt. 24:45) Àṣeyọrí rẹ̀ sinmi púpọ̀ lórí bí Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan ṣe fẹ́ láti ṣe tó àti bí ó ti lágbára tó láti ṣe. Ìjọ ń pọkàn pọ̀ sórí wíwàásù ìhìn rere ní ìpínlẹ̀ rẹ̀, sísọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn tuntun, àti fífún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Ẹni kọ̀ọ̀kan wa lè ṣàjọpín nínú iṣẹ́ yìí. A tún lè gbé àwọn góńgó kalẹ̀ fún ara wa nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́, kíkópa jíjọjú nínú ìpàdé, àti ríran àwọn tí ó wà nínú àìní lọ́wọ́ láàárín ìjọ. Àwọn ìgbòkègbodò wọ̀nyí ń ṣí àwọn àǹfààní púpọ̀ sílẹ̀ fún wa láti fi ìmúratán wa hàn kedere.
■ Mímú Ipò Iwájú Nínú Ipò Àbójútó: Jehofa ti fi àbójútó ìjọ kọ̀ọ̀kan sí ìkáwọ́ àwọn alàgbà rẹ̀ tí a yàn sípò. (Ìṣe 20:28) Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti nàgà láti tóótun fún àǹfààní yìí. (1 Tim. 3:1) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn arákùnrin nínú ìjọ ni ó ṣeé ṣe fún láti tóótun fún àwọn ẹrù iṣẹ́ tí ó ga sí i. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ń dàgbà sí i nípa tẹ̀mí, tí wọ́n sì ní láti máa báa lọ láti dàgbà sí i lábẹ́ àbójútó àti ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ àwọn alàgbà ìjọ. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní láti jẹ́ ọ̀jáfáfá akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àti àwọn ìtẹ̀jáde wa. Wọ́n lè fi ìmúratán wọn hàn nípa títẹrí ba fún àwọn alàgbà tí a fi ẹ̀mí yàn, ní fífara wé ìgbàgbọ́ wọn, àti ní mímú àwọn ànímọ́ tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn alábòójútó dàgbà.—Heb. 13:7, 17.
■ Kíkó Wọnú Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún: Ìjọ ń ṣiṣẹ́ ní pàtàkì láti wàásù ìhìn rere. (Matt. 24:14) Ẹ wo ìbùkún tí ó máa ń jẹ yọ nígbà tí àwọn onítara bá fi kún ìsapá wọn nípa fíforúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà! Èyí sábà máa ń béèrè fún ṣíṣèyípadà nínú ìgbésí ayé wọn. Ó lè béèrè fún àfikún ìyípadà láti máa bá a lọ nínú apá àkànṣe iṣẹ́ ìsìn yìí. Ṣùgbọ́n àwọn tí ń bá iṣẹ́ yìí lọ, dípò jíjuwọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún mélòó kan, nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì ráńpẹ́, dájúdájú ń rí ìbùkún jìngbìnnì Jehofa. Àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ àti àwọn mìíràn tí ó dàgbà dénú lè fi kún àṣeyọrí àwọn aṣáájú ọ̀nà, ní fífún wọn níṣìírí lọ́rọ̀ àti níṣe. Ẹ wo irú ẹ̀mí àtàtà tí àwọn ọ̀dọ́ tí ó kó wọnú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà gbàrà tí wọ́n parí ẹ̀kọ́ wọn ń fi hàn! Ohun kan náà ni ó jẹ́ òtítọ́ pẹ̀lú àwọn àgbà tí ó forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà gbàrà tí àwọn ojúṣe wọn nípa ti ara dín kù díẹ̀. Ẹ wo irú ìtẹ́lọ́rùn tí Kristian tí ó ti yara rẹ̀ sí mímọ́ ń gbádùn nígbà tí ó bá tipa báyìí fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú bí Jehofa ti ń mú iṣẹ́ ìkójọ náà yára kánkán!—Isa. 60:22.
■ Ṣíṣàjọpín Nínú Kíkọ́ àti Títọ́jú Àwọn Ibi Ìpàdé: Ní ti gidi, a ti kọ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó bágbà mu, a sì ti mú ìrísí ọ̀pọ̀ Ilẹ̀ Àpéjọ sunwọ̀n sí i. Lọ́nà tí ó yani lẹ́nu, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa tí wọ́n finnúfíndọ̀ yọ̀ọ̀da àkókò àti òye iṣẹ́ wọn ni ó ṣe gbogbo iṣẹ́ náà. (1 Kron. 28:21) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ọ̀da ara ẹni ni ó ń tún àwọn ilé wọ̀nyí ṣe, nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ. (2 Kron. 34:8) Níwọ̀n bí iṣẹ́ yìí ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀, àwọn tí ń ṣèrànwọ́ ń jọ̀wọ́ ara wọn tinútinú, wọn kò béèrè pé kí a san owó fún wọn, gan-an bí wọn kò ti ní sọ pé kí a san owó fún wọn fún wíwàásù láti ilé dé ilé, fún sísọ àsọyé nínú ìjọ, tàbí fún ṣíṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ àpéjọ tàbí ti àpéjọpọ̀. Àwọn olùyọ̀ọ̀da ara ẹni wọ̀nyí ń lo òye iṣẹ́ wọn lọ́fẹ̀ẹ́, ní wíwéwèé àti kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn fún ìyìn Jehofa. Wọ́n ń hára gàgà láti ṣèrànwọ́ nínú àwọn ọ̀ràn bíi ṣíṣàkójọ àwọn ìwé ilé tí òfin béèrè fún, pípa àkọsílẹ̀ ìnáwó mọ́, ṣíṣèrànwọ́ nínú títàrírà, àti ṣíṣèṣirò àwọn ohun èlò tí a nílò. Àwọn ìránṣẹ́ Jehofa olùṣòtítọ́ wọ̀nyí kò fi kún iye owó tàbí wa ọ̀nà láti jèrè lára iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe, yálà ní tààràtà tàbí lọ́nà tí kò ṣe tààràtà, níwọ̀n bí wọ́n ti ya gbogbo tálẹ́ǹtì àti àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn sọ́tọ̀ fún Jehofa. Ìgbòkègbodò yìí ń béèrè fún àwọn òṣìṣẹ́ aláápọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ìsìn wọn ‘tọkàntọkàn bí ẹni pé fún Jehofa.’—Kol. 3:23.
15 Kí ni ohun tí ó mú kí ìmúratán àwọn ènìyàn Jehofa jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́? Ẹ̀mí fífúnni ni. Ìfúnni ọlọ́làwọ́ wọn ju owó tàbí àwọn ohun ti ara lọ—wọ́n “jọ̀wọ́ ara wọn tinútinú.” (Orin Da. 110:3) Èyí gan-an ni ìyàsímímọ́ wa sí Jehofa dá lé lórí. A ń san èrè fún wa lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. A ń ní “ayọ̀ púpọ̀” a sì ń “ká yanturu” nítorí pé àwọn ẹlòmíràn mọrírì àwọn ohun tí a ń ṣe, wọ́n sì ń san-an padà fún wa. (Ìṣe 20:35; 2 Kor. 9:6; Luku 6:38) Baba wa ọ̀run, Jehofa, ẹni tí ó “nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà,” ni Olóore wa tí ó ga jù lọ. (2 Kor. 9:7) Òun yóò san-an padà fún wa ní ìlọ́po ọgọ́rọ̀ọ̀rún, pẹ̀lú àwọn ìbùkún tí yóò wà pẹ́ títí láé. (Mal. 3:10; Romu 6:23) Nítorí náà, nígbà tí a bá ṣí àwọn àǹfààní nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa sílẹ̀ fún ọ, ìwọ yóò ha fi tinútinú yọ̀ọ̀da ara rẹ, kí o sì dáhùn bí Isaiah ti ṣe pé: “Èmi nìyí; rán mi”?—Isa. 6:8.