ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/96 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún May

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún May
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 6
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 13
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 20
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 27
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 5/96 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún May

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 6

Orin 153

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàyẹ̀wò “Ẹ̀yín Ha Kẹ́sẹ Járí ní Oṣù April Bí?”

15 min: “Jẹ́ Ẹni Tí Ń Fi Tọkàntọkàn Ṣiṣẹ́!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Bí àkókò bá ti yọ̀ǹda tó, gbé “Awọn Kókó Lati Jiroro Papọ Gẹgẹ Bi Idile Kan,” tí ó wà nínú Ile-Iṣọ Naa April 15, 1982, ojú ìwé 22, yẹ̀ wò.

20 min: “Ẹ Máa Bá Aládùúgbò Yín Sọ Òtítọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dábàá. Fún àwọn ẹni tuntun ní ìṣírí láti nípìn-ín nínú ìpínkiri ìwé ìròyìn, ní fífi àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó ṣe ṣókí bẹ̀rẹ̀. Ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì.

Orin 148 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 13

Orin 63

5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.

18 min: “A Kò Tí ì Ní Ọ̀pọ̀ Nǹkan Tẹ̀mí Tó Báyìí Rí!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Jẹ́ kí akéde méjì tàbí mẹ́ta, èyí tí ó ní ọ̀dọ́langba kan nínú, mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn ìbùkún tí wọ́n ti ní. Parí ọ̀rọ̀ rẹ nípa fífi bí ìmọrírì tí ó pọ̀ ṣe máa ń sún wa sí ìgbòkègbodò onítara nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ hàn.

22 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọrun’ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti 1996.” Ìgbéyẹ̀wò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn láti ẹnu akọ̀wé. Níbi apá náà “A Nílò Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Rẹ,” tẹnu mọ́ ọn pé àwọn ìlànà Bibeli ti àìlábòsí, ìgbọràn, ìdàníyàn onífẹ̀ẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, kan gbogbo ọ̀ràn àwọn tí ń lo ilé gbígbé tí Society ṣètò. Gbóríyìn fún àwọn tí ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò ilé gbígbé tí Society ń ṣe.

Orin 193 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 20

Orin 126

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Gbé ìṣètò ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹ̀ wò. Gba gbogbo ènìyàn níyànjú láti nípìn-ín nínú ìpínkiri ìwé ìròyìn.

15 min: “Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Sísọ Òtítọ́.” Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò, pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́. Fi àsansílẹ̀ owó lọ àwọn tí ó bá fi ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ hàn. Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn kúkurú méjì.

20 min: “Ki Ni Ó Beere fun Lati Mú Ọ Layọ?” Ọ̀rọ̀ àsọyé tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà June 1, 1993, ojú ìwé 19 sí 22.

Orin 28 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 27

Orin 121

5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.

15 min: Fífi Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun lọ Àwọn Ènìyàn ní June. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn kọ́kọ́ jíròrò ìdí tí a fi tẹ ìwé Ìmọ̀ jáde. Lẹ́yìn náà, ṣàyẹ̀wò àwọn kókó bíi mélòó kan nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn akéde ògbóṣáṣá méjì tàbí mẹ́ta. Ìwé náà dáhùn àwọn ìbéèrè nípa ọjọ́ ọ̀la, ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn, Ìjọba Ọlọrun, ìwà bí Ọlọrun, ìgbésí ayé ìdílé, àti àwọn àǹfààní àdúrà. Àwọn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú àwùjọ náà ṣàṣefihàn ìyọsíni tí a lè lò láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́, yálà nígbà ìkésíni àkọ́kọ́ tàbí nígbà ìpadàbẹ̀wò. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn jíròrò àwọn kókó tí ó tẹ̀ lé e yìí lẹ́yìn náà. Ó ṣe pàtàkì láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ó gbéṣẹ́ púpọ̀ sí i láàárín àkókò kúkúrú. A ṣe ìwé yìí ní pàtàkì fún ète yẹn. Ó gbé òtítọ́ kalẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe tààràtà, láìfọ̀rọ̀bọpobọyọ̀. Àwọn ìbéèrè tí ó wà fún ìpinrọ̀ kọ̀ọ̀kan, àti ní ìparí àkòrí kọ̀ọ̀kan, ń ràn wá lọ́wọ́ láti pọkànpọ̀ sórí àwọn kókó pàtàkì. Ìwé yìí kárí àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí a máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ẹni tuntun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìyàsímímọ́, tí wọ́n fẹ́ láti ṣe ìrìbọmi. Fún gbogbo àwùjọ ní ìṣírí láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú góńgó bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní June.

10 min: Àpótí Ìbéèrè. Kà á kí o sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ.

15 min: “Ọwọ́ Rẹ Ha Dí Jù Bí?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Bí àkókò bá ṣe yọ̀ǹda tó, fi àlàyé tí o fàyọ láti inú Jí! ti December 8, 1990, ojú ìwé 14 sí 16 kún un. Jẹ́ kí akéde kan tàbí méjì sọ ohun tí wọ́n ti ṣe láti fi àṣeyọrí kojú ìtòlẹ́sẹẹsẹ dídí fọ́fọ́ nínú ìṣàkóso Ọlọrun, ní ṣókí.

Orin 155 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́