Ẹ̀yín Ha Kẹ́sẹ Járí ní Oṣù April Bí?
Ìgbà wo ni a lè sọ pé ìjọ kan kẹ́sẹ járí? A fún gbogbo wa ní ìṣírí láti lọ́wọ́ nínú àkànṣe ìgbétáásì ìwé ìròyìn ní oṣù April àti May, ní àfikún sí ọjọ́ tí a yà sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí àkànṣe Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn ní April. Bí gbogbo àwọn akéde tí ó wà nínú ìjọ bá nípìn-ín nínú àkànṣe ìgbétáásì náà, yálà ní àkànṣe ọjọ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún ìpínkiri ìwé ìròyìn tàbí ní àwọn ọjọ́ mìíràn láàárín oṣù náà, tí wọ́n sì ròyìn ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn wọn, a lè sọ nígbà náà pé, “A kẹ́sẹ járí!” Nísinsìnyí tí April ti kọjá lọ, a ní láti ṣàyẹ̀wò bí a ti kẹ́sẹ járí tó. Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1996, ojú ìwé 5, lábẹ́ àkòrí náà, “Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ,” fún wa ní àwọn àbá 17 lórí bí a ṣe lè kẹ́sẹ járí ní April àti May.
Ṣé ìwé ìròyìn kò tó fún ìjọ yín ní oṣù April? Akéde mélòó ló lọ́wọ́ nínú àkànṣe ìgbétáásì ìwé ìròyìn ní oṣù tí ó kọjá? Ẹ̀yin yóò ha ni ìpín kíkún nínu ìgbétáásì náà ní oṣù yìí bí? A ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti pín ìwé ìròyìn—láti ilé dé ilé, ní ojú pópó, láti ìsọ̀ dé ìsọ̀, ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn, nígbà ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́, nígbà tí a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, nígbà tí a bá ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àtijọ́, nígbà tí a bá lọ rajà, nígbà tí a bá ń rìnrìn àjò, nígbà tí a bá ń bá àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ ẹni, aládùúgbò, àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni, àwọn olùkọ́ sọ̀rọ̀, nígbà tí a bá wà nínú ọkọ̀ èrò, àti nígbà tí a bá wà nínú yàra tí a ti ń dúró láti rí ẹnì kan. A lè sọ ní ti tòótọ́ pé àǹfààní láti fi àwọn ìwé ìròyìn lọ àwọn ènìyàn yí wa ká.
A gbóríyìn fún gbogbo àwọn ìjọ tí wọ́n kẹ́sẹ járí ní April, a sì fún yín ní ìṣírí láti rí i pé ẹ kẹ́sẹ járí ní May náà. Àwọn ìjọ tí wọn kò kẹ́sẹ járí ní April ńkọ́? Èé ṣe tí ẹ kò ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àbá gbígbéṣẹ́ tí ó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1996? Gbogbo aṣáájú ọ̀nà àti àwọn akéde ní láti rí i dájú pé àwọ́n ní ìwé ìròyìn tí ó pọ̀ tó láti pín kiri. A tilẹ̀ lè jẹ́ kí akéde tuntun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ní oṣù yìí kí wọ́n baà lè nípìn-ín nínú àkànṣe ìgbétáásì ìwé ìròyìn yìí.—Wo ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 97 sí 100.
Kíkó ipa jíjọjú nínú àkànṣe ìgbétáásì ìwé ìròyìn náà yóò mú kí o gbádùn ìtẹ́lọ́rùn inú lọ́hùn-ún tí ń wá láti inú ṣíṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.—Esek. 9:11; Luku 17:10.