ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/96 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 10/96 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní October: Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tàbí fún ìwé ìròyìn méjèèjì. Ìwé ìròyìn ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún ọdún kan jẹ́: ₦400. Ẹlẹ́ẹ̀kan lóṣù fún ọdún kan tàbí ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún oṣù mẹ́fà jẹ́: ₦200. November: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A óò ṣe àkànṣe ìsapá láti ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ìwé tí a fi síta, pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. December: Gẹ̀ẹ́sì—New World Translation pẹ̀lú ìwé True Peace and Security—How Can You Find It? Yorùbá—Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun. Ìfilọni àfirọ́pò: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. Àwọn èdè yòó kù—Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí Iwe Itan Bibeli Mi. Ìfilọni àfirọ́pò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. January: Ẹ́fíìkì àti Haúsá—Alafia ati Ãbò Tõtọ—Lati Orisun Wo?, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Gẹ̀ẹ́sì—Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun, The Bible—God’s Word or Man’s? Ìgbò—Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, True Peace and Security—How Can You Find It?, Yiyan Ọna Igbesi Ayé Ti O Dara Julọ. Ísókó—Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Yorùbá—Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.

◼ “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún 1997” ni àkìbọnú tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí, a sì gbọ́dọ̀ tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ fún ìtọ́kasí jálẹ̀ ọdún 1997.

◼ Society ti mú ìtẹ̀jáde Watchtower Library—1995 Edition wà lórí CD-ROM ní èdè German, Gẹ̀ẹ́sì, Italian, àti Spanish. A ṣe Watchtower Library—1995 Edition láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Windows 3.1. Bí ó ti wù kí ó rí, a ti dán an wò dáradára pẹ̀lú Windows 95 àti Windows NT 3.51, ó sì ṣiṣẹ́ dáradára pẹ̀lú ìgbékalẹ̀ ìṣiṣẹ́ ẹ̀rọ Windows mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí. A lè lò ó pẹ̀lú ìgbékalẹ̀ ìṣiṣẹ́ ẹ̀rọ OS/2, ṣùgbọ́n, a kò ní ṣe ẹ̀dà kankan fún kọ̀m̀pútà Macintosh. Ní àfikún sí Reference Bible, ẹ̀dà Gẹ̀ẹ́sì yóò ní Ilé Ìṣọ́ láti ọdún 1950 sí 1995, tí ó dọ́gba pẹ̀lú ìdìpọ̀ 46, nínú. Yóò tún ní Jí!, Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, àti àwọn ìwé, ìwé pélébé, ìwé pẹlẹbẹ, àti àwọn àṣàrò kúkúrú, láti ọdún 1970 sí 1995, nínú. Àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí i lè kọ̀wé béèrè fún un nípasẹ̀ ìjọ. Iye rẹ̀ (tí ó lè yí padà) lè jẹ́ nǹkan bíi ₦3,200. Máà tí ì fowó ránṣẹ́. A óò gbowó lọ́wọ́ rẹ nígbà tí ó bá dé. Jọ̀wọ́, kíyè sí i pé, ó di àìgbọdọ̀máṣe fún ẹni tí ń ṣe ìbéèrè náà láti san owó ohun èlò yìí ní gbàrà tí ó bá ti tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́