Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run Fún 1997
Àwọn Ìtọ́ni
Ní 1997, àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí ni yóò jẹ́ ìṣètò fún dídarí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run.
ÀWỌN ÌWÉ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́: Bíbélì, Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa [uw-YR], Ilé Ìṣọ́ [w-YR], Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun [kl-YR], àti Iwe Itan Bibeli Mi [my-YR] ni àwọn ibi tí a óò gbé iṣẹ́ àyànfúnni kà.
A gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà LÁKÒÓKÒ, pẹ̀lú orin, àdúrà, àti àwọn ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀, kí a sì tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí ó ti tẹ̀ lé e yìí:
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 1: Ìṣẹ́jú 15. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni yóò bójú tó ọ̀rọ̀ àsọyé yìí, a óò sì gbé e ka Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa tàbí Ilé Ìṣọ́. Nígbà tí a bá gbé e karí Ilé Ìṣọ́, kí a ṣe iṣẹ́ àyànfúnni yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìtọ́ni oníṣẹ̀ẹ́jú 15, láìsí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ; nígbà tí a bá gbé e karí ìwé Isopọṣọkan, kí a ṣe é gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìtọ́ni oníṣẹ̀ẹ́jú 10 sí 12, tí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ oníṣẹ̀ẹ́jú 3 sí 5 yóò sì tẹ̀ lé e, ní lílo àwọn ìbéèrè tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde náà. Ète náà kò gbọdọ̀ jẹ́ láti wulẹ̀ kárí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀, bí kò ṣe láti pa àfiyèsí pọ̀ sórí ìwúlò gbígbéṣẹ́ tí ó wà nínú ìsọfúnni tí a ń jíròrò, ní títẹnu mọ́ ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. A gbọ́dọ̀ lo ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a fi hàn. A rọ gbogbo àwọn tí a ń yan iṣẹ́ yìí fún láti múra sílẹ̀ dáradára ṣáájú, kí àwùjọ baà lè jàǹfààní kíkún rẹ́rẹ́ láti inú àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ yìí.
Àwọn arákùnrin tí a ń yan ọ̀rọ̀ àsọyé yìí fún ní láti ṣọ́ra láti má ṣe kọjá àkókò tí a fún wọn. A lè fúnni ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́ bí ó bá pọn dandan tàbí bí olùbánisọ̀rọ̀ náà bá béèrè fún un.
ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ KÍKÀ: Ìṣẹ́jú 6. Èyí ni a óò bójú tó láti ọwọ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tí yóò mú àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà bá àwọn àìní àdúgbò mu, lọ́nà tí ó gbéṣẹ́. Èyí kò ní láti jẹ́ kìkì àkópọ̀ lórí ibi tí a yàn fún kíkà. Fi ṣíṣe àtúnyẹ̀wò gbogbo orí tí a yàn fúnni mọ sí ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan. Bí ó ti wù kí ó rí, olórí ète náà ni láti ran àwùjọ lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí ìsọfúnni náà fi ṣeyebíye fún wa àti bí ó ti ṣeyebíye tó fún wa. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò yọ̀ọ̀da àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ láti lọ sí kíláàsì wọn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 2: Ìṣẹ́jú 5. Èyí jẹ́ Bíbélì kíkà lórí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a yàn fúnni, tí arákùnrin kan yóò bójú tó. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ kìíní àti ní àwọn àwùjọ yòó kù tí ó jẹ́ àfikún. Ìwé kíkà tí a yàn fúnni sábà máa ń mọ níwọ̀n láti yọ̀ọ̀da fún akẹ́kọ̀ọ́ náà láti ṣe àlàyé ṣókí ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀. A lè fi ìtàn tí ó yí àwọn ẹsẹ náà ká, ìjẹ́pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀, àti bí àwọn ìlànà rẹ̀ ṣe kàn wá kún un. A gbọ́dọ̀ ka gbogbo ẹsẹ tí a yàn fúnni pátá, láìdánu dúró lágbede méjì. Àmọ́ ṣáá o, níbi tí àwọn ẹsẹ tí a óò kà kò bá ti tẹ̀ léra, akẹ́kọ̀ọ́ náà lè sọ ẹsẹ tí kíkà náà ti ń bá a lọ.
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 3: Ìṣẹ́jú 5. Arábìnrin ni a óò yan èyí fún. A óò gbé àwọn kókó ẹ̀kọ́ iṣẹ́ yìí karí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A lè gbé e kalẹ̀ ní ọ̀nà ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, àwọn tí ń kópa sì lè jókòó tàbí dúró. Ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ náà gbà ran onílé lọ́wọ́ láti ronú lórí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà, kí ó sì lóye rẹ̀, àti bí ó ṣe lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́, ni yóò jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ. Akẹ́kọ̀ọ́ tí a yan iṣẹ́ yìí fún gbọ́dọ̀ lè kàwé. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò ṣètò fún olùrànlọ́wọ́ kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n a lè lo olùrànlọ́wọ́ mìíràn ní àfikún. Akẹ́kọ̀ọ́ náà lè pinnu bóyá òun yóò jẹ́ kí onílé ka àwọn ìpínrọ̀ kan nínú ìwé náà, tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ tí a gbà lo àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà ni ó yẹ kí a fún ní àfiyèsí pàtàkì, kì í ṣe ọ̀nà tí a gbà gbé e kalẹ̀.
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 4: Ìṣẹ́jú 5. A lè yan èyí fún arákùnrin tàbí arábìnrin. A óò gbé e karí Iwe Itan Bibeli Mi. Nígbà tí a bá yàn án fún arákùnrin, èyí gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo àwùjọ pátá. Ó sábà máa ń dára jù lọ fún arákùnrin náà láti múra ọ̀rọ̀ àsọyé rẹ̀ sílẹ̀ ní níní àwùjọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́kàn, kí ó baà lè kún fún ẹ̀kọ́ ní tòótọ́, kí ó sì ṣe àwọn tí ń gbọ́ ọ láǹfààní ní ti gidi. Nígbà tí a bá yan apá yìí fún arábìnrin, kí ó gbé àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti lànà rẹ̀ sílẹ̀ fún Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 3.
ÌMỌ̀RÀN ÀTI ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ ÀKÍYÈSÍ: Lẹ́yìn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò fún wọn ní ìmọ̀ràn pàtó, kò pọn dandan pé kí ó tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìmọ̀ràn ìtẹ̀síwájú tí a tò sínú ìwé Imọran Ọrọ Sisọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn agbègbè tí ó yẹ fún akẹ́kọ̀ọ́ náà láti túbọ̀ múra sí. Bí ó bá jẹ́ “D” nìkan ni ó tọ́ sí akẹ́kọ̀ọ́ náà, tí kò sì sí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ mìíràn tí a kọ “S” tàbí “Ṣ” sí, nígbà náà, olùgbaninímọ̀ràn ní láti yí àmì róbótó yípo àpótí, níbi tí a máa ń kọ “D,” “S” tàbí “Ṣ” sí, tí ó wà níwájú ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò ṣiṣẹ́ lé lórí tẹ̀ lé e. Òun yóò fi èyí tó akẹ́kọ̀ọ́ náà létí ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, yóò sì tún kọ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ yìí sórí ìwé Iṣẹ́-Àyànfúnni Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun (S-89-YR) tí akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò gbà tẹ̀ lé e. Àwọn tí ó níṣẹ́ ní láti jókòó ní apá iwájú gbọ̀ngàn náà. Èyí kì yóò jẹ́ kí a fi àkókò ṣòfò, yóò sì mú kí ó ṣeé ṣe fún alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ láti fún akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan nímọ̀ràn ní tààràtà. Bí àkókò bá ṣe yọ̀ọ̀da sí, lẹ́yìn fífúnni ní ìmọ̀ràn aláfẹnusọ tí ó pọn dandan, olùgbaninímọ̀ràn lè sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó tí ó kún fún ẹ̀kọ́ tí ó sì gbéṣẹ́, tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kò mẹ́nu kàn. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ kò gbọdọ̀ lò ju ìṣẹ́jú méjì lọ fún ìmọ̀ràn àti àwọn ọ̀rọ̀ àkíyèsí ṣókí èyíkéyìí mìíràn, lẹ́yìn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan. Bí arákùnrin tí ó bójú tó àwọn kókó pàtàkì láti inú Bíbélì bá nílò ìmọ̀ràn, a lè fún un ní ìmọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́.
MÍMÚRA ÀWỌN IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI SÍLẸ̀: Ṣáájú mímúra iṣẹ́ tí a yàn fún un sílẹ̀, akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ka àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ inú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ tí ó sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí ó fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí a fún ní Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 2 lè yan ẹṣin ọ̀rọ̀ kan tí ó bá apá ibi tí wọ́n fẹ́ kà nínú Bíbélì mu. Àwọn iṣẹ́ àyànfúnni yòó kù ni a óò sọ ní ìbámu pẹ̀lú ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a fi hàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a tẹ̀.
ÌDÍWỌ̀N ÀKÓKÒ: Kò sí ẹni tí ó gbọ́dọ̀ lò kọjá àkókò, bẹ́ẹ̀ sì ni ìmọ̀ràn àti àwọn ọ̀rọ̀ àkíyèsí olùgbaninímọ̀ràn kò gbọdọ̀ kọjá àkókò. A ní láti fi ọgbọ́n dá Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 2 títí dé 4 dúró nígbà tí àkókò bá tó. Ẹni tí a yàn láti fúnni ní àmì ìdáṣẹ́dúró ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní kánmọ́. Nígbà tí àwọn arákùnrin tí ń bójú tó Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 1 àti àwọn kókó pàtàkì láti inú Bíbélì bá kọjá àkókò, a ní láti fún wọn ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́. Àròpọ̀ àkókò ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ́: ìṣẹ́jú 45, láìní orin àti àdúrà nínú.
ÀTÚNYẸ̀WÒ ALÁKỌSÍLẸ̀: A óò máa ṣe àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, látìgbàdégbà. Bí o bá ń múra sílẹ̀, ṣàtúnyẹ̀wò àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a yàn, kí o sì parí Bíbélì kíkà tí a là lẹ́sẹẹsẹ. Bíbélì nìkan ni a lè lò lákòókò àtúnyẹ̀wò oníṣẹ̀ẹ́jú 25 yìí. A óò lo ìyókù àkókò náà fún jíjíròrò àwọn ìbéèrè àti ìdáhùn. Akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan yóò máàkì ìwé tirẹ̀. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò ṣàyẹ̀wò ìdáhùn àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò náà pẹ̀lú àwùjọ, yóò sì pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìbéèrè tí ó nira jù lọ, ní ríran gbogbo àwùjọ lọ́wọ́ láti lóye ìdáhùn náà dáradára. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn àyíká ipò àdúgbò mú kí ó pọn dandan, a lè ṣe àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀ náà ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn àkókò tí a fi hàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ.
ÀWỌN ÌJỌ ŃLÁ: Àwọn ìjọ tí ó ní iye akẹ́kọ̀ọ́ tí ó tó 50 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí ó forúkọ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́, lè fẹ́ láti ṣètò fún àfikún àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe iṣẹ́ àyànfúnni wọn níwájú àwọn olùgbaninímọ̀ràn míràn. Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, àwọn tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi, tí ìgbésí ayé wọn wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Kristẹni, lè forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú ní ilé ẹ̀kọ́, kí a sì fún wọn níṣẹ́.
ÀWỌN TÍ KÒ WÁ: Gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìjọ lè fi ìmọrírì hàn fún ilé ẹ̀kọ́ yìí, nípa sísapá láti máa wà níbẹ̀ ní gbogbo àkókò ìjókòó ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, nípa mímúra iṣẹ́ àyànfúnni wọn sílẹ̀ dáradára, àti nípa kíkópa nínú àwọn apá tí ó ní ìbéèrè nínú. A retí pé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò jẹ́ kí iṣẹ́ àyànfúnni wọn jẹ wọ́n lọ́kàn. Bí akẹ́kọ̀ọ́ kan kò bá wá nígbà tí a ṣètò rẹ̀ sí, olùyọ̀ǹda ara ẹni kan lè gba iṣẹ́ náà ṣe, ní ṣíṣe àmúlò kókó èyíkéyìí tí ó rò pé òún tóótun láti lò láàárín irú àkókò ìfitónilétí kúkúrú bẹ́ẹ̀. Tàbí kẹ̀, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lè kárí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìlọ́wọ́sí yíyẹ láti ọ̀dọ̀ àwùjọ.
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ
Jan. 6 Bíbélì kíkà: Sekaráyà 1 sí 5
Orin 85
No. 1: w89-YR 6/15 ojú ìwé 30 àti 31 (láìfi àpótí kún un)
No. 2: Sekaráyà 2:1-13
No. 3: A Kò Dá Ènìyàn Láti Kú (kl-YR ojú ìwé 53 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 4: Rutu ati Naomi (my-YR ìtàn 51)
Jan. 13 Bíbélì kíkà: Sekaráyà 6 sí 9
Orin 215
No. 1: Jésù Ní Kọ́kọ́rọ́ Ikú àti ti Hédíìsì (uw-YR ojú ìwé 73 sí 77 ìpínrọ̀ 8 sí 15)
No. 2: Sekaráyà 7:1-14
No. 3: Ìdìmọ̀lù Ibi Kan (kl-YR ojú ìwé 55 àti 56 ìpínrọ̀ 4 sí 7)
No. 4: Gideoni ati 300 Eniyan Rẹ̀ (my-YR ìtàn 52)
Jan. 20 Bíbélì kíkà: Sekaráyà 10 sí 14
Orin 98
No. 1: w89-YR 6/15 ojú ìwé 31 (àpótí)
No. 2: Sekaráyà 12:1-14
No. 3: Bí Sátánì Ṣe Di Rìkíṣí Rẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 56 sí 58 ìpínrọ̀ 8 sí 12)
No. 4: Ileri Jefta (my-YR ìtàn 53)
Jan. 27 Bíbélì kíkà: Málákì 1 sí 4
Orin 118
No. 1: w89-YR 7/1 ojú ìwé 30 àti 31
No. 2: Málákì 1:6-14
No. 3: Bí Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú Ṣe Gbilẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 58 àti 59 ìpínrọ̀ 13 sí 15)
No. 4: Ọkunrin Alagbara Julọ (my–YR ìtàn 54)
Feb. 3 Bíbélì kíkà: Mátíù 1 sí 3
Orin 132
No. 1: w89-YR 7/15 ojú ìwé 24 àti 25 ìpínrọ̀ 1
No. 2: Mátíù 2:1-15
No. 3: Ṣọ́ra fún Àwọn Ọgbọ́n Ẹ̀wẹ́ Sátánì (kl-YR ojú ìwé 59 àti 60 ìpínrọ̀ 16 sí 18)
No. 4: Ọdọmọkunrin Kan Sìn Ọlọrun (my-YR ìtàn 55)
Feb. 10 Bíbélì kíkà: Mátíù 4 àti 5
Orin 36
No. 1: Mọrírì Ìjọba Wíwà Pẹ́ Títí ti Ọlọ́run (uw-YR ojú ìwé 78 sí 81 ìpínrọ̀ 1 sí 9)
No. 2: Mátíù 4:1-17
No. 3: Ní Ìgbàgbọ́, Kí O Sì Múra Sílẹ̀ fún Àtakò (kl-YR ojú ìwé 60 àti 61 ìpínrọ̀ 19 sí 21)
No. 4: Saulu—Ọba Kinni ní Israeli (my–YR ìtàn 56)
Feb. 17 Bíbélì kíkà: Mátíù 6 àti 7
Orin 222
No. 1: Ohun tí Ìjọba Ọlọ́run Yóò Ṣàṣeparí (uw-YR ojú ìwé 81 àti 82 ìpínrọ̀ 10 sí 12)
No. 2: Mátíù 7:1-14
No. 3: Ọ̀nà Ọlọ́run Láti Gba Aráyé Là (kl-YR ojú ìwé 62 àti 63 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: Ọlọrun Yàn Dafidi (my-YR ìtàn 57)
Feb. 24 Bíbélì kíkà: Mátíù 8 àti 9
Orin 162
No. 1: Ohun tí Ìjọba Náà Ti Ṣàṣeparí (uw-YR ojú ìwé 83 sí 86 ìpínrọ̀ 13 sí 15)
No. 2: Mátíù 8:1-17
No. 3: Ìdí Tí Messia Yóò Fi Kú (kl-YR ojú ìwé 63 sí 65 ìpínrọ̀ 6 sí 11)
No. 4: Dafidi ati Goliati (my-YR ìtàn 58)
March 3 Bíbélì kíkà: Mátíù 10 àti 11
Orin 172
No. 1: Bí A Ti Ń Wá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́ (uw-YR ojú ìwé 87 sí 89 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 2: Mátíù 11:1-15
No. 3: Bí A Ṣe San Ìràpadà Náà (kl-YR ojú ìwé 65 sí 68 ìpínrọ̀ 12 sí 16)
No. 4: Idi ti Dafidi Fi Gbọdọ Salọ (my-YR ìtàn 59)
Mar. 10 Bíbélì kíkà: Mátíù 12 àti 13
Orin 133
No. 1: Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ (uw-YR ojú ìwé 90 àti 91 ìpínrọ̀ 7 sí 9)
No. 2: Mátíù 12:22-37
No. 3: Ìwọ àti Ìràpadà Kristi (kl-YR ojú ìwé 68 àti 69 ìpínrọ̀ 17 sí 20)
No. 4: Abigaili ati Dafidi (my-YR ìtàn 60)
Mar. 17 Bíbélì kíkà: Mátíù 14 àti 15
Orin 129
No. 1: Fi Ìjọba Náà Ṣe Àkọ́kọ́ Nínú Ìgbésí Ayé Rẹ (uw-YR ojú ìwé 91 sí 94 ìpínrọ̀ 10 sí 15)
No. 2: Mátíù 14:1-22
No. 3: Ọlọ́run Ha Ni Ó Fa Ìjìyà Ẹ̀dá Ènìyàn Bí? (kl-YR ojú ìwé 70 àti 71 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: A Fi Dafidi Jọba (my-YR ìtàn 61)
Mar. 24 Bíbélì kíkà: Mátíù 16 àti 17
Orin 151
No. 1: Ohun Tí Ìwé Mímọ́ Sọ Nípa Batisí Tí Jòhánù Ṣe (uw-YR ojú ìwé 95 àti 96 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 2: Mátíù 17:14-27
No. 3: Ìbẹ̀rẹ̀ Pípé Kan àti Ìpèníjà Onínú-Burúkú (kl-YR ojú ìwé 72 àti 73 ìpínrọ̀ 6 sí 10)
No. 4: Wahala Ninu Ile Dafidi (my-YR ìtàn 62)
Mar. 31 Bíbélì kíkà: Mátíù 18 àti 19
Orin 97
No. 1: Kí Ni Batisí Sínú Ikú? (uw-YR ojú ìwé 97 àti 98 ìpínrọ̀ 6 sí 8)
No. 2: Mátíù 19:16-30
No. 3: Àwọn Ọ̀ràn Àríyànjiyàn Náà Gan-an àti Ọ̀nà Tí Jèhófà Yóò Gbà Yanjú Wọn (kl-YR ojú ìwé 74 sí 76 ìpínrọ̀ 11 sí 15)
No. 4: Ọlọgbọn Ọba Solomoni (my-YR ìtàn 63)
Apr. 7 Bíbélì kíkà: Mátíù 20 àti 21
Orin 107
No. 1: Kí Ni Ó Túmọ̀ Sí Láti Batisí “ní Orúkọ Baba àti Ti Ọmọkùnrin àti Ti Ẹ̀mí Mímọ́”? (uw-YR ojú ìwé 98 ìpínrọ̀ 9)
No. 2: Mátíù 20:1-16
No. 3: Ohun Tí Fífi Tí Ọlọ́run Fàyè Gba Ìwà Búburú Ti Fi Ẹ̀rí Rẹ̀ Hàn (kl-YR ojú ìwé 76 àti 77 ìpínrọ̀ 16 sí 19)
No. 4: Solomoni Kọ́ Tempili Naa (my-YR ìtàn 64)
Apr. 14 Bíbélì kíkà: Mátíù 22 àti 23
Orin 56
No. 1: Gbígbé Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìtumọ̀ Batisí Wa (uw-YR ojú ìwé 99 sí 102 ìpínrọ̀ 10 sí 14)
No. 2: Mátíù 23:1-15
No. 3: Ìhà Ọ̀dọ Ta Ni O Dúró Sí? (kl-YR ojú ìwé 78 àti 79 ìpínrọ̀ 20 sí 23)
No. 4: A Pín Ijọba Naa (my-YR ìtàn 65)
Apr. 21 Bíbélì kíkà: Mátíù 24 àti 25
Orin 193
No. 1: Dídá Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Mọ̀ Yàtọ̀ (uw-YR ojú ìwé 103 àti 104 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 2: Mátíù 24:32-44
No. 3: Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ Sí Àwọn Olólùfẹ́ Wa Tí Wọ́n Ti Kú? (kl-YR ojú ìwé 80 àti 81 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 4: Jesebeli—Ayaba Buburu (my-YR ìtàn 66)
Apr. 28 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Sekaráyà 1 sí Mátíù 25
Orin 6
May 5 Bíbélì kíkà: Mátíù 26
Orin 14
No. 1: Kí Ní Ń Béèrè Láti La Ìpọ́njú Ńlá Já? (uw-YR ojú ìwé 105 ìpínrọ̀ 5)
No. 2: Mátíù 26:31-35, 69-75
No. 3: Ohun Tí Pípadà Di Erùpẹ̀ Túmọ̀ Sí Ní Ti Gidi (kl-YR ojú ìwé 82 àti 83 ìpínrọ̀ 7 sí 10)
No. 4: Jehoṣafati Gbẹkẹle Jehofah (my-YR ìtàn 67)
May 12 Bíbélì kíkà: Mátíù 27 àti 28
Orin 102
No. 1: w89-YR 7/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2 sí 6
No. 2: Mátíù 27:11-26
No. 3: Ipò Wo Ni Àwọn Òkú Wà? (kl-YR ojú ìwé 83 àti 84 ìpínrọ̀ 11 sí 14)
No. 4: Awọn Ọmọkunrin Meji Ti O Tún Wà Láàyè (my-YR ìtàn 68)
May 19 Bíbélì kíkà: Máàkù 1 àti 2
Orin 180
No. 1: w89-YR 10/15 ojú ìwé 30
No. 2: Máàkù 1:12-28
No. 3: Gbogbo Àwọn Tí Ó Wà ní Ìrántí Jèhófà Ni A Óò Jí Dìde (kl-YR ojú ìwé 85 sí 87 ìpínrọ̀ 15 sí 18)
No. 4: Ọdọmọbinrin Kan Ràn Ọkunrin Alagbara Kan Lọwọ (my-YR ìtàn 69)
May 26 Bíbélì kíkà: Máàkù 3 àti 4
Orin 46
No. 1: Ìdí Tí Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Fi La Ìpọ́njú Ńlá Já (uw-YR ojú ìwé 106 àti 107 ìpínrọ̀ 6 sí 8)
No. 2: Máàkù 3:1-15
No. 3: Àjíǹde Sí Ibo? (kl-YR ojú ìwé 88 àti 89 ìpínrọ̀ 19 sí 22)
No. 4: Jona ati Ẹja Nla Naa (my-YR ìtàn 70)
June 2 Bíbélì kíkà: Máàkù 5 àti 6
Orin 220
No. 1: Ìdí Tí A Fi Ka Párádísè Tẹ̀mí Tí A Ní Sí Iyebíye (uw-YR ojú ìwé 107 sí 109 ìpínrọ̀ 9 sí 13)
No. 2: Máàkù 5:21-24, 35-43
No. 3: Ìjọba Ọlọ́run àti Ète Rẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 90 àti 91 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: Ọlọrun Ṣeleri Paradise Kan (my-YR ìtàn 71)
June 9 Bíbélì kíkà: Máàkù 7 àti 8
Orin 207
No. 1: Èé Ṣe Tí Àwọn Àjògún Ìjọba Fi Kéré Níye Tó Bẹ́ẹ̀ Lórí Ilẹ̀ Ayé Lónìí? (uw-YR ojú ìwé 110 sí 112 ìpínrọ̀ 1 sí 7)
No. 2: Máàkù 7:24-37
No. 3: Ìjọba Ọlọ́run Jẹ́ Àkóso Kan (kl-YR ojú ìwé 91 àti 92 ìpínrọ̀ 6 àti 7)
No. 4: Ọlọrun Ran Hesekiah Ọba Lọwọ (my-YR ìtàn 72)
June 16 Bíbélì kíkà: Máàkù 9 àti 10
Orin 11
No. 1: Àwọn Ọmọkùnrin Tẹ̀mí—Báwo Ni Wọ́n Ṣe Mọ̀? (uw-YR ojú ìwé 112 àti 113 ìpínrọ̀ 8 sí 10)
No. 2: Máàkù 9:14-29
No. 3: Bí A Ṣe Mọ̀ Pé Ìjọba Ọlọ́run Jẹ́ Gidi (kl-YR ojú ìwé 92 àti 93 ìpínrọ̀ 8 sí 11)
No. 4: Ọba Rere Ikẹhin ní Israeli (my-YR ìtàn 73)
June 23 Bíbélì kíkà: Máàkù 11 àti 12
Orin 87
No. 1: Kí Ni Ìjẹ́pàtàkì Ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí? (uw-YR ojú ìwé 114 sí 116 ìpínrọ̀ 11 sí 14)
No. 2: Máàkù 11:12-25
No. 3: Ìdí Tí Ìjọba Ọlọ́run Fi Jẹ́ Ìrètí Kan Ṣoṣo Tí Aráyé Ní (kl-YR ojú ìwé 94 àti 95 ìpínrọ̀ 12 àti 13)
No. 4: Ọkunrin Kan Ti Kò Bẹ̀rù (my-YR ìtàn 74)
June 30 Bíbélì kíkà: Máàkù 13 àti 14
Orin 38
No. 1: Dídá Ètò Àjọ Tí Ó Ṣeé Fojú Rí Ti Jèhófà Mọ̀ Yàtọ̀ (uw-YR ojú ìwé 117 àti 118 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 2: Máàkù 14:12-26
No. 3: Ìdí Tí Jésù Kò Fi Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣàkóso Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ Lẹ́yìn Ìgòkè Re Ọ̀run Rẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 95 àti 96 ìpínrọ̀ 14 àti 15)
No. 4: Ọmọkunrin Mẹrin ní Babiloni (my-YR ìtàn 75)
July 7 Bíbélì kíkà: Máàkù 15 àti16
Orin 187
No. 1: w89-YR 10/15 ojú ìwé 31
No. 2: Máàkù 15:16-32
No. 3: Nígbà Wo Ni Àkókò Tí A Yàn Kalẹ̀ fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè Bẹ̀rẹ̀ Tí Ó Sì Parí? (kl-YR ojú ìwé 96 àti 97 ìpínrọ̀ 16 sí 18)
No. 4: A Pa Jerusalemu Run (my-YR ìtàn 76)
July 14 Bíbélì kíkà: Lúùkù 1
Orin 212
No. 1: w89-YR 11/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 1 sí 8
No. 2: Lúùkù 1:5-17
No. 3: Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Nìwọ̀nyí (kl-YR ojú ìwé 98 àti 99 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 4: Wọn Kò Jẹ Tẹriba (my-YR ìtàn 77)
July 21 Bíbélì kíkà: Lúùkù 2 àti 3
Orin 89
No. 1: Ètò Àjọ Ọlọ́run Jẹ́ Ìṣàkóso Àtọ̀runwá (uw-YR ojú ìwé 118 sí 120 ìpínrọ̀ 4 sí 7)
No. 2: Lúùkù 2:1-14
No. 3: Kí Ni Díẹ̀ Lára Àwọn Apá Ẹ̀ka Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn? (kl-YR ojú ìwé 99 sí 103 ìpínrọ̀ 5 sí 7)
No. 4: Ìkọ̀wé Lara Ogiri (my-YR ìtàn 78)
July 28 Bíbélì kíkà: Lúùkù 4 àti 5
Orin 92
No. 1: Ipa Iṣẹ́ Tí Ìwé Mímọ́ Fi Lélẹ̀ fún Àwọn Tí Ń Mú Ipò Iwájú (uw-YR ojú ìwé 120 sí 122 ìpínrọ̀ 8 sí 12)
No. 2: Lúùkù 4:31-44
No. 3: Àwọn Ìwà Ìbàjẹ́ Tí A Sọ Tẹ́lẹ̀ Pé Yóò Sàmì Sí Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn (kl-YR ojú ìwé 103 àti 104 ìpínrọ̀ 8 sí 12)
No. 4: Danieli Ninu Iho Kiniun (my-YR ìtàn 79)
Aug. 4 Bíbélì kíkà: Lúùkù 6 àti 7
Orin 213
No. 1: Ṣíṣe Ìfọ́síwẹ́wẹ́ Ìmọrírì Wa fún Ètò Àjọ Ọlọ́run (uw-YR ojú ìwé 123 àti 124 ìpínrọ̀ 13 àti 14)
No. 2: Lúùkù 6:37-49
No. 3: Apá Ẹ̀ka Ṣíṣàrà-Ọ̀tọ̀ Méjì Ti Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn (kl-YR ojú ìwé 105 ìpínrọ̀ 13 àti 14)
No. 4: Awọn Eniyan Ọlọrun Fi Babiloni Silẹ (my-YR ìtàn 80)
Aug. 11 Bíbélì kíkà: Lúùkù 8 àti 9
Orin 67
No. 1: Èé Ṣe Tí A Fi Gbọ́dọ̀ Fetí Sí Ìmọ̀ràn? (uw-YR ojú ìwé 125 sí 127 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 2: Lúùkù 9:23-36
No. 3: Dáhùn Padà Sí Ẹ̀rí Náà Pé Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Nìwọ̀nyí (kl-YR ojú ìwé 106 àti 107 ìpínrọ̀ 15 sí 17)
No. 4: Gbigbẹkẹle Iranlọwọ Ọlọrun (my-YR ìtàn 81)
Aug. 18 Bíbélì kíkà: Lúùkù 10 àti 11
Orin 34
No. 1: Àpẹẹrẹ Àtàtà ti Àwọn Tí Ó Tẹ́wọ́ Gba Ìmọ̀ràn (uw-YR ojú ìwé 127 àti 128 ìpínrọ̀ 5 àti 6)
No. 2: Lúùkù 11:37-51
No. 3: Àwọn Ẹ̀mí Burúkú Ń Bẹ Ní Ti Gidi! (kl-YR ojú ìwé 108 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 4: Mordekai ati Esteri (my-YR ìtàn 82)
Aug. 25 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Mátíù 26 sí Lúùkù 11
Orin 160
Sept. 1 Bíbélì kíkà: Lúùkù 12 àti 13
Orin 163
No. 1: Mú Àwọn Ànímọ́ Tí Kò Ṣeé Díye Lé Dàgbà (uw-YR ojú ìwé 128 sí 130 ìpínrọ̀ 7 sí 11)
No. 2: Lúùkù 13:1-17
No. 3: Àwọn Áńgẹ́lì Burúkú Gbè Sẹ́yìn Sátánì (kl-YR ojú ìwé 109 ìpínrọ̀ 4 àti 5)
No. 4: Awọn Odi Jerusalemu (my-YR ìtàn 83)
Sept. 8 Bíbélì kíkà: Lúùkù 14 sí 16
Orin 124
No. 1: Má Ṣe Kọ Ìbáwí Jèhófà Sílẹ̀ (uw-YR ojú ìwé 130 àti 131 ìpínrọ̀ 12 sí 14)
No. 2: Lúùkù 14:1-14
No. 3: Kọ Gbogbo Onírúurú Ìbẹ́mìílò Sílẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 111 ìpínrọ̀ 6 sí 8)
No. 4: Angẹli Kan Bẹ̀ Maria Wò (my-YR ìtàn 84)
Sept. 15 Bíbélì kíkà: Lúùkù 17 àti 18
Orin 200
No. 1: Ìfẹ́ Ń Fi Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Hàn Yàtọ̀ (uw-YR ojú ìwé 132 àti 133 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 2: Lúùkù 17:22-37
No. 3: Ìdí Tí Bíbélì Fi Dá Ìbẹ́mìílò Lẹ́bi (kl-YR ojú ìwé 112 àti 113 ìpínrọ̀ 9 sí 11)
No. 4: A Bí Jesu ní Ibùso Ẹran (my-YR ìtàn 85)
Sept. 22 Bíbélì kíkà: Lúùkù 19 àti 20
Orin 145
No. 1: Ohun Tí Ó Yẹ Kí A Ṣe Nígbà Tí Ìṣòro Bá Yọjú (uw-YR ojú ìwé 134 ìpínrọ̀ 6 sí 9)
No. 2: Lúùkù 19:11-27
No. 3: Bíbélì Ṣí Bí Àwọn Ẹ̀mí Burúkú Ṣe Ń Ṣiṣẹ́ Payá (kl-YR ojú ìwé 113 àti 114 ìpínrọ̀ 12 àti 13)
No. 4: Ìràwọ̀ Kan Darí Awọn Eniyan (my-YR ìtàn 86)
Sept. 29 Bíbélì kíkà: Lúùkù 21 àti 22
Orin 86
No. 1: Ẹ Yanjú Ìṣòro Lọ́nà Tí Ó Bá Ìwé Mímọ́ Mu (uw-YR ojú ìwé 135 àti 136 ìpínrọ̀ 10 sí 13)
No. 2: Lúùkù 22:24-38
No. 3: Bí A Ṣe Lè Dènà Àwọn Ẹ̀mí Burúkú (kl-YR ojú ìwé 114 àti 115 ìpínrọ̀ 14 àti 15)
No. 4: Jesu Ọdọmọde Ninu Tempili (my-YR ìtàn 87)
Oct. 6 Bíbélì kíkà: Lúùkù 23 àti 24
Orin 88
No. 1: w89-YR 11/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 9 sí 25
No. 2: Lúùkù 23:32-49
No. 3: Bí O Ṣe Lè fún Ìgbàgbọ́ Rẹ Lókun (kl-YR ojú ìwé 115 àti 116 ìpínrọ̀ 16 àti 17)
No. 4: Johannu Baptisi Jesu (my-YR ìtàn 88)
Oct. 13 Bíbélì kíkà: Jòhánù 1 sí 3
Orin 31
No. 1: w90-YR 3/15 ojú ìwé 24 àti 25 ìpínrọ̀ 1
No. 2: Jòhánù 1:19-34
No. 3: Tẹra Mọ́ Ìjà Rẹ Lòdì Sí Àwọn Ẹ̀mí Burúkú (kl-YR ojú ìwé 116 àti 117 ìpínrọ̀ 18 sí 20)
No. 4: Jesu Fọ Tempili Mọ́ (my-YR ìtàn 89)
Oct. 20 Bíbélì kíkà: Jòhánù 4 àti 5
Orin 35
No. 1: Wá Ọ̀nà Láti “Gbòòrò Síwájú” Nínú Ìfẹ́ (uw-YR ojú ìwé 137 àti 138 ìpínrọ̀ 14 sí 17)
No. 2: Jòhánù 4:39-54
No. 3: Gbígbé Ìgbésí Ayé Ìwà-Bí-Ọlọ́run Ń Mú Ayọ̀ Wá (kl-YR ojú ìwé 118 àti 119 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 4: Pẹlu Obinrin Kan Lẹbàá Kànga (my-YR ìtàn 90)
Oct. 27 Bíbélì kíkà: Jòhánù 6 àti7
Orin 150
No. 1: Sọ Ìfọkànsìn Oníwà-Bí-Ọlọ́run Dàṣà Nínú Ilé (uw-YR ojú ìwé 139 ìpínrọ̀ 1 àti 2)
No. 2: Jòhánù 6:52-71
No. 3: Àìlábòsí Ń Yọrí Sí Ayọ̀ (kl-YR ojú ìwé 119 àti 120 ìpínrọ̀ 5 àti 6)
No. 4: Jesu Kọ́ni Lori Òkè (my-YR ìtàn 91)
Nov. 3 Bíbélì kíkà: Jòhánù 8 àti9
Orin 48
No. 1: Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó, Ìkọ̀sílẹ̀, àti Ìpínyà (uw-YR ojú ìwé 140 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Jòhánù 9:18-34
No. 3: Ìwà Ọ̀làwọ́ Ń Mú Ayọ̀ Wá (kl-YR ojú ìwé 120 ìpínrọ̀ 7 àti 8)
No. 4: Jesu Jí Okú Dide (my-YR ìtàn 92)
Nov. 10 Bíbélì kíkà: Jòhánù 10 àti 11
Orin 117
No. 1: Àwọn Kókó Pàtàkì Nínú Ìgbéyàwó Tí Ó Ṣàṣeyọrí sí Rere (uw-YR ojú ìwé 140 àti 141 ìpínrọ̀ 4 àti 5)
No. 2: Jòhánù 10:22-39
No. 3: Pa Agbára Ìrònú Rẹ Mọ́ Kí O Sì Yẹra fún Ibi (kl-YR ojú ìwé 121 ìpínrọ̀ 9 àti 10)
No. 4: Jesu Bọ́ Ọpọlọpọ Eniyan (my-YR ìtàn 93)
Nov. 17 Bíbélì kíkà: Jòhánù 12 àti 13
Orin 158
No. 1: Mú Ipa Iṣẹ́ Rẹ Ṣe Nínú Ìṣètò Ìdílé Tí Ọlọ́run Dá Sílẹ̀ (uw-YR ojú ìwé 142 àti 143 ìpínrọ̀ 6 sí 10)
No. 2: Jòhánù 12:1-16
No. 3: Jíjẹ́ Olóòótọ́ sí Ẹnì Kejì Ẹni Ń Mú Ayọ̀ Wá Nínú Ìgbéyàwó (kl-YR ojú ìwé 122 àti 123 ìpínrọ̀ 11 sí 13)
No. 4: Ó Fẹran Awọn Ọmọde (my-YR ìtàn 94)
Nov. 24 Bíbélì kíkà: Jòhánù 14 sí 16
Orin 63
No. 1: Jẹ́ Kí Bíbélì Jẹ́ Orísun Ìmọ̀ràn Rẹ (uw-YR ojú ìwé 144 ìpínrọ̀ 11 sí 13)
No. 2: Jòhánù 16:1-16
No. 3: Máà Jẹ́ Apá Kan Ayé (kl-YR ojú ìwé 123 sí 125 ìpínrọ̀ 14 àti 15)
No. 4: Ọna Ti Jesu Gbà Nkọ́ni (my-YR ìtàn 95)
Dec. 1 Bíbélì kíkà: Jòhánù 17 àti 18
Orin 114
No. 1: Ìdí Tí A Fi Lọ́kàn Ìfẹ́ Nínú Òfin Mósè (uw-YR ojú ìwé 146 àti 147 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 2: Jòhánù 18:1-14
No. 3: Ìdí Tí Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kò Fi Ń Ṣe Àṣeyẹ Kérésìmesì Tàbí Ti Ọjọ́ Ìbí (kl-YR ojú ìwé 126 ìpínrọ̀ 16 àti 17)
No. 4: Jesu Wò Aláìsàn Sàn (my-YR ìtàn 96)
Dec. 8 Bíbélì kíkà: Jòhánù 19 sí 21
Orin 138
No. 1: w90-YR 3/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2 sí 7
No. 2: Jòhánù 19:25-37
No. 3: Ẹ Máa Bá A Lọ Láti Ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa (kl-YR ojú ìwé 127 ìpínrọ̀ 18)
No. 4: Jesu Dé Gẹgẹ Bi Ọba (my-YR ìtàn 97)
Dec. 15 Bíbélì kíkà: Ìṣe 1 sí 3
Orin 41
No. 1: w90-YR 5/15 ojú ìwé 24 sí 26 ìpínrọ̀ 1 (láìfi àpótí kún un)
No. 2: Ìṣe 1:1-14
No. 3: Bí Àwọn Ìlànà Bíbélì Ṣe Kan Iṣẹ́ àti Eré Ìnàjú (kl-YR ojú ìwé 127 àti 128 ìpínrọ̀ 19 àti 20)
No. 4: Lori Òkè Olifi (my-YR ìtàn 98)
Dec. 22 Bíbélì kíkà: Ìṣe 4 sí 6
Orin 113
No. 1: Àwọn Ìdí Tí Ó Bá Ìwé Mímọ́ Mu Pé A Kò Sí Lábẹ́ Òfin Mósè (uw-YR ojú ìwé 147 àti 148 ìpínrọ̀ 5 àti 6)
No. 2: Ìṣe 5:27-42
No. 3: Fi Ọ̀wọ̀ Hàn fún Ìwàláàyè àti Ẹ̀jẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 128 àti 129 ìpínrọ̀ 21 sí 23)
No. 4: Ninu Iyàrá Kan Lókè Pẹtẹẹsi (my-YR ìtàn 99)
Dec. 29 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Lúùkù 12 sí Ìṣe 6
Orin 144