Sekaráyà
1 Ní oṣù kẹjọ, ọdún kejì ìjọba Dáríúsì,+ Jèhófà sọ fún wòlíì Sekaráyà*+ ọmọ Berekáyà ọmọ Ídò pé: 2 “Jèhófà bínú gan-an sí àwọn baba yín.+
3 “Sọ fún àwọn èèyàn yìí pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “‘Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, ‘èmi yóò sì pa dà sọ́dọ̀ yín,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”’
4 “‘Ẹ má dà bí àwọn baba yín, tí àwọn wòlíì àtijọ́ kéde fún pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fi ìwà búburú yín sílẹ̀* kí ẹ sì jáwọ́ nínú iṣẹ́ ibi.’”’+
“‘Àmọ́ wọn ò gbọ́, wọn ò sì fetí sí ohun tí mo sọ,’+ ni Jèhófà wí.
5 “‘Ibo wá ni àwọn baba yín wà báyìí? Àwọn wòlíì yẹn ńkọ́, ṣé wọ́n wà títí láé? 6 Àmọ́ ohun tí mo sọ àti àṣẹ tí mo pa fún àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì, ó ṣẹ sí àwọn baba yín lára, àbí kò ṣẹ?’+ Torí náà, wọ́n pa dà sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì sọ pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti fi ìyà jẹ wá nítorí àwọn ọ̀nà wa àti àwọn ìṣe wa, bó ṣe pinnu láti ṣe.’”+
7 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, ìyẹn oṣù Ṣébátì,* ní ọdún kejì ìjọba Dáríúsì,+ Jèhófà bá wòlíì Sekaráyà ọmọ Berekáyà ọmọ Ídò sọ̀rọ̀. Sekaráyà sọ pé: 8 “Mo rí ìran kan ní òru. Ọkùnrin kan ń gun ẹṣin pupa, ó sì dúró láàárín àwọn igi mátílì tó wà ní àfonífojì; ẹṣin pupa, ẹṣin pupa rẹ́súrẹ́sú àti ẹṣin funfun sì wà lẹ́yìn rẹ̀.”
9 Torí náà, mo sọ pé: “Olúwa mi, àwọn wo nìyí?”
Áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ dá mi lóhùn pé: “Màá fi ẹni tí wọ́n jẹ́ hàn ọ́.”
10 Lẹ́yìn náà, ọkùnrin tó dúró láàárín àwọn igi mátílì náà sọ pé: “Àwọn yìí ni Jèhófà rán jáde pé kí wọ́n rìn káàkiri ayé.” 11 Wọ́n sì sọ fún áńgẹ́lì Jèhófà tó dúró láàárín àwọn igi mátílì náà pé: “A ti rìn káàkiri ayé, a sì rí i pé gbogbo ayé pa rọ́rọ́, kò sí wàhálà kankan.”+
12 Torí náà, áńgẹ́lì Jèhófà sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kí o tó ṣàánú Jerúsálẹ́mù àti àwọn ìlú Júdà+ tí o ti bínú sí fún àádọ́rin (70) ọdún báyìí?”+
13 Jèhófà fi ọ̀rọ̀ tó dáa àti ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú dá áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn. 14 Áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì sọ fún mi pé: “Kéde pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Mo ní ìtara tó pọ̀ fún Jerúsálẹ́mù àti fún Síónì.+ 15 Inú bí mi gan-an sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ara tù,+ torí mi ò bínú púpọ̀ sí àwọn èèyàn mi,+ àmọ́ wọ́n dá kún àjálù náà.”’+
16 “Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘“Èmi yóò pa dà ṣàánú Jerúsálẹ́mù,”+ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, “wọn yóò kọ́ ilé mi sí ibẹ̀,+ wọn yóò sì na okùn ìdíwọ̀n sórí Jerúsálẹ́mù.”’+
17 “Kéde lẹ́ẹ̀kan sí i pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Ìwà rere máa pa dà kún àkúnwọ́sílẹ̀ ní àwọn ìlú mi; Jèhófà yóò sì pa dà tu Síónì nínú,+ yóò sì tún Jerúsálẹ́mù yàn.”’”+
18 Mo wá wòkè, mo sì rí ìwo mẹ́rin.+ 19 Torí náà, mo bi áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Kí làwọn nǹkan yìí?” Ó dáhùn pé: “Àwọn ìwo yìí ló fọ́n Júdà,+ Ísírẹ́lì+ àti Jerúsálẹ́mù ká.”+
20 Jèhófà wá fi àwọn oníṣẹ́ ọnà mẹ́rin hàn mí. 21 Mo bi í pé: “Kí ni àwọn yìí ń bọ̀ wá ṣe?”
Ó sọ pé: “Àwọn ìwo yìí ló fọ́n Júdà ká débi tí kò fi sí ẹnì kankan tó lè gbé orí sókè. Àwọn yìí ní tiwọn yóò wá láti dẹ́rù bà wọ́n, kí wọ́n lè ṣẹ́ ìwo àwọn orílẹ̀-èdè tó gbé ìwo wọn sókè sí ilẹ̀ Júdà, láti fọ́n ọn ká.”