-
Ẹ́sírà 6:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Àwọn àgbààgbà Júù ń bá iṣẹ́ ìkọ́lé náà lọ, wọ́n ń tẹ̀ síwájú,+ àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Hágáì+ àti Sekaráyà+ ọmọ ọmọ Ídò sì ń fún wọn níṣìírí; wọ́n parí iṣẹ́ ìkọ́lé náà nípa àṣẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ àti nípa àṣẹ Kírúsì+ àti Dáríúsì+ àti Atasásítà+ ọba Páṣíà. 15 Wọ́n parí ilé náà ní ọjọ́ kẹta oṣù Ádárì,* ní ọdún kẹfà àkóso Ọba Dáríúsì.
-