ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́sírà 1:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 1 Ní ọdún kìíní Kírúsì+ ọba Páṣíà, kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà+ sọ lè ṣẹ, Jèhófà ta ẹ̀mí Kírúsì ọba Páṣíà jí láti kéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì tún kọ ọ́ sílẹ̀+ pé:

      2 “Ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà sọ nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé,+ ó sì pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù,+ tó wà ní Júdà.

  • Àìsáyà 41:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Mo ti gbé ẹnì kan dìde láti àríwá, ó sì máa wá,+

      Ẹnì kan láti ibi tí oòrùn ti ń yọ*+ tó máa ké pe orúkọ mi.

      Ó máa tẹ àwọn alákòóso* mọ́lẹ̀ bíi pé amọ̀ ni wọ́n,+

      Bí amọ̀kòkò tó ń tẹ amọ̀ rírin mọ́lẹ̀.

  • Àìsáyà 45:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 45 Ohun tí Jèhófà sọ fún ẹni tó yàn nìyí, fún Kírúsì,+

      Ẹni tí mo di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú,+

      Láti tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba níwájú rẹ̀,+

      Láti gba ohun ìjà* àwọn ọba,

      Láti ṣí àwọn ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì níwájú rẹ̀,

      Kí wọ́n má sì ti àwọn ẹnubodè:

  • Àìsáyà 46:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Màá pe ẹyẹ aṣọdẹ wá láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,*+

      Ọkùnrin tó máa ṣe ohun tí mo pinnu*+ máa wá láti ilẹ̀ tó jìn.

      Mo ti sọ̀rọ̀, màá sì mú kó ṣẹ.

      Mo ti ní in lọ́kàn, màá sì ṣe é.+

  • Dáníẹ́lì 10:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ní ọdún kẹta Kírúsì+ ọba Páṣíà, a ṣí ọ̀rọ̀ kan payá fún Dáníẹ́lì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹtiṣásárì;+ òótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó dá lórí ìjàkadì ńlá kan. Ọ̀rọ̀ náà yé e, a sì jẹ́ kí ohun tó rí yé e.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́